Ẹ Maṣe Tàsé Ète Ominira Tí Ọlọrun Fi Funni
“Nibi ti ẹmi Jehofa bá wà, ominira wà nibẹ.”—2 KỌRINTI 3:17, NW.
1. Eeṣe ti Aisaya 65:13, 14 fi kan Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa?
JEHOFA ni Ọlọrun ominira. Iru ibukun wo sì ni ominira ti Ọlọrun fi funni jẹ́! Nitori pe awọn iranṣẹ rẹ̀ oluṣeyasimimọ ní iru ominira bẹẹ, awọn ọrọ Jehofa Oluwa Ọba-Alaṣẹ wọnyi ṣee fisilo fun wọn pe: “Kiyesi i, awọn iranṣẹ mi yoo jẹun, ṣugbọn ebi yoo pa ẹyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi yoo mu, ṣugbọn oungbẹ yoo gbẹ ẹyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi yoo yọ̀, ṣugbọn oju yoo ti ẹyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi yoo kọrin fun inudidun, ṣugbọn ẹyin yoo ké fun ibanujẹ ọkàn, ẹyin yoo sì hu fun irobinujẹ ọkàn.”—Aisaya 65:13, 14.
2. Eeṣe ti awọn eniyan Jehofa fi laasiki nipa tẹmi?
2 Awọn eniyan Ọlọrun ń gbadun ipo aasiki nipa tẹmi yii nitori pe a ń fi ẹmi mímọ́, tabi ipá agbékánkánṣiṣẹ́ rẹ̀ dari wọn. Apọsiteli Pọọlu sọ pe: “Jehofa ni Ẹ̀mí naa; nibi ti ẹ̀mí Jehofa bá sì wà, ominira wà nibẹ.” (2 Kọrinti 3:17, NW) Ki ni ète ominira ti Ọlọrun fi funni? Ki ni a sì beere fun lọwọ wa lati lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́?
Ominira Tí Ọlọrun Ní
3. Iru ominira wo ni Ọlọrun ni, eesitiṣe?
3 Jehofa nikan ni ó ní ominira patapata. Kò si eyikeyii ninu awọn iṣẹda rẹ̀ ti o lè pààlà sí ominira rẹ̀ nitori pe oun jẹ́ Ọlọrun Olodumare ati Ọba-Alaṣẹ Agbaye. Gẹgẹ bi Joobu ọkunrin oloootọ naa ti sọ, “ta ni yoo dá a pada? Ta ni yoo bi í pe, ki ni iwọ ń ṣe nì?” (Joobu 9:12) Bakan naa, Nebukadinesari ọba Babiloni ni a fipa mú lati gbà pe: “Kò sì sí ẹni ti ń dá ọwọ [Ọlọrun] duro, tabi ẹni ti ń wí fun un pe, ki ni iwọ ń ṣe nì?”—Daniẹli 4:35.
4. Bawo ni o ṣe jẹ́ pe Jehofa pa ominira rẹ̀ mọ sabẹ ìkáwọ́?
4 Bi o ti wu ki o ri, awọn ilana ododo ti Jehofa funraarẹ pa ominira patapata yẹn mọ sabẹ ìkáwọ́. Eyi ni a ṣapejuwe nigba ti Aburahamu sọ idaniyan jade nipa awọn olugbe Sodomu ti o sì beere pe: “Onidaajọ gbogbo ayé ki yoo ha ṣe eyi ti o tọ́?” Idahun pada Ọlọrun fihan pe ó mọ ẹrù-iṣẹ́ naa lati ṣe ohun ti ó tọ́. Oun kì bá tí pa Sodomu run bi awọn olugbe olododo eyikeyii bá ti ń baa lọ lati wà ninu rẹ̀. (Jẹnẹsisi 18:22-33) Ọlọrun tun pa ominira rẹ̀ mọ sabẹ ìkáwọ́ nitori pe ifẹ ati ọgbọn rẹ̀ mú un ki o lọra lati binu ki o sì lo ikora-ẹni-nijaanu.—Aisaya 42:14.
Awọn Ààlà Ominira Eniyan
5. Ki ni awọn okunfa diẹ ti o pààlà si ominira eniyan?
5 Bi o tilẹ jẹ pe Jehofa ní ominira patapata, gbogbo awọn ti o kù ń huwa laaarin awọn ààlà ti a gbekalẹ fun wọn nipa iru ẹ̀dá, agbara, ati agbegbe ibugbe wọn, pẹlu awọn koko abajọ bii iwọn gígùn igbesi-aye awọn eniyan ẹlẹṣẹ ti o kuru nisinsinyi. Ọlọrun dá eniyan pẹlu ominira pípé lati gbeṣẹṣe laaarin agbegbe ti Jehofa ti gbé kalẹ fun un. Awọn idi melookan miiran wà tí ominira eniyan fi láàlà, kii ṣe patapata.
6. Jíjíhìn fun Ọlọrun ni ipa wo lori ominira wa?
6 Akọọkọ, ominira eniyan láàlà nitori pe Ọlọrun dá eniyan lati ṣiṣẹsin fun ète Rẹ̀. Jehofa ‘lẹtọọ lati gba ogo ati ọla ati agbara nitori pe oun ni ó dá ohun gbogbo ati nitori pe nipa ifẹ rẹ̀ ni wọn fi wà ti a sì dá wọn.’ (Iṣipaya 4:11) Nitori naa eniyan yoo jihin fun Ẹlẹdaa rẹ̀, ẹni ti o ti fi ẹ̀tọ́ ṣe awọn ofin nipa eyi ti a o gbà ṣakoso eniyan. Ni Isirẹli igbaani labẹ Ofin Mose, Ọlọrun beere pe ki ẹni ti ó bá ṣi orukọ rẹ̀ lò tabi rú ofin Ọjọ-isinmi rẹ̀ di pípa. (Ẹkisodu 20:7; 31:14, 15; Lefitiku 24:13-16; Numeri 15:32-36) Bi o tilẹ jẹ pe awa gẹgẹ bii Kristẹni kò sí labẹ Ofin naa, ominira wa láàlà nitori pe a o jihin fun Jehofa, ẹni tí í ṣe Onidaajọ, Olufunni ni ofin, ati Ọba wa.—Aisaya 33:22; Roomu 14:12.
7, 8. (a) Bawo ni ofin adanida ṣe pààlà si ominira eniyan? (b) Awọn ofin Ọlọrun miiran wo ni o pààlà si ominira wa gẹgẹ bi eniyan?
7 Ekeji, ominira eniyan láàlà nitori awọn ofin adanida ti Ọlọrun. Fun apẹẹrẹ, nitori ofin òòfà ilẹ̀, eniyan kò lè fò kuro lori pẹ̀tẹ́ẹ̀sì àwòṣífìlà kan láìṣèṣe tabi ki o pa araarẹ̀. O ṣe kedere pe, awọn ofin adanida Ọlọrun pààlà si ominira eniyan lati ṣe awọn nǹkan kan.
8 Ẹkẹta, ominira eniyan láàlà nitori awọn ofin iwa rere Ọlọrun. Ó ṣeeṣe julọ, ki iwọ ti ṣakiyesi imuṣẹ ohun ti Pọọlu kọ ni Galatia 6:7, 8 pe: “Ki a maṣe tàn yin jẹ; a kò lè gan Ọlọrun: nitori ohunkohun ti eniyan bá funrugbin, oun ni yoo sì ká. Nitori ẹni ti o bá ń funrugbin sipa ti ara rẹ̀, nipa ti ara ni yoo ká idibajẹ; ṣugbọn ẹni ti o bá ń funrugbin sipa ti ẹmi, nipa ti ẹmi ni yoo ká ìyè ainipẹkun.” Láì ṣeé jiyàn lé lórí, awọn ofin iwa rere ti Jehofa Ọlọrun tun pààlà si ominira wa, ṣugbọn ṣiṣegbọran si wọn ni a beere fun ki a baa lè jèrè ìyè.
9. Bawo ni jíjẹ́ ti a jẹ́ apakan awujọ eniyan ṣe pààlà si ominira wa?
9 Ẹkẹrin, ominira eniyan láàlà nitori pe oun jẹ́ apakan awujọ eniyan. Fun idi yii, oun gbọdọ ni ominira kiki dé iwọn ti kò fi aiṣedajọ ododo dí ominira awọn ẹlomiran lọwọ. Awọn Kristẹni gbọdọ wà ni itẹriba si “awọn alaṣẹ onipo gigaju” ti ijọba, ni ṣiṣegbọran si wọn niwọn bi wọn kò ba ti beere pe ki a ṣẹ̀ sí awọn ofin Ọlọrun. (Roomu 13:1, NW; Iṣe 5:29) Fun apẹẹrẹ, a gbọdọ ṣegbọran si awọn ofin tí ó jẹ mọ́ sísan owo-ori, iwọn ìyárasáré ti a fi ń wa ọkọ irinna kan, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Otitọ naa pe a gbọdọ ṣegbọran si iru awọn ofin “Kesari” bẹẹ fihan siwaju sii pe ominira ti Ọlọrun fi fun wa kii ṣe patapata.—Maaku 12:17; Roomu 13:7.
Ki Ni Idi Fun Ominira Aláàlà?
10, 11. Eeṣe ti Jehofa fi fun eniyan ni ominira aláàlà?
10 Eeṣe ti Ọlọrun fi fun eniyan ní ominira aláàlà? Idi kan ni pe ki Ẹlẹdaa lè ni awọn iṣẹda ọlọgbọnloye lori ilẹ̀-ayé ti wọn yoo maa mú ọla ati iyin wá fun un nipa awọn ọrọ ati iwa rere wọn. Awọn eniyan lè ṣe eyi, nigba ti ó jẹ́ pe awọn ẹranko kò lè ṣe bẹẹ. Awọn ẹranko, ti a ń ṣakoso nipasẹ ọgbọn-inu àdámọ́, kò mọ ohunkohun nipa ihuwa rere. Iwọ lè kọ́ ajá kan lati maṣe gbé ohun kan, ṣugbọn iwọ kò lè kọ́ ọ ni àìtọ́ olè jíjà. Ẹranko kan ti a ti ṣetolẹsẹẹsẹ ihuwasi rẹ̀, gẹgẹ bi o ti ri, kò lè ṣe awọn ipinnu ti ń mú ìyìn ati ọla wá fun Ọlọrun, nigba ti o jẹ́ pe eniyan lè finnufindọ yàn lati ṣiṣẹsin Ẹlẹdaa rẹ̀ lati inu ifẹ ati imọriri wá.
11 Ọlọrun tun fun awọn eniyan lominira yii fun anfaani ati ayọ wọn. Wọn lè lo ominira aláàlà wọn nipa jíjẹ́ olójú-ọnà ati olùhùmọ̀, olóore ati olufọwọsowọpọ. Awọn eniyan tun ni ominira yíyàn ninu iru awọn ọran bii iṣẹ́-àjókòótì ati ibi gbígbé. Lonii, awọn kókó tí o jẹmọ ti iṣunna-owo ati ti iṣelu a maa pààlà si ominira yíyàn yẹn lọpọ igba, ṣugbọn eyi lè jẹ́ nitori ìwọ̀ra eniyan, kii ṣe nitori ọna ti Ọlọrun gbà dá araye ni ipilẹṣẹ.
12. Eeṣe ti ọpọ julọ araye fi wà ninu ìdè ìsìnrú?
12 Bi o tilẹ jẹ́ pe Jehofa fun awọn eniyan ni ominira fàlàlà, ọpọ rẹpẹtẹ awọn eniyan lonii wà ninu ìdè ìsìnrú ti ń banininujẹ. Ki ni ṣẹlẹ? Awọn eniyan meji akọkọ, Adamu ati Efa, kuna ète ominira ti Ọlọrun fi fun wọn. Wọn lọ rekọja awọn ààlà atọrunwa lori ominira wọn wọn sì pe ẹ̀tọ́ ipo iṣakoso Ọlọrun lori wọn gẹgẹ bi Oluwa Ọba-Alaṣẹ, Jehofa nija. (Jẹnẹsisi 3:1-7; Jeremaya 10:10; 50:31) Lainitẹẹlọrun lati lo ominira wọn lati bọla fun Ọlọrun, wọn lò ó lọna imọtara-ẹni-nikan, lati pinnu ohun ti o tọ́ ati ohun ti kò tọ́ funraawọn, ti wọn si tipa bayii darapọ mọ Satani ninu iṣọtẹ rẹ̀ lodisi Jehofa. Dipo rírí ominira pupọ sii, bi o ti wu ki o ri, Adamu ati Efa ẹlẹṣẹ ni a fi sabẹ awọn ipo ikalọwọko ti ń danniwo ati ìdè ìsìnrú, ilọsilẹ ominira wọn, ati nikẹhin ikú. Atọmọdọmọ wọn jogun ipadanu ominira yii. “Gbogbo eniyan ni o ṣá ti ṣẹ̀, ti wọn sì kuna ogo Ọlọrun.” “Iku ni èrè ẹṣẹ.”—Roomu 3:23; 5:12; 6:23.
13. Eeṣe ti o fi ṣeeṣe fun Satani lati mú eniyan lẹ́rú?
13 Nitori iṣọtẹ ni Edẹni, Adamu ati atọmọdọmọ rẹ̀ tún wá sinu ìdè ìsìnrú Satani Eṣu. Họwu, “gbogbo ayé ni o wà labẹ agbara ẹni buburu nì”! (1 Johanu 5:19) Agbara ati oye rẹ̀ gigaju ni ó ti mu ki ó ṣeeṣe fun Satani lati tan gbogbo araye jẹ ki ó si sọ awọn ti a ti sọ di àjèjì si Ọlọrun di ẹrú. Ju bẹẹ lọ, awọn eniyan onimọtara-ẹni-nikan ti jẹgàba lori awọn eniyan ẹlẹgbẹ wọn sí ifarapa wọn. (Oniwaasu 8:9) Fun idi yii, araye ni gbogbogboo wà nisinsinyi ninu ìdè ìsìnrú ẹṣẹ ati iku, si Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀, ati si awọn eto igbekalẹ ti oṣelu, ọrọ̀-ajé, ati isin ayé.
A Mú Ominira Tootọ Ṣeeṣe
14. Ireti araye fun ominira tootọ ni a sopọ mọ ki ni?
14 Jijere ominira kuro lọwọ ẹṣẹ, iku, ati Eṣu ati ayé rẹ̀ ni ó so pọ pẹkipẹki pẹlu ipinnu Ọlọrun lati yanju ariyanjiyan nipa ẹ̀tọ́ ipo ọba-alaṣẹ agbaye rẹ̀. Nitori pe Satani gbé ariyanjiyan yii dide, Jehofa ti yọnda rẹ̀ lati maa gbé lọ, ani bi Ó ti gba Farao laaye lati wà fun akoko kan. Eyi jẹ nitori ki Jehofa lè ṣaṣefihan agbara rẹ̀ ni kikun ki ó sì sọ orukọ rẹ̀ di eyi ti a polongo ni gbogbo ilẹ̀-ayé. (Ẹkisodu 9:15, 16) Ọlọrun yoo dá araarẹ lare laipẹ gẹgẹ bi Ọba-Alaṣẹ Agbaye yoo sì ya orukọ mímọ́ rẹ̀ si mímọ́ nipa mimu ẹ̀gàn ti a ti mu wa sori rẹ̀ nipasẹ iṣọtẹ Satani, Adamu, ati Efa kuro. Nipa bayii, awọn wọnni ti wọn ń bẹru Jehofa ni a o dá silẹ kuro ninu ìdè ìsìnrú si ẹṣẹ ati ikú a o sì mu wọn wá sinu ayé titun ominira kan ti Ọlọrun fi funni.—Roomu 8:19-23.
15. Ipa wo ni Jesu kó ninu imupadabọsipo ominira fun araye?
15 Lati mú ominira iran eniyan padabọsipo, Ọlọrun rán Ọmọkunrin rẹ̀ wa si ilẹ̀-ayé gẹgẹ bi eniyan. Ni fífínnú-fíndọ̀ fi iwalaaye eniyan pípé rẹ̀ lélẹ̀, Ọmọkunrin Ọlọrun, Jesu Kristi, pese ẹbọ irapada naa, ipilẹ fun dida araye si lominira. (Matiu 20:28) Ó sì tún polongo ihin-iṣẹ ominira. Ni ibẹrẹ iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀, ó lo awọn ọrọ naa fun araarẹ pe: “Ẹmi Oluwa Jehofa ń bẹ lara mi: nitori o ti fi ami ororo yàn mi lati waasu ihinrere fun awọn òtòṣì; o ti rán mi lati ṣe àwòtán awọn onirobinujẹ ọkàn, lati kede idasilẹ fun awọn igbekun, ati iṣisilẹ tubu fun awọn òǹdè.”—Aisaya 61:1; Luuku 4:16-21.
16. Igbesẹ wo ni awọn Juu ọrundun kìn-ín-ní nilati gbé lati jere ominira tootọ?
16 Bawo ni awọn eniyan yoo ṣe jere ominira yẹn? Jesu sọ pe: “Bi ẹyin bá duro ninu ọrọ mi, nigba naa ni ẹyin jẹ́ ọmọ-ẹhin mi nitootọ. Ẹ ó sì mọ otitọ, otitọ yoo sì sọ yin di ominira.” Nipa bayii, awọn ọmọlẹhin Jesu ti wá lati gbadun ominira tẹmi. (Johanu 8:31, 32, 36) Siwaju sii, Jesu sọ fun gomina Roomu Pọntu Pilatu pe: “Nitori eyi ni a ṣe bí mi, ati nitori idi eyi ni mo sì ṣe wá si ayé, ki emi ki o lè jẹrii si otitọ. Olukuluku ẹni tí í ṣe ti otitọ ń gbọ́ ohùn mi.” (Johanu 18:37) Awọn Juu ti wọn tẹwọgba otitọ gẹgẹ bi a ti waasu ti a sì ṣapẹẹrẹ rẹ̀ nipasẹ Jesu ronupiwada awọn ẹṣẹ wọn, wọn tún ipa-ọna àìtọ́ wọn ṣe, wọn mu araawọn wá si iwaju Jehofa, a sì bamtisi wọn gẹgẹ bi a ti ṣe fun Jesu. (Matiu 3:13-17; Iṣe 3:19) Ni ọna yii wọn wá gbadun ominira ti Ọlọrun fi funni.
17. Eeṣe ti Jehofa fi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ lominira?
17 Jehofa fun awọn iranṣẹ rẹ̀ aduroṣinṣin ni ominira ni ipilẹ lati dá ipò ọba-alaṣẹ tirẹ̀ lare ṣugbọn pẹlu fun ìtùnú tabi anfaani wọn. Ó dá awọn ọmọ Isirẹli silẹ lominira kuro ninu ìdè ìsìnrú Ijibiti ki wọn baa lè fogo fun un gẹgẹ bi ijọba awọn alufaa kan, awọn ẹlẹ́rìí rẹ̀. (Ẹkisodu 19:5, 6; Aisaya 43:10-12) Bakan naa, Jehofa mú awọn eniyan rẹ̀ jade kuro ni igbekun Babiloni ni pataki lati tun tẹmpili rẹ̀ kọ́ ki wọn sì mu ijọsin tootọ padabọsipo. (Ẹsira 1:2-4) Nigba ti awọn ìgbèkùn naa dari ìfẹ́ araawọn kọ kìkì itẹlọrun ohun ti ara tiwọn funraawọn, Jehofa rán awọn wolii rẹ̀ Hagai ati Sekaraya si wọn lati rán wọn leti awọn iṣẹ aigbọdọmaṣe wọn niwaju Ọlọrun. Titipa bayii fi ominira ti Ọlọrun fifun wọn si igun oju iwoye titọna yọrisi pipari tẹmpili naa, sí ogo Ọlọrun, ati pẹlu sí itunu ati wíwà lalaafia awọn eniyan rẹ̀ pẹlu.
Ṣiṣai Tàsé Ète Ominira ti Ọlọrun Fi Funni
18. Eeṣe ti a fi lè sọ pe awọn iranṣẹ Jehofa ode-oni kò tíì tàsé ète ominira ti Ọlọrun fifun wọn?
18 Ki ni nipa awọn iranṣẹ Ọlọrun ode-oni? Gẹgẹ bi eto-ajọ kan, wọn kò tíì tàsé ète ominira ti Ọlọrun fifun wọn. Ni awọn ọdun 1870 wọn bẹrẹ sii dominira kuro ninu awọn aṣiṣe Babiloni ati lati gbadun ominira Kristẹni ti a mú pọ̀ sii. Eyi jẹ́ ni gbígbé ni ibamu pẹlu Owe 4:18, eyi ti o sọ pe: “Ipa-ọna awọn oloootọ dabi títàn imọlẹ, ti o ń tàn siwaju ati siwaju titi di ọ̀sángangan.” Sibẹ, gẹgẹ bi a ti kó awọn eniyan Ọlọrun igbaani lọ si igbekun Babiloni fun akoko kan, ni 1918 awọn iranṣẹ Jehofa wá sabẹ ìdè ìsìnrú Babiloni Ńlá. (Iṣipaya 17:1, 2, 5) Awọn mẹmba ilẹ-ọba isin èké agbaye yẹn yọ̀ nigba ti ‘awọn ẹlẹ́rìí meji’ iṣapẹẹrẹ dubulẹ ninu iku nipa tẹmi. Ṣugbọn nipa inurere ailẹtọọsi Ọlọrun ni 1919 awọn iranṣẹ rẹ̀ ẹni ami ororo ni a mu sọji, ti wọn di ẹni ti a dá silẹ lominira nipa tẹmi. (Iṣipaya 11:3, 7-11) Ni fifi ominira ti Ọlọrun fifun wọn silo, wọn di ẹlẹ́rìí onitara ti Ọga Ogo naa. Nitori naa, ó ti yẹ tó pe wọn fi tayọtayọ gba orukọ naa Ẹlẹ́rìí Jehofa mọra, ni 1931! (Aisaya 43:10-12) Paapaa lati 1935 ni “ogunlọgọ ńlá kan” ti wọn ni ireti lati jere ìyè ayeraye lori ilẹ̀-ayé, ti darapọ mọ Awọn Ẹlẹ́rìí ẹni ami ororo. Awọn pẹlu kò tàsé ète ominira ti Ọlọrun fifun wọn.—Iṣipaya 7:9-17, NW.
19, 20. (a) Ki ni ọna kan ti ó yẹ fun afiyesi ti awọn eniyan Jehofa ń gbà fi ominira ti Ọlọrun fifun wọn si ilo rere? (b) Ni ọna ti o ṣee kiyesi miiran wo ni Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń gbà lo ominira ti Ọlọrun ti fifun wọn lọna rere?
19 Awọn eniyan Jehofa ń fi ominira wọn silo lọna rere ni ọna meji ti o yẹ fun afiyesi ni pataki. Fun ohun kan, wọn lò ó lati lépa ipa ọna ododo. (1 Peteru 2:16) Iru orukọ rere wo ni wọn sì ni! Fun apẹẹrẹ, ọkunrin kan nigba kan rí wọnu Gbọngan Ijọba kan ni Zurich, Switzerland, ó sì sọ pe oun fẹ́ di ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nigba ti a beere idi rẹ̀, o ṣalaye pe arabinrin oun jẹ́ Ẹlẹ́rìí a sì ti yọ ọ́ lẹgbẹ fun iwa palapala. Ó sọ pe: ‘Eto-ajọ ti mo fẹ́ darapọ mọ niyẹn—ọ̀kan ti kò fàyè gba iwa buburu.’ Pẹlu idi rere New Catholic Encyclopedia ti ṣakiyesi pe Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti jere orukọ rere fun jíjẹ́ “ọ̀kan lara awọn awujọ ti o mọ̀wàáhù julọ ni ayé.”
20 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tun lo ominira ti Ọlọrun fifun wọn nipa mímú iṣẹ-aṣẹ wọn lati waasu ihinrere Ijọba ṣẹ, gẹgẹ bi Jesu ti ṣe. (Matiu 4:17) Nipa ọrọ ẹnu ati iwe títẹ̀, lọna bí-àṣà ati lọna àìjẹ́-bí-àṣà, wọn ń kéde Ijọba Jehofa. Ni ṣiṣe bẹẹ awọn funraawọn janfaani gidigidi nipa fífún igbagbọ araawọn lokun ati mímú ireti wọn mọ́lẹ̀. Ju bẹẹ lọ, igbokegbodo yii ṣiṣẹ lati gbà wọn ati awọn wọnni ti o fetisilẹ si wọn là. (1 Timoti 4:16) Nipa igbokegbodo yii, iwe naa Dynamic Religious Movements sọ pe: “Yoo ṣoro lati rí mẹmba awujọ eyikeyii miiran ti ń ṣiṣẹ kára ninu isin wọn gẹgẹ bi awọn Ẹlẹ́rìí ti ń ṣe.
21. Ẹ̀rí wo ni o wà nibẹ pe Jehofa ń bukun iṣẹ-ojiṣẹ awọn eniyan rẹ̀?
21 Jehofa sì ti ń bukun fun wa tó ní gbígbé ète ominira ti Ọlọrun fifun wa jade! Eyi ni a lè rí lati inu irohin iṣẹ-isin pápá ọdun ti o kọja—gongo ti ó ju million mẹrin awọn akede Ijọba, ti iye ti o ju million mẹwaa sì pesẹ sí Iṣe-iranti iku Jesu. Ninu iwadiiwo kan, Ireland ni gongo 29 tẹleratẹlera ninu iye awọn akede loṣooṣu; Mexico ni gongo 78 ni 80 oṣu; Japan sì ni 153 gongo tẹleratẹlera!
Lo Ominira Ti Ọlọrun Fifun Ọ Lọna Rere
22. Ki ni kókó awọn ibeere diẹ ti ń ru ironu soke ti a le beere nipa araawa?
22 Bi iwọ bá jẹ ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí oluṣeyasimimọ ti Jehofa, iwọ ha ń lo ominira rẹ ti Ọlọrun ti fifun ọ lọna rere bi? Olukuluku wa lè beere lọwọ araarẹ lọna ti o tọna pe: ‘Mo ha ń ṣọra lati lo ominira ti Ọlọrun fifun mi ki n lè yẹra fun mimu ẹnikẹni kọsẹ nipa iwa ti kò tọna bi? Mo ha ń fi tọkantọkan ṣegbọran si awọn ofin Kesari, bi o tilẹ jẹ pe mo ń fi ofin Ọlọrun saaju bí? Mo ha ń fọwọsowọpọ ni kíkún pẹlu awọn alagba ijọ bi? Mo ha ń lo ominira ti Ọlọrun fifun mi dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ninu wiwaasu ihinrere bi? Mo ha ń ní “pupọ lati ṣe ninu iṣẹ Oluwa” nigba gbogbo bi? Mo ha ń lépa iṣẹ igbesi-aye nipa ti ara lọna ìwárapàpà nigba ti mo lè maa fi ominira ti Ọlọrun fifun mi si ìlò ti o sàn jù nipa mímú iṣẹ-ojiṣẹ mi gbooro sii, ni nínàgà jade fun ẹrù-iṣẹ́ pupọ sii ninu ijọ tabi fun iṣẹ-isin alakooko kikun bi?’—1 Kọrinti 15:58, NW.
23. Ki ni a gbọdọ ṣe ki a má baa tàsé ète ominira ti Ọlọrun fi funni?
23 Njẹ ki gbogbo wa ‘tọ́ ọ wò, ki a sì ri pe rere ni Jehofa.’ (Saamu 34:8) Ẹ jẹ ki a nigbẹkẹle ninu rẹ̀, mu araawa bá awọn ofin rẹ̀ mu, ki a sì fogo fun orukọ mímọ́ rẹ̀ nipa fifi titaratitara kéde Ijọba rẹ̀. Ranti pe awọn wọnni ti ‘ń funrugbin ni yanturu yoo karugbin ni yanturu.’ (2 Kọrinti 9:6) Nitori naa, ẹ jẹ ki a ṣe iṣẹ-isin tọkantọkan si Jehofa ki a sì fihan pe awa kò tíì tàsé ète ominira ti Ọlọrun fifun wa.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Iru ominira wo ni Ọlọrun ní?
◻ Ominira eniyan ní awọn ààlà wo?
◻ Bawo ni a ṣe mú ominira tootọ ṣeeṣe?
◻ Ki ni a gbọdọ ṣe lati yẹra fun kikuna ète ominira ti Ọlọrun fi funni?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ominira eniyan ni a pààlà si nipa iru awọn okunfa bii ofin òòfà ilẹ̀