ORÍ KEJÌLÁ
Ìwọ́ Lè Borí Àwọn Ìṣòro Tí Ń Ṣe Ìdílé Lọ́ṣẹ́
1. Àwọn ìṣòro fífara sin wo ní ń bẹ nínú àwọn ìdílé kan?
AṢẸ̀ṢẸ̀ parí fífọ̀ àti nínu ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà ni. Lójú àwọn tí ń kọjá lọ, ó ń dán gbinrin, àfi bí agánrán. Ṣùgbọ́n lábẹ́nú, ara ọkọ̀ náà ti ń dípẹtà. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn ṣe rí nínú àwọn ìdílé kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní ìrísí òde, gbogbo rẹ̀ rí rèterète, ojú tí ń mú ẹ̀rín músẹ́ jáde bo ìbẹ̀rù àti ìrora mọ́lẹ̀. Níbi tí ojú àwọn ará ìta kò tó, àlàáfíà ìdílé ti ń dípẹtà. Àwọn ìṣòro méjì tí ó lè ní àbájáde yìí ni ìmukúmu àti ìwà ipá.
ỌṢẸ́ TÍ ÌMUKÚMU Ń ṢE
2. (a) Kí ni ojú ìwòye Bibeli nípa mímu ọtí? (b) Kí ni ìmukúmu?
2 Bibeli kò sọ pé mímu ọtí ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì burú, ṣùgbọ́n, ó sọ pé ó burú láti jẹ́ ọ̀mùtí. (Owe 23:20, 21; 1 Korinti 6:9, 10; 1 Timoteu 5:23; Titu 2:2, 3) Àmọ́, jíjẹ́ onímukúmu tún burú ju jíjẹ́ ọ̀mùtí lọ; ó jẹ́ mímu ọtí ní àmuyíràá nígbà gbogbo, àti àìlè ṣàkóso ara ẹni nítorí mímu ún. Àwọn onímukúmu lè jẹ́ àgbàlagbà. Ó bani nínú jẹ́ pé, wọ́n tún lè jẹ́ ọ̀dọ́.
3, 4. Ṣàpèjúwe àbájáde tí ìmukúmu ń ní lórí alábàáṣègbéyàwó onímukúmu náà àti àwọn ọmọ rẹ̀.
3 Tipẹ́tipẹ́ ni Bibeli ti fi hàn pé, ọtí àmujù lè ba àlàáfíà ìdílé jẹ́. (Deuteronomi 21:18-21) Gbogbo ìdílé látòkè délẹ̀ ni ń nímọ̀lára àbájáde búburú tí ìmukúmu ń mú wá. Aya lè kó wọ inú ìsapá láti mú kí ọkọ rẹ̀ jáwọ́ nínú mímùmukúmu ọtí tàbí láti kojú àwọn ìwà ọkọ rẹ̀ tí a kò lè sọ bí yóò ti rí.a Ó lè gbìyànjú láti máa gbé ọtí náà pamọ́, kí ó dà á nù, kí ó fi owó ọkọ rẹ̀ pamọ́, kí ó sì máa bẹ ọkọ rẹ̀ láti ro ti ìdílé, láti ro ìwàláàyè rẹ̀, kí ó sì tún máa fi Ọlọrun bẹ̀ ẹ́ pàápàá—ṣùgbọ́n kí onímukúmu náà ṣì máa gbà á pé. Bí ìsapá rẹ̀ léraléra láti ṣàkóso ọtí mímu ọkọ rẹ̀ ti ń já sí pàbó, yóò máa nímọ̀lára ìjákulẹ̀ àti àìtóótun. Ẹ̀rù lè bẹ̀rẹ̀ sí í bà á, kí inú máa bí i, kí ó bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára ẹ̀bi, kí ara rẹ̀ máà lélẹ̀, kí ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn, kí ó máà sì ní ọ̀wọ̀ ara ẹni.
4 Àbájáde ìmukúmu òbí kò yọ àwọn ọmọ sílẹ̀. A ń ṣe àwọn mìíràn léṣe. A ń fi ìbálòpọ̀ fìtínà àwọn mìíràn. Wọ́n tilẹ̀ lè dá ara wọn lẹ́bi fún bí òbí kan ṣe ń mu ọtí nímukúmu. Léraléra, ìwà ségesège onímukúmu náà ń ba ìgbẹ́kẹ̀lé wọn nínú àwọn ẹlòmíràn jẹ́. Nítorí pé, wọn kò lè fara balẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé, àwọn ọmọ náà lè kọ́ láti pa ìmọ̀lára wọn mọ́, èyí tí ó sì sábà ń ní àbájáde burúkú nípa ti ara. (Owe 17:22) Irú ìwà àìnígbọkànlé nínú ara ẹni tàbí àìní ọ̀wọ̀ ara ẹni yìí lè bá àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ dàgbà.
KÍ NI ÌDÍLÉ NÁÀ LÈ ṢE?
5. Báwo ni a ṣe lè bójú tó ìmukúmu, èé sì ti ṣe tí èyí fi ṣòro?
5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ amòye sọ pé ìmukúmu kò gbóògùn, ọ̀pọ̀ jù lọ fohùn ṣọ̀kan pé, ìkọ́fẹpadà dé ìwọ̀n àyè kan ṣeé ṣe pẹ̀lú ìtòlẹ́sẹẹsẹ yíyàgò pátápátá. (Fi wé Matteu 5:29.) Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnú dùn ún ròfọ́, agada ọwọ́ sì ṣeé bẹ́ gẹdú ni ọ̀rọ̀ mímú kí onímukúmu kan tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́, níwọ̀n bí òun yóò ti máa fìgbà gbogbo sẹ́ ìṣòro tí ó ní. Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé bá gbé ìgbésẹ̀ láti kojú ọ̀nà tí ìmukúmu náà ti gbà ní ipa lórí wọn, onímukúmu náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé òún ní ìṣòro. Oníṣègùn kan tí ó ti ní ìrírí nínú ríran àwọn onímukúmu àti ìdílé wọn lọ́wọ́ wí pé: “Mo rò pé ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé kí ìdílé náà máa bá ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́ lọ lọ́nà tí ó lè ṣàǹfààní fún wọn jù lọ. Onímukúmu náà yóò túbọ̀ máa rí i bí ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín òun àti àwọn mẹ́ḿbà ìdílé yòókù ti gbòòrò tó.”
6. Kí ni orísun ìmọ̀ràn dídára jù lọ fún àwọn ìdílé tí wọ́n ní mẹ́ḿbà tí ó jẹ́ onímukúmu?
6 Bí onímukúmu bá wà nínú ìdílé rẹ, ìmọ̀ràn Bibeli tí a mí sí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé lọ́nà tí ó ṣàǹfààní jù lọ. (Isaiah 48:17; 2 Timoteu 3:16, 17) Gbé àwọn ìlànà kan yẹ̀ wò tí ó ti ran àwọn ìdílé lọ́wọ́ láti kojú ìmukúmu pẹ̀lú àṣeyọrí.
7. Bí mẹ́ḿbà kan bá jẹ́ onímukúmu, ta ni ó jẹ̀bi?
7 Dáwọ́ títẹ́wọ́ gba gbogbo ẹ̀bi náà dúró. Bibeli sọ pé: “Olúkúlùkù ni yoo ru ẹrù ti ara rẹ̀,” pẹ̀lúpẹ̀lù, “olúkúlùkù wa ni yoo ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọrun.” (Galatia 6:5; Romu 14:12) Onímukúmu náà lè gbìyànjú láti di ẹ̀bi náà lè ìdílé rẹ̀ lórí. Fún àpẹẹrẹ, ó lè sọ pé: “Ká ní ẹ ti bá mi lò lọ́nà tí ó dára ni, n kì bá mu ọtí.” Bí àwọn mìíràn bá gbà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n ń fún un níṣìírí láti máa bá mímu ọtí nìṣó. Kódà, bí ó bá jẹ́ àyíká ipò tàbí àwọn ènìyàn míràn ni ó nípa lórí wa, gbogbo wa pátá—títí kan àwọn onímukúmu—ni yóò jíhìn fún ohun tí a bá ṣe.—Fi wé Filippi 2:12.
8. Àwọn ọ̀nà díẹ̀ wo ni a lè gbà ran onímukúmu náà lọ́wọ́ láti kojú àwọn àbájáde ìṣòro rẹ̀?
8 Má ṣe rò pé ìgbà gbogbo ni ìwọ yóò máa dáàbò bo onímukúmu náà lọ́wọ́ àbájáde ọtí mímu rẹ̀. Òwe Bibeli nípa ẹnì kan tí ń bínú lè ṣeé lò lọ́nà kan náà fún onímukúmu náà pé: “Bí ìwọ bá gbà á, síbẹ̀ ìwọ óò tún ṣe é.” (Owe 19:19) Jẹ́ kí onímukúmu náà jìyà àbájáde ọtí mímu rẹ̀. Jẹ́ kí ó fúnra rẹ̀ fọ ẹ̀gbin tí ó ti ṣe mọ́ tónítóní tàbí kí ó tẹ ẹni tí ó gbà á síṣẹ́ láago ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì tí ọ̀ran ọtí mímu rẹ̀ ṣẹlẹ̀.
9, 10. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn ìdílé ẹni tí ó jẹ́ onímukúmu náà tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́, ìrànlọ́wọ́ àwọn wo ni wọ́n ní láti wá ní pàtàkì?
9 Tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Owe 17:17 sọ pé: “Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n arákùnrin ni a bí fún ìgbà ìpọ́njú.” Nígbà tí onímukúmu bá wà nínú ìdílé rẹ, ìrora ọkàn ń bẹ. O nílò ìrànlọ́wọ́. Má ṣe lọ́ra láti gbára lé ‘àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́’ fún ìrànlọ́wọ́. (Owe 18:24) Bíbá àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n lóye ìṣòro náà, tàbí tí wọ́n ti dojú kọ irú ipò kan náà sọ̀rọ̀, lè pèsè àwọn àbá gbígbéṣẹ́ fún ọ, lórí ohun tí o lè ṣe àti ohun tí o kò gbọdọ̀ ṣe. Ṣùgbọ́n wà déédéé. Bá àwọn tí o gbẹ́kẹ̀ lé sọ̀rọ̀, àwọn tí yóò pa “ọ̀rọ̀ àṣírí” rẹ mọ́.—Owe 11:13.
10 Kọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé àwọn Kristian alàgbà. Àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristian lè jẹ́ orísun ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n dàgbà dénú wọ̀nyí ní ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun dáradára, wọ́n sì jáfáfá nínú bí a ṣeé ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò. Wọ́n lè jẹ́ “ibi ìlùmọ́ kúrò lójú ẹ̀fúùfù, àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì; bí odò omi ní ibi gbígbẹ, bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ gbígbẹ.” (Isaiah 32:2) Kì í ṣe kìkì pé àwọn Kristian alàgbà ń dáàbò bo ìjọ lódindi kúrò lọ́wọ́ àwọn agbára ìdarí aṣeniléṣe nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún ń tuni nínú, wọ́n ń tuni lára, wọ́n sì ń ní ọkàn-ìfẹ́ ara ẹni nínú àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ní ìṣòro. Lo àǹfààní ìrànlọ́wọ́ wọn dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́.
11, 12. Ta ní ń pèsè ìrànlọ́wọ́ títóbi jù lọ fún àwọn ìdílé tí wọ́n ní onímukúmu, báwo sì ni a ṣe ń pèsè ìrànlọ́wọ́ náà?
11 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, gba okun láti ọ̀dọ̀ Jehofa. Bibeli fi tìfẹ́tìfẹ́ mú un dá wa lójú pé: “Oluwa ń bẹ létí ọ̀dọ̀ àwọn tí í ṣe oníròbìnújẹ́ ọkàn; ó sì gba irú àwọn tí í ṣe onírora ọkàn là.” (Orin Dafidi 34:18) Bí o bá nímọ̀lára ìròbínújẹ́ ọkàn tàbí tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ nítorí pákáǹleke ti bíbá mẹ́ḿbà ìdílé tí ó jẹ́ onímukúmu gbé pọ̀, mọ̀ pé ‘Oluwa ń bẹ létí ọ̀dọ̀ rẹ.’ Ó lóye bí ipò ìdílé rẹ ti nira tó.—1 Peteru 5:6, 7.
12 Gbígba ohun tí Jehofa sọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú àníyàn. (Orin Dafidi 130:3, 4; Matteu 6:25-34; 1 Johannu 3:19, 20) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀ ń mú kí ó ṣeé ṣe fún ọ láti rí ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun gbà, tí ó lè fún ọ ní “agbára tí ó rékọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” láti lè máa fara dà á láti ọjọ́ dé ọjọ́.—2 Korinti 4:7.b
13. Ìṣòro kejì wo ni ó ń ṣe ọ̀pọ̀ ìdílé lọ́ṣẹ́?
13 Mímu ọtí ní àmujù lè yọrí sí ìṣòro mìíràn tí ń ṣe ọṣẹ́ nínú ìdílé—ìwà ipá abẹ́lé.
ỌṢẸ́ TÍ ÌWÀ IPÁ ABẸ́LÉ Ń ṢE
14. Nígbà wo ni ìwà ipá abẹ́lé bẹ̀rẹ̀, báwo sì ni ipò náà ti rí lónìí?
14 Ìṣẹ̀lẹ̀ ìwà ipá abẹ́lé kan láàárín tẹ̀gbọ́n tàbúrò, Kaini àti Abeli, ni ìwà ipá àkọ́kọ́ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. (Genesisi 4:8) Láti ìgbà náà wá, onírúurú ìwà ipá abẹ́lé ti ń pọ́n aráyé lójú. Àwọn ọkọ tí ń lu aya wọn ní àlùbolẹ̀ ń bẹ, àwọn aya tí ń gbéjà ko ọkọ wọ́n wà, àwọn òbí tí ń lu àwọn ọmọ wọn kéékèèké bí ẹní máa kú wà, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọmọ tí wọ́n ti dàgbà tí wọ́n ń hùwà ìkà sí àwọn òbí wọn àgbàlagbà.
15. Báwo ni ìwà ipá abẹ́lé ṣe ń nípa lórí èrò ìmọ̀lára àwọn mẹ́ḿbà ìdílé?
15 Ọṣẹ́ tí ìwà ipá abẹ́lé ń ṣe ré kọjá àwọn àpá ti a lè fojú rí fíìfíì. Obìnrin kan tí a máa ń lù ní àlùbolẹ̀ wí pé: “Ọ̀pọ̀ ẹ̀bi àti ìtìjú ń bẹ tí o ní láti kojú. Ní òwúrọ̀ púpọ̀ jù lọ, ìwọ yóò wulẹ̀ fẹ́ láti wà lórí ibùsùn, ní rírò pé àlá burúkú lásán ni.” Àwọn ọmọdé tí wọ́n fojú rí ìwà ipá abẹ́lé tàbí tí wọ́n nírìírí rẹ̀ lè jẹ́ oníwà ipá nígbà tí wọ́n bá dàgbà, tí àwọn náà sì ní ìdílé tiwọn fúnra wọn.
16, 17. Kí ni ṣíṣeni léṣe ní ti èrò ìmọ̀lára, báwo sì ni ó ṣe ń nípa lórí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé?
16 Ìwà ipá abẹ́lé kò mọ sórí ṣíṣeni léṣe nípa ti ara nìkan. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìkọlù náà lè jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ ẹnu. Owe 12:18 sọ pé: “Àwọn kan ń bẹ tí ń yára sọ̀rọ̀ lásán bí ìgúnni idà.” Àwọn ‘ohun tí ń gúnni’ wọ̀nyí tí a fi ń dá ìwà ipá abẹ́lé mọ̀, ní nínú, pípeni lórúkọ burúkú àti pípariwo léni lórí, bákan náà sì ni ṣíṣe lámèyítọ́ ẹni nígbà gbogbo, ọ̀rọ̀ ìwọ̀sí, àti fífi ìwà ipá wuni léwu. Àwọn ọgbẹ́ ìwà ipá ní ti èrò ìmọ̀lára kò ṣeé fojú rí, àwọn ẹlòmíràn kì í sì í sábà kíyè sí i.
17 Èyí tí ó bani nínú jẹ́ ní pàtàkì jù lọ ni ṣíṣe ọmọdé léṣe ní ti èrò ìmọ̀lára—ṣíṣe lámèyítọ́ nígbà gbogbo àti fífojú kéré agbára ìṣe tí ọmọ kan ní, fífojú kéré òye rẹ̀, tàbí bí ó ṣe ṣeyebíye tó gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. Irú ọ̀rọ̀ èébú bẹ́ẹ̀ lè pa ẹ̀mí ọmọdé kan run. Òtítọ́ ni pé, gbogbo ọmọdé nílò ìbáwí. Ṣùgbọ́n Bibeli fún àwọn bàbá ní ìtọ́ni pé: “Ẹ máṣe máa dá awọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má baà soríkodò.”—Kolosse 3:21.
BÍ A ṢE LÈ YẸRA FÚN ÌWÀ IPÁ ABẸ́LÉ
18. Níbo ni ìwà ipá abẹ́lé ti ń bẹ̀rẹ̀, kí sì ni Bibeli fi hàn pé ó jẹ́ ọ̀nà tí a lè gbà kiwọ́ rẹ̀ bọlẹ̀?
18 Ìwà ipá abẹ́lé ń bẹ̀rẹ̀ nínú ọkàn-àyà àti èrò inú; bí a ṣe ń hùwà ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú bí a ṣe ń ronú. (Jakọbu 1:14, 15) Láti kiwọ́ ìwà ipá náà bọlẹ̀, ẹni tí ń hùwà ìkà síni náà ní láti yí bí ó ṣe ń ronú padà. (Romu 12:2) Èyí ha ṣeé ṣe bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní agbára láti yí àwọn ènìyàn padà. Ó lè fa àwọn ojú ìwòye aṣekúpani “tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in-gbọn-in” tu pàápàá. (2 Korinti 10:4; Heberu 4:12) Ìmọ̀ pípéye nípa Bibeli lè ṣèrànwọ́ láti mú ìyípadà pátápátá bá àwọn ènìyàn, débi tí a óò fi lè sọ pé wọ́n gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀.—Efesu 4:22-24; Kolosse 3:8-10.
19. Ojú wo ni ó yẹ kí Kristian kan fi wo alábàáṣègbéyàwó rẹ̀, báwo sì ni ó ṣe yẹ kí ó máa bá a lò?
19 Ojú tí a fi ń wo alábàáṣègbéyàwó ẹni. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wí pé: “Ó yẹ kí awọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ awọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara awọn fúnra wọn. Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀.” (Efesu 5:28) Bibeli tún sọ pé ọkọ ní láti fún aya rẹ̀ ní “ọlá . . . gẹ́gẹ́ bí fún ohun-ìlò aláìlerató.” (1 Peteru 3:7) A ṣí àwọn aya létí “lati nífẹ̀ẹ́ awọn ọkọ wọn,” kí wọ́n sì ní “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” fún wọn. (Titu 2:4; Efesu 5:33) Ó dájú pé, kò sí ọkọ kan tí ó bẹ̀rù Ọlọrun tí yóò fi tòótọ́tòótọ́ sọ pé, òun ń bọlá fún aya òun ní tòótọ́, bí òún bá ń ṣe é léṣe tàbí tí òún ń bú u. Kò sì sí aya kan tí ń pariwo lé ọkọ rẹ̀ lórí, tàbí tí ń fi ọ̀rọ̀ aṣa bá a sọ̀rọ̀, tàbí tí ń bá a jà nígbà gbogbo tí ó lè sọ ní tòótọ́ pé, òún nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, òún sì ń bọ̀wọ̀ fún un.
20. Ta ni àwọn òbí yóò jíhìn fún lórí àwọn ọmọ wọn, èé sì ti ṣe tí kò fi yẹ kí àwọn òbí fojú kéré agbára ìṣe àwọn ọmọ wọn?
20 Ojú ìwòye tí ó tọ́ nípa àwọn ọmọ. Ìfẹ́ àti àfíyèsí àwọn òbí tọ́ sí àwọn ọmọ, àní, wọ́n nílò rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pe àwọn ọmọ ní “ìní Oluwa” àti “èrè rẹ̀.” (Orin Dafidi 127:3) Ẹrù iṣẹ́ àwọn òbí ni níwájú Jehofa láti bójú tó ogún ìní yẹn. Bibeli sọ̀rọ̀ nípa “awọn ọ̀nà ìhùwà ìkókó” àti “ìwà òmùgọ̀” ìgbà ọmọdé. (1 Korinti 13:11; Owe 22:15, NW) Kò yẹ kí ó ya àwọn òbí lẹ́nu bí wọ́n bá dojú kọ ìwà òmùgọ̀ tí ń bẹ nínú àwọn ọmọ wọn. Àwọn ògowẹẹrẹ kì í ṣe àgbàlagbà. Kò yẹ kí àwọn òbí béèrè ju ohun tí ọjọ́ orí ọmọ kan, ipò àtilẹ̀wá ìdílé, àti ohun tí agbára rẹ̀ gbé lọ.—Wo Genesisi 33:12-14.
21. Ojú wo ni ó bá ìfẹ́ Ọlọrun mú láti fi wo àwọn òbí tí wọ́n ti dàgbà àti láti bá wọn lò?
21 Ojú tí a fi ń wo àwọn òbí tí wọ́n ti dàgbà. Lefitiku 19:32 sọ pé: “Kí ìwọ kí ó sì dìde dúró níwájú orí ewú, kí o sì bọ̀wọ̀ fún ojú arúgbó.” Òfin Ọlọrun tipa báyìí fún ọ̀wọ̀ àti ìkàsí ńláǹlà fún àwọn àgbàlagbà níṣìírí. Èyí lè jẹ́ ìpènijà nígbà tí ó bà dà bíi pé òbí kan tí ó ti dàgbà ń béèrè ju ohun tí agbára ẹní gbé lọ tàbí tí ó ń ṣàìsàn, bóyá tí kì í yára rìn tàbí yára ronú. Síbẹ̀, a rán àwọn ọmọ létí láti “máa san ìsanfidípò yíyẹ fún awọn òbí wọn.” (1 Timoteu 5:4) Èyí yóò túmọ̀ sí bíbá wọn lò pẹ̀lú ọlá àti ọ̀wọ̀, bóyá pípèsè fún wọn ní ti ọ̀ràn ìnáwó pàápàá. Híhùwà ìkà nípa ti ara sí àwọn òbí tí wọ́n ti dàgbà tàbí híhùwà ìkà sí wọn lọ́nà míràn ta ko bí Bibeli ṣe ní kí á hùwà pátápátá.
22. Kí ni ànímọ́ pàtàkì nínú bíborí ìwà ipá abẹ́lé, báwo sì ni a ṣe lè lò ó?
22 Mú ìkóra-ẹni-níjàánu dàgbà. Owe 29:11 sọ pé: “Aṣiwèrè a sọ gbogbo inú rẹ̀ jáde: ṣùgbọ́n ọlọgbọ́n a pa á mọ́ di ìgbà ìkẹyìn.” Báwo ni o ṣe lè ṣàkóso ẹ̀mí rẹ? Dípò jíjẹ́ kí ìbínú gbèrú nínú lọ́hùn-ún, tètè yanjú àwọn ìṣòro tí ó bá dìde. (Efesu 4:26, 27) Fi ibẹ̀ sílẹ̀ bí o bá nímọ̀lára pé o kò lè ṣàkóso ara rẹ mọ́. Gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun láti mú kí o ní ìkóra-ẹni-níjàánu. (Galatia 5:22, 23) Dídọ́gbẹ̀ẹ́rẹ́ tàbí lílọ́wọ́ nínú àwọn eré ìmárale kan lè ṣèrànwọ́ láti ṣàkóso èrò ìmọ̀lára rẹ. (Owe 17:14, 27) Sakun láti “lọ́ra láti bínú.”—Owe 14:29.
PÍPÍNYÀ TÀBÍ GBÍGBÉ PA PỌ̀?
23. Kí ni ó lè ṣẹlẹ̀ bí mẹ́ḿbà kan nínú ìjọ Kristian bá ń hu ìwà ipá onírufùfù ìbínú léraléra, láìronú pìwà dà, bóyá tí ó tún ń ṣe ìdílé rẹ̀ léṣe nípa ti ara?
23 Bibeli ka “ìṣọ̀tá, gbọ́nmisi-omi-ò-to, . . . ìrufùfù ìbínú,” mọ́ àwọn iṣẹ́ tí Ọlọrun kò fọwọ́ sí, ó sì sọ pé “awọn wọnnì tí ń fi irúfẹ́ awọn nǹkan báwọ̀nyí ṣèwàhù kì yoo jogún ìjọba Ọlọrun.” (Galatia 5:19-21) Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ pé òún jẹ́ Kristian tí ó sì ń hu ìwà ipá onírufùfù ìbínú léraléra, láìronú pìwà dà, bóyá tí ó tún ń ṣe alábàáṣègbéyàwó tàbí àwọn ọmọ léṣe, ni a lè yọ lẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ Kristian. (Fi wé 2 Johannu 9, 10.) Ní ọ̀nà yìí, a óò mú kí ìjọ wà ní mímọ́ tónítóní kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ń hùwà ìkà síni.—1 Korinti 5:6, 7; Galatia 5:9.
24. (a) Báwo ni àwọn alábàáṣègbéyàwó tí a ti ṣe léṣe ṣe lè yàn láti hùwà padà? (b) Báwo ni àwọn alàgbà àti àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n bìkítà ṣe lè ṣèrànwọ́ fún àwọn alábàáṣègbéyàwó tí a ti ṣe léṣe, ṣùgbọ́n kí ni kò yẹ kí wọ́n ṣe?
24 Àwọn Kristian tí alábàáṣègbéyàwó wọn ń lù ní àlùbolẹ̀ nísinsìnyí ńkọ́, tí kò sì fi àmì ìyípadà kankan hàn? Àwọn kan ti yàn láti dúró ti alábàáṣègbéyàwó tí ń ṣe wọ́n léṣe náà, fún ìdí kan tàbí òmíràn. Àwọn mìíràn ti yàn láti kó jáde, ní níní ìmọ̀lára pé, ìlera wọn nípa ti ara, ti èrò orí, àti tẹ̀mí—àní bóyá ìwàláàyè wọn pàápàá—wà nínú ewu. Ohun tí ẹnì kan tí ó jìyà ìwà ipá abẹ́lé bá yàn láti ṣe nínú àwọn àyíká ipò wọ̀nyí jẹ́ ìpinnu ara ẹni níwájú Jehofa. (1 Korinti 7:10, 11) Àwọn ọ̀rẹ́ afẹ́nifẹ́re, àwọn ẹbí, tàbí àwọn Kristian alàgbà lè fẹ́ láti ṣèrànwọ́, kí wọ́n sì fúnni ní ìmọ̀ràn, ṣùgbọ́n wọn kò ní láti fipá mú òjìyà kan láti gbé ìgbésẹ̀ kan pàtó. Ìpinnu ti ara rẹ̀ nìyẹn.—Romu 14:4; Galatia 6:5.
ÒPIN ÀWỌN ÌṢÒRO TÍ Ń ṢỌṢẸ́
25. Kí ni ète Jehofa fún ìdílé?
25 Nígbà tí Jehofa so Adamu àti Efa pọ̀ nínú ìgbéyàwó, kò fìgbà kankan pète pé àwọn ìṣòro tí ń ṣọṣẹ́, irú bí ìmukúmu tàbí ìwà ipá, yóò máa ba ìdílé jẹ́ díẹ̀díẹ̀. (Efesu 3:14, 15) Ó fẹ́ kí ìdílé jẹ́ ibi tí ìfẹ́ àti àlàáfíà yóò ti gbilẹ̀, tí a óò sì bójú tó àìní mẹ́ḿbà kọ̀ọ̀kan ní ti èrò orí, èrò ìmọ̀lára, àti nípa tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó yọjú, ìgbésí ayé ìdílé jó àjórẹ̀yìn kíámọ́sá.—Fi wé Oniwasu 8:9.
26. Ọjọ́ ọ̀la wo ni ó dúró de àwọn tí wọ́n ń gbìyànjú láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí Jehofa béèrè fún?
26 Ó múni láyọ̀ pé, Jehofa kò tí ì pa ète rẹ̀ fún ìdílé tì. Ó ṣèlérí láti mú ayé tuntun alálàáfíà kan wá nínú èyí tí àwọn ènìyàn “yóò wà ní àlàáfíà ẹnikẹ́ni kì yóò sì dẹ́rù bà wọ́n.” (Esekieli 34:28) Ní àkókò yẹn, ìmukúmu, ìwà ipá abẹ́lé, àti gbogbo àwọn ìṣòro mìíràn tí ń ṣe ìdílé lọ́ṣẹ́ lónìí, yóò di ohun àtijọ́. Àwọn ènìyàn yóò rẹ́rìn-ín músẹ́, kì í ṣe láti fi bo ìbẹ̀rù àti ìrora wọn mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí pé, wọ́n ń rí “inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—Orin Dafidi 37:11.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tọ́ka sí i pé ọkùnrin ni onímukúmu náà, àwọn ìlànà tí ó wà níhìn-ín tún ṣeé mú lò bí onímukúmu náà bá jẹ́ obìnrin.
b Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, wọ́n ní àwọn ibùdó ìtọ́jú, ilé ìwòsàn, àti àwọn ètò ìkọ́fẹpadà, tí ó wà fún ríran àwọn onímukúmu àti ìdílé wọn lọ́wọ́. Yálà láti wá irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ tàbí láti má ṣe wá a, jẹ́ ìpinnu ara ẹni. Watch Tower Society kò fàṣẹ sí ọ̀nà ìtọ́jú kan ní pàtó. Bí ó ti wù kí ó rí, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ó má baà jẹ́ pé, ní wíwá ìrànlọ́wọ́ kiri, ẹnì kan yóò tibẹ̀ lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tí ń fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ báni dọ́rẹ̀ẹ́.
BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN . . . ÀWỌN ÌDÍLÉ LÁTI YẸRA FÚN ÀWỌN ÌṢÒRO TÍ Ó LÈ ṢỌṢẸ́ RÍRINLẸ̀?
Jehofa kò fọwọ́ sí mímu ọtí ní àmujù.—Owe 23:20, 21.
Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni yóò jíhìn fún àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.—Romu 14:12.
Láìsí ìkóra-ẹni-níjàánu a kò lè ṣiṣẹ́ sin Ọlọrun lọ́nà tí ó tẹ́wọ́ gbà.—Owe 29:11.
Àwọn ojúlówó Kristian ń bọlá fún àwọn òbí wọn tí wọ́n ti dàgbà.—Lefitiku 19:32.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 146]
Àwọn Kristian alàgbà lè jẹ́ orísun ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà nínú yíyanjú àwọn ìṣòro ìdílé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 151]
Àwọn tọkọtaya Kristian tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ara wọn, yòó gbé ìgbésẹ̀ kíámọ́sá láti yanjú aáwọ̀