ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́kísódù

      • Mósè àti igi ẹlẹ́gùn-ún tó ń jó (1-12)

      • Jèhófà sọ ìtúmọ̀ orúkọ Rẹ̀ (13-15)

      • Jèhófà fún Mósè ní ìtọ́ni (16-22)

Ẹ́kísódù 3:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 2:16; 18:1
  • +Ẹk 24:12, 13; 1Ọb 19:8, 9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2004, ojú ìwé 24

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 10

Ẹ́kísódù 3:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:30-34

Ẹ́kísódù 3:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/2009, ojú ìwé 15

Ẹ́kísódù 3:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 17:1, 7
  • +Jẹ 26:24
  • +Jẹ 28:13; 32:9; Mt 22:32; Iṣe 7:32

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/2005, ojú ìwé 13

Ẹ́kísódù 3:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 1:11; Ais 63:9; Iṣe 7:34

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 7

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2019, ojú ìwé 15

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/2009, ojú ìwé 15

    7/1/2003, ojú ìwé 19

Ẹ́kísódù 3:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:51
  • +Nọ 13:26, 27; Di 27:3
  • +Jẹ 10:15-17; Ẹk 33:1, 2; Di 7:1; Joṣ 3:10; Ne 9:7, 8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 7

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2019, ojú ìwé 15

Ẹ́kísódù 3:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 1:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 7

Ẹ́kísódù 3:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 105:26, 38; Iṣe 7:34

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 7

Ẹ́kísódù 3:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2005, ojú ìwé 13-14

Ẹ́kísódù 3:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “sin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 31:23; Joṣ 1:5; Ais 41:10; Ro 8:31; Flp 4:13
  • +Ẹk 19:2; Di 4:11, 12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2005, ojú ìwé 14

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 10, 104-105

Ẹ́kísódù 3:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 15:3; Sm 96:8; 135:13; Ho 12:5; Jo 17:26; Ro 10:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 7-9

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2013, ojú ìwé 25

Ẹ́kísódù 3:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Èmi Yóò Di Ohun Tí Mo Bá Yàn; Èmi Yóò Jẹ́ Ohun Tí Èmi Yóò Jẹ́.” Wo Àfikún A4.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 23:13; Ais 14:27; Jo 12:28
  • +Ẹk 6:3, 7; Ro 9:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    6/2020, ojú ìwé 6

    Ilé Ìṣọ́,

    7/15/2014, ojú ìwé 27

    3/15/2013, ojú ìwé 25-27

    7/1/2010, ojú ìwé 4

    3/15/2004, ojú ìwé 25

    1/15/2002, ojú ìwé 5

    3/1/1995, ojú ìwé 10

    8/1/1994, ojú ìwé 10-11

    Bíbélì Fi Kọ́ni, ojú ìwé 196-197

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 9-10

    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, ojú ìwé 43

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1735

    Jí!,

    2/8/2004, ojú ìwé 23

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 12-14, 104-105

Ẹ́kísódù 3:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 17:1, 7
  • +Jẹ 26:24
  • +Jẹ 28:13; Mt 22:32
  • +Sm 135:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 4

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2013, ojú ìwé 25-27

Ẹ́kísódù 3:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 50:24; Ẹk 13:19

Ẹ́kísódù 3:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:13, 14; Le 26:13
  • +Jẹ 15:16
  • +Ẹk 23:23
  • +Nọ 13:27; Di 8:7-9

Ẹ́kísódù 3:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 4:31
  • +Jẹ 14:13
  • +Ẹk 5:3; 10:25, 26

Ẹ́kísódù 3:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 5:2; 14:8; Ro 9:17

Ẹ́kísódù 3:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 7:3; 12:33; Di 6:22

Ẹ́kísódù 3:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 11:2; 12:35, 36

Ẹ́kísódù 3:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:13, 14; Ẹk 12:36

Àwọn míì

Ẹ́kís. 3:1Ẹk 2:16; 18:1
Ẹ́kís. 3:1Ẹk 24:12, 13; 1Ọb 19:8, 9
Ẹ́kís. 3:2Iṣe 7:30-34
Ẹ́kís. 3:6Jẹ 17:1, 7
Ẹ́kís. 3:6Jẹ 26:24
Ẹ́kís. 3:6Jẹ 28:13; 32:9; Mt 22:32; Iṣe 7:32
Ẹ́kís. 3:7Ẹk 1:11; Ais 63:9; Iṣe 7:34
Ẹ́kís. 3:8Ẹk 12:51
Ẹ́kís. 3:8Nọ 13:26, 27; Di 27:3
Ẹ́kís. 3:8Jẹ 10:15-17; Ẹk 33:1, 2; Di 7:1; Joṣ 3:10; Ne 9:7, 8
Ẹ́kís. 3:9Ẹk 1:11
Ẹ́kís. 3:10Sm 105:26, 38; Iṣe 7:34
Ẹ́kís. 3:12Di 31:23; Joṣ 1:5; Ais 41:10; Ro 8:31; Flp 4:13
Ẹ́kís. 3:12Ẹk 19:2; Di 4:11, 12
Ẹ́kís. 3:13Ẹk 15:3; Sm 96:8; 135:13; Ho 12:5; Jo 17:26; Ro 10:13
Ẹ́kís. 3:14Job 23:13; Ais 14:27; Jo 12:28
Ẹ́kís. 3:14Ẹk 6:3, 7; Ro 9:17
Ẹ́kís. 3:15Jẹ 17:1, 7
Ẹ́kís. 3:15Jẹ 26:24
Ẹ́kís. 3:15Jẹ 28:13; Mt 22:32
Ẹ́kís. 3:15Sm 135:13
Ẹ́kís. 3:16Jẹ 50:24; Ẹk 13:19
Ẹ́kís. 3:17Jẹ 15:13, 14; Le 26:13
Ẹ́kís. 3:17Jẹ 15:16
Ẹ́kís. 3:17Ẹk 23:23
Ẹ́kís. 3:17Nọ 13:27; Di 8:7-9
Ẹ́kís. 3:18Ẹk 4:31
Ẹ́kís. 3:18Jẹ 14:13
Ẹ́kís. 3:18Ẹk 5:3; 10:25, 26
Ẹ́kís. 3:19Ẹk 5:2; 14:8; Ro 9:17
Ẹ́kís. 3:20Ẹk 7:3; 12:33; Di 6:22
Ẹ́kís. 3:21Ẹk 11:2; 12:35, 36
Ẹ́kís. 3:22Jẹ 15:13, 14; Ẹk 12:36
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ẹ́kísódù 3:1-22

Ẹ́kísódù

3 Mósè ń bójú tó agbo ẹran Jẹ́tírò+ bàbá ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ àlùfáà Mídíánì. Nígbà tó ń da agbo ẹran náà lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn aginjù, ó dé Hórébù, òkè Ọlọ́run tòótọ́.+ 2 Áńgẹ́lì Jèhófà fara hàn án nínú ọwọ́ iná tó ń jó láàárín igi ẹlẹ́gùn-ún kan.+ Bó ṣe ń wò ó, ó rí i pé iná ń jó lára igi ẹlẹ́gùn-ún náà, síbẹ̀ igi náà ò jóná. 3 Mósè wá sọ pé: “Jẹ́ kí n lọ wo nǹkan àrà yìí, kí n lè mọ ohun tí kò jẹ́ kí igi ẹlẹ́gùn-ún náà jóná.” 4 Nígbà tí Jèhófà rí i pé ó lọ wò ó, Ọlọ́run pè é látinú igi ẹlẹ́gùn-ún náà pé: “Mósè! Mósè!” Ó dáhùn pé: “Èmi nìyí.” 5 Ó wá sọ pé: “Má ṣe sún mọ́ ibí yìí. Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, torí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí o dúró sí.”

6 Ó sọ pé: “Èmi ni Ọlọ́run bàbá rẹ, Ọlọ́run Ábúráhámù,+ Ọlọ́run Ísákì+ àti Ọlọ́run Jékọ́bù.”+ Ni Mósè bá fojú pa mọ́, torí ẹ̀rù ń bà á láti wo Ọlọ́run tòótọ́. 7 Jèhófà sì sọ pé: “Mo ti rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn mi ní Íjíbítì, mo sì ti gbọ́ igbe wọn torí àwọn tó ń fipá kó wọn ṣiṣẹ́; mo mọ̀ dáadáa pé wọ́n ń jẹ̀rora.+ 8 Màá lọ gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì,+ màá sì mú wọn kúrò ní ilẹ̀ yẹn lọ sí ilẹ̀ kan tó dára, tó sì fẹ̀, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ ní agbègbè àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.+ 9 Wò ó! Mo ti gbọ́ igbe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, mo sì ti rí bí àwọn ará Íjíbítì ṣe ń fìyà jẹ wọ́n gidigidi.+ 10 Ní báyìí, wá, jẹ́ kí n rán ọ sí Fáráò, wàá sì mú àwọn èèyàn mi, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì.”+

11 Àmọ́ Mósè sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Ta ni mo jẹ́, tí màá fi lọ bá Fáráò, tí màá sì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì?” 12 Ó fèsì pé: “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ,+ ohun tí yóò sì jẹ́ àmì fún ọ pé èmi ni mo rán ọ nìyí: Lẹ́yìn tí o bá ti mú àwọn èèyàn náà kúrò ní Íjíbítì, ẹ máa jọ́sìn* Ọlọ́run tòótọ́ lórí òkè yìí.”+

13 Àmọ́ Mósè sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Ká ní mo lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí mo sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín rán mi sí yín,’ tí wọ́n sì bi mí pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’+ Kí ni kí n sọ fún wọn?” 14 Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Èmi Yóò Di Ohun Tí Mo Bá Fẹ́.”*+ Ó sì sọ pé: “Ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí, ‘Èmi Yóò Di ti rán mi sí yín.’”+ 15 Ọlọ́run wá sọ fún Mósè lẹ́ẹ̀kan sí i pé:

“Ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, Ọlọ́run Ábúráhámù,+ Ọlọ́run Ísákì+ àti Ọlọ́run Jékọ́bù+ ló rán mi sí yín.’ Èyí ni orúkọ mi títí láé,+ bí wọ́n á sì ṣe máa rántí mi láti ìran dé ìran nìyí. 16 Wá lọ, kí o kó àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín ti fara hàn mí, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù, ó sì sọ pé: “Mo ti kíyè sí yín,+ mo sì ti rí ohun tí wọ́n ń ṣe sí yín ní Íjíbítì. 17 Torí náà, mo ṣèlérí pé màá gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì tó ń fìyà jẹ yín,+ màá sì mú yín lọ sí ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì,+ àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ sí ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.”’+

18 “Ó dájú pé wọ́n á fetí sí ohùn rẹ,+ ìwọ àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì yóò lọ bá ọba Íjíbítì, ẹ ó sì sọ fún un pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn Hébérù+ ti bá wa sọ̀rọ̀. Torí náà, jọ̀ọ́, jẹ́ ká rin ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta lọ sí aginjù, ká lè rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa.’+ 19 Àmọ́ èmi fúnra mi mọ̀ dáadáa pé ọba Íjíbítì kò ní jẹ́ kí ẹ lọ àfi tí mo bá fi ọwọ́ agbára mú un.+ 20 Ṣe ni màá na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ Íjíbítì nípasẹ̀ gbogbo nǹkan àgbàyanu tí màá ṣe níbẹ̀, lẹ́yìn náà, á jẹ́ kí ẹ lọ.+ 21 Màá mú kí àwọn èèyàn yìí rí ojú rere àwọn ará Íjíbítì, tí ẹ bá sì ń lọ, ó dájú pé ẹ ò ní lọ lọ́wọ́ òfo.+ 22 Kí obìnrin kọ̀ọ̀kan béèrè àwọn ohun èlò fàdákà àti wúrà pẹ̀lú aṣọ lọ́wọ́ ọmọnìkejì rẹ̀ àti obìnrin tó ń gbé nílé rẹ̀, kí ẹ sì fi wọ àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin yín; ẹ ó sì gba tọwọ́ àwọn ará Íjíbítì.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́