ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Léfítíkù

      • Ẹbọ ìrẹ́pọ̀ (1-17)

        • Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀rá tàbí ẹ̀jẹ̀ (17)

Léfítíkù 3:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹbọ àlàáfíà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 22:21; Nọ 6:13, 14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2000, ojú ìwé 15-16

Léfítíkù 3:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 7:29-31
  • +Ẹk 29:13; Le 7:23-25; 1Ọb 8:64

Léfítíkù 3:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 7:1-4

Léfítíkù 3:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 6:12
  • +Le 4:29, 31

Léfítíkù 3:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 6:13, 14

Léfítíkù 3:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:22; Le 9:18-20; 2Kr 7:7

Léfítíkù 3:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 4:8, 9; 9:10

Léfítíkù 3:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “búrẹ́dì,” ìyẹn, ìpín ti Ọlọ́run nínú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 4:31

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 11/2020, ojú ìwé 3

Léfítíkù 3:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 4:24, 26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    11/2019, ojú ìwé 22-23

Léfítíkù 3:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    11/2019, ojú ìwé 22-23

Léfítíkù 3:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 7:23; 1Sa 2:15-17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    11/2019, ojú ìwé 22-23

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 11/2020, ojú ìwé 3

Léfítíkù 3:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 9:4; Le 17:10, 13; Di 12:23; Iṣe 15:20, 29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2008, ojú ìwé 32

    5/15/2004, ojú ìwé 22

Àwọn míì

Léf. 3:1Le 22:21; Nọ 6:13, 14
Léf. 3:3Le 7:29-31
Léf. 3:3Ẹk 29:13; Le 7:23-25; 1Ọb 8:64
Léf. 3:4Le 7:1-4
Léf. 3:5Le 6:12
Léf. 3:5Le 4:29, 31
Léf. 3:6Nọ 6:13, 14
Léf. 3:9Ẹk 29:22; Le 9:18-20; 2Kr 7:7
Léf. 3:10Le 4:8, 9; 9:10
Léf. 3:11Le 4:31
Léf. 3:14Le 4:24, 26
Léf. 3:16Le 7:23; 1Sa 2:15-17
Léf. 3:17Jẹ 9:4; Le 17:10, 13; Di 12:23; Iṣe 15:20, 29
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Léfítíkù 3:1-17

Léfítíkù

3 “‘Tí ohun tó mú wá bá jẹ́ ẹbọ ìrẹ́pọ̀,*+ tó sì jẹ́ látinú ọ̀wọ́ ẹran ló ti fẹ́ mú un wá, yálà akọ tàbí abo, ẹran tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá ni kó mú wá fún Jèhófà. 2 Kó gbé ọwọ́ lé orí ẹran tó mú wá, kí wọ́n pa á ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé; kí àwọn ọmọ Áárónì, àwọn àlùfáà, sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 3 Kó fi lára ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà:+ ọ̀rá+ tó bo ìfun, gbogbo ọ̀rá tó yí ìfun ká 4 àti kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú rẹ̀. Kó tún yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, pẹ̀lú àwọn kíndìnrín+ ẹran náà. 5 Kí àwọn ọmọ Áárónì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ, lórí ẹbọ sísun tó wà lórí igi lórí iná;+ ọrẹ àfinásun tó ní òórùn dídùn* ló jẹ́ sí Jèhófà.+

6 “‘Tó bá jẹ́ látinú agbo ẹran ló ti fẹ́ mú ọrẹ wá fún Jèhófà láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, kó jẹ́ akọ tàbí abo tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá.+ 7 Tó bá jẹ́ ọmọ àgbò ló fẹ́ fi ṣe ọrẹ, kó mú un wá síwájú Jèhófà. 8 Kó gbé ọwọ́ lé orí ẹran tó mú wá, kí wọ́n sì pa á níwájú àgọ́ ìpàdé. Kí àwọn ọmọ Áárónì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 9 Kó mú ọ̀rá látinú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, kó fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.+ Kó gé ìrù rẹ̀ tó lọ́ràá nítòsí eegun ẹ̀yìn kúrò lódindi, ọ̀rá tó bo ìfun, gbogbo ọ̀rá tó yí ìfun ká, 10 pẹ̀lú kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú. Kó tún yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín+ náà. 11 Kí àlùfáà mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ bí oúnjẹ,* ọrẹ àfinásun sí Jèhófà+ ló jẹ́.

12 “‘Tó bá jẹ́ ewúrẹ́ ló fẹ́ fi ṣe ọrẹ, kó mú un wá síwájú Jèhófà. 13 Kó gbé ọwọ́ lé e lórí, kí wọ́n pa á níwájú àgọ́ ìpàdé, kí àwọn ọmọ Áárónì sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 14 Ibi tó máa fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà lára ẹran náà ni ọ̀rá tó bo ìfun, gbogbo ọ̀rá tó yí ìfun ká,+ 15 pẹ̀lú kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú. Kó tún yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín rẹ̀. 16 Kí àlùfáà mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ bí oúnjẹ, ọrẹ àfinásun tó máa mú òórùn dídùn* jáde ló jẹ́. Ti Jèhófà ni gbogbo ọ̀rá.+

17 “‘Ó jẹ́ àṣẹ tó máa wà fún àwọn ìran yín títí lọ, ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé: Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀rá tàbí ẹ̀jẹ̀+ èyíkéyìí.’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́