ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • fy orí 10 ojú ìwé 116-127
  • Nígbà Tí Mẹ́ḿbà Kan Nínú Ìdílé Bá Ń Ṣàìsàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nígbà Tí Mẹ́ḿbà Kan Nínú Ìdílé Bá Ń Ṣàìsàn
  • Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KÍ NI ÌMỌ̀LÁRA RẸ NÍPA RẸ̀?
  • Ẹ̀MÍ TÍ Ń WONI SÀN
  • GBÍGBÉ ÀWỌN OHUN ÀKỌ́MÚṢE KALẸ̀
  • RÍRAN ÀWỌN ỌMỌ LỌ́WỌ́
  • OJÚ TÍ Ó YẸ KÍ A FI WO ÌTỌ́JÚ ÌṢÈGÙN
  • Ṣé Èṣù Ló Ń Jẹ́ Ká Ṣàìsàn Ni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Àìsàn Ò Ní Sí Mọ́!
    Jí!—2007
  • Jóòbù Jẹ́ Oníwà Títọ́ ó Sì Ní Ìfaradà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Aráyé Ń Fẹ́ Ìlera Tó Jíire!
    Jí!—2007
Àwọn Míì
Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
fy orí 10 ojú ìwé 116-127

ORÍ KẸWÀÁ

Nígbà Tí Mẹ́ḿbà Kan Nínú Ìdílé Bá Ń Ṣàìsàn

1, 2. Báwo ni Satani ṣe gbìyànjú láti lo ìbànújẹ́ àti àìsàn láti ba ìwà títọ́ Jobu jẹ́?

DÁJÚDÁJÚ, a gbọ́dọ̀ ka ọkùnrin náà, Jobu, mọ́ ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n gbádùn ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀. Bibeli pè é ní ‘ọkùnrin tí ó pọ̀ ju gbogbo àwọn ọmọ ará ìlà oòrùn lọ.’ Ó bí ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta, gbogbo wọ́n jẹ́ mẹ́wàá. Ó tún rí já jẹ. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó mú ipò iwájú nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí, ipò àwọn ọmọ rẹ̀ níwájú Jehofa sì jẹ ẹ́ lógún. Gbogbo èyí yọrí sí ìdè ìdílé tí ó yi típẹ́típẹ́, tí ó sì jẹ́ aláyọ̀.​—Jobu 1:​1-5.

2 Satani, olórí ọ̀tá Jehofa Ọlọrun, kíyè sí bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún Jobu. Satani, ẹni tí ó máa ń wá ọ̀nà láti ba ìwà títọ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun jẹ́ nígbà gbogbo, gbéjà ko Jobu nípa bíba ìdílé aláyọ̀ rẹ̀ jẹ́. Lẹ́yìn náà, ó “sọ Jobu ní oówo kíkankíkan láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ lọ dé àtàrí rẹ̀.” Nípa báyìí, Satani retí láti lo ìbànújẹ́ àti àìsàn láti ba ìwà títọ́ Jobu jẹ́.​—Jobu 2:​6, 7.

3. Kí ni àwọn àmì àrùn àmódi Jobu?

3 Bibeli kò sọ orúkọ tí àwọn oníṣègùn ń pe àrùn tí ó kọ lu Jobu. Ṣùgbọ́n, ó sọ àwọn àmì àrùn náà fún wa. Ìdin bo ara rẹ̀, awọ ara rẹ̀ ń tèépá, ó sì ń jẹrà. Èémí Jobu ń rùn ràì, òórùn burúkú sì ń ti ara rẹ̀ jáde. Ó ń jẹ̀rora látòkèdélẹ̀. (Jobu 7:5; 19:17; 30:​17, 30) Nínú ìpọ́njú líle koko, Jobu jókòó sínú eérú, ó sì ń fi àpáàdì họ ara rẹ̀. (Jobu 2:8) Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ ìran tí ń múni káàánú tó!

4. Kí ni ìdílé kọ̀ọ̀kan máa ń nírìírí rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan?

4 Báwo ni ìwọ yóò ṣe hùwà padà bí irú àrùn burúkú bẹ́ẹ̀ bá kọ lù ọ́? Lónìí, Satani kì í fi àìsàn kọ lu àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún Jobu. Síbẹ̀, lójú ìwòye àìpé ẹ̀dá ènìyàn, àwọn másùnmáwo ìgbésí ayé ojoojúmọ́, àti àyíká tí a ń gbé tí ń bàjẹ́ sí i, a ní láti retí pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn mẹ́ḿbà ìdílé lè ṣàìsàn. Láìka àwọn ọgbọ́n ìdènà àìsàn tí a lè lò sí, gbogbo wa ni a lè ṣàìsàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn díẹ̀ péré ni yóò jìyà tó Jobu. Nígbà tí àìsàn bá wọ agbo ìdílé wa, ó lè jẹ́ ìpènijà ní tòótọ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a wo bí Bibeli ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ọ̀tá aráyé tí ó máa ń fìgbà gbogbo yọ aráyé lẹ́nu.​—Oniwasu 9:11; 2 Timoteu 3:16.

KÍ NI ÌMỌ̀LÁRA RẸ NÍPA RẸ̀?

5. Báwo ni àwọn mẹ́ḿbà ìdílé ṣe sábà máa ń hùwà padà sí àìsàn onígbà díẹ̀?

5 Àìrójúráyè fún ìgbòkègbodò ìgbésí ayé ojoojúmọ́, láìka ohun tí ó lè fà á sí, máa ń ṣòro, èyí sì máa ń jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì bí ó bá jẹ́ àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ ni ó fa àìrójúráyè náà. Kódà, àmódi onígbà díẹ̀ pàápàá ń béèrè fún àtúnṣebọ̀sípò, títẹ́wọ́ gba bí nǹkan ti rí, àti ìrúbọ. Àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí ara wọ́n le, lè ní láti pa rọ́rọ́, kí ẹni tí ń ṣàìsàn náà lè sinmi. Wọ́n lè ní láti pa àwọn ìgbòkègbodò kan tì. Síbẹ̀, ní àwọn ìdílé tí ó pọ̀ jù lọ, àwọn ọmọ kéékèèké pàápàá ń ṣàánú ẹ̀gbọ́n wọn, àbúrò wọn, tàbí òbí wọn tí ń ṣàìsàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a lè ní láti rán wọn létí láti jẹ́ onírònú. (Kolosse 3:12) Nínú ọ̀ràn àìsàn onígbà kúkúrú, ìdílé sábà máa ń wà ní sẹpẹ́ láti ṣe ohun tí ó bá yẹ ní ṣíṣe. Yàtọ̀ sí ìyẹn, mẹ́ḿbà ìdílé kọ̀ọ̀kan yóò retí irú ìgbatẹnirò kan náà, bí òun náà bá ṣàìsàn.​—Matteu 7:12.

6. Àwọn ìhùwàpadà wo ni a sábà máa ń rí bí àìsàn líle koko, tí kò lọ bọ̀rọ̀ bá kọ lu mẹ́ḿbà kan nínú ìdílé?

6 Ṣùgbọ́n, bí àmódi náà bá le ńkọ́, tí wàhálà náà sì ṣẹlẹ̀ lójijì, tí ó sì wà fún ìgbà pípẹ́? Fún àpẹẹrẹ, bí àrùn rọpárọsẹ̀ bá kọ lu ẹnì kan nínú ìdílé náà ńkọ́, tàbí tí àrùn ọdẹ orí abọ́jọ́-ogbórìn kò bá jẹ́ kí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, tàbí tí àmódi mìíràn bá sọ ọ́ di aláìlera? Tàbí bí àrùn ọpọlọ bá kọ lu mẹ́ḿbà kan nínú ìdílé náà ńkọ́, irú bíi ìṣiṣẹ́gbòdì ọpọlọ? Ìhùwàpadà àkọ́kọ́ tí ó sábà máa ń wáyé ni kíkáàánú​—ìbànújẹ́ pé ẹnì kan tí a fẹ́ràn ń jìyà gan-an. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìhùwàpadà míràn máa ń tẹ̀ lé ìkáàánú. Bí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé ṣe ń rí bí àìsàn mẹ́ḿbà kan ṣe ń nípa lórí wọn àti bí ó ṣe ń dín òmìnira wọn kù, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í bínú. Wọ́n lè ṣe kàyéfì pé: “Èé ṣe tí èyí fi ní láti ṣẹlẹ̀ sí mi?”

7. Báwo ni aya Jobu ṣe hùwà padà sí àìsàn ọkọ rẹ̀, kí sì ni ó dájú pé ó gbàgbé?

7 Ó dà bíi pé ohun kan náà ni ó wá sí aya Jobu lọ́kàn. Rántí pé, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀ ni. Bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ yẹn ṣe ń ṣẹlẹ̀, kò sí iyè méjì pé ọkàn rẹ̀ dàrú. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, bí ó ṣe rí ọkọ rẹ̀ tí ó ti fìgbà kan rí jẹ́ ọ̀jáfáfá, alágbára, tí àrùn tí ń roni gógó, tí ó sì ń kóni nírìíra, sọ di ahẹrẹpẹ, ó dà bíi pé ó pàdánù kókó pàtàkì tí ó ju àwọn ọ̀ràn ìbànújẹ́ náà lọ​—ipò ìbátan tí òun pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ ní pẹ̀lú Ọlọrun. Bibeli sọ pé: “Nígbà náà ni aya [Jobu] wí fún un pé, ìwọ́ di ìwà òtítọ́ rẹ mú síbẹ̀! bú Ọlọrun, kí o sì kú.”​—Jobu 2:9.

8. Nígbà tí mẹ́ḿbà kan nínú ìdílé bá ń ṣàìsàn gidigidi, ẹsẹ ìwé mímọ́ wo ni yóò ran àwọn mẹ́ḿbà tí ó kù nínú ìdílé lọ́wọ́ láti di ojú ìwòye títọ́ mú?

8 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń ní ìjákulẹ̀, wọ́n tilẹ̀ ń bínú, nígbà tí àìsàn ẹlòmíràn bá yí ìgbésí ayé wọn padà lójijì. Síbẹ̀, Kristian kan tí ó ronú lórí ipò náà, ní láti mọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé èyí fún òun ní àǹfààní láti fi ojúlówó ìfẹ́ òun hàn. Ìfẹ́ tòótọ́ ‘máa ń ní ìpamọ́ra àti inú rere . . . tí kì í sì í wá awọn ire tirẹ̀ nìkan . . . A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa farada ohun gbogbo.” (1 Korinti 13:​4-7) Nítorí náà, dípò yíyọ̀ọ̀da kí àwọn ìmọ̀lára òdì ṣàkóso wa, ó ṣe pàtàkì pé kí a ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe láti ṣàkóso wọn.​—Owe 3:21.

9. Ìmúdánilójú wo ni ó lè ṣèrànwọ́ fún ìdílé kan nípa tẹ̀mí àti nípa ti èrò ìmọ̀lára, nígbà tí mẹ́ḿbà kan bá ń ṣàìsàn gidigidi?

9 Kí ni a lè ṣe láti dáàbò bo ire tẹ̀mí àti ti èrò ìmọ̀lára ti ìdílé nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ bá ń ṣàìsàn gidigidi? Dájúdájú, àmódi kọ̀ọ̀kan ń béèrè àbójútó àti ìtọ́jú kan pàtó, kì yóò sì jẹ́ ohun tí ó tọ́ láti dábàá ọ̀nà ìtọ́jú ìṣègùn tàbí ìtọ́jú abẹ́lé èyíkéyìí nínú ìtẹ̀jáde yìí. Síbẹ̀síbẹ̀, nípa tẹ̀mí, Jehofa ‘ń gbé àwọn tí ó ṣubú ró.’ (Orin Dafidi 145:14) Ọba Dafidi kọ̀wé pé: “Ìbùkún ni fún ẹni tí ń ro ti àwọn aláìní, Oluwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú. Oluwa yóò pa á mọ́, yóò sì mú un wà láàyè; . . . Oluwa yóò gbà á ní ìyànjú lórí ẹní àrùn.” (Orin Dafidi 41:​1-3) Jehofa ń pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mọ́ láàyè nípa tẹ̀mí, àní nígbà tí a bá dán wọn wò ní ti èrò ìmọ̀lára ju bí agbára wọn ti mọ lọ pàápàá. (2 Korinti 4:7) Ọ̀pọ̀ mẹ́ḿbà ìdílé tí ń dojú kọ àìsàn líle koko nínú agbo ilé wọn ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ onipsalmu náà ní àsọtúnsọ pé: “A pọ́n mi lójú gidigidi: Oluwa, sọ mí di ààyè, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.”​—Orin Dafidi 119:107.

Ẹ̀MÍ TÍ Ń WONI SÀN

10, 11. (a) Kí ni ó ṣe pàtàkì bí ìdílé kan yóò bá kojú àìsàn kan pẹ̀lú ìkẹ́sẹjárí? (b) Báwo ni obìnrin kan ṣe kojú àìsàn ọkọ rẹ̀?

10 Òwe Bibeli kan wí pé: “Ọkàn ènìyàn yóò fàyà rán àìlera rẹ̀; ṣùgbọ́n ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì, ta ni yóò gbà á.” (Owe 18:14) Hílàhílo lè kó ìdààmú bá ìṣarasíhùwà ìdílé àti “ọkàn ènìyàn.” Síbẹ̀, “àyà tí ó yè kooro ni ìyè ara.” (Owe 14:30) Yálà ìdílé kan kẹ́sẹ járí nínú kíkojú àmódi líle koko tàbí kò kẹ́sẹ járí, sinmi lórí ìṣarasíhùwà, tàbí ẹ̀mí, tí àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ ní.​—Fi wé Owe 17:22.

11 Obìnrin Kristian kan fara da rírí ọkọ rẹ̀ tí àrùn rọpárọsẹ̀ sọ di ahẹrẹpẹ lẹ́yìn ọdún mẹ́fà péré tí wọ́n ṣègbéyàwó. Ó rántí pé: “Ó nípa lórí ohùn ọkọ mi gidigidi, ó sì ṣòro púpọ̀ láti lè bá a jíròrò. Ẹ̀fọ́rí tí gbígbìyànjú láti lóye ohun tí ó ń tiraka láti sọ máa ń fà pọ̀ jọjọ.” Ìwọ náà ronú nípa ìrora àti àròdùn ọkàn tí yóò ti dé bá ọkọ náà. Kí ni tọkọtaya náà ṣe? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń gbé ní ibi tí ó jìnnà púpọ̀ sí ìjọ Kristian, arábìnrin náà sa gbogbo ipá rẹ̀ láti dúró bí alágbára nípa tẹ̀mí, nípa kíka gbogbo ìsọfúnni tí ètò àjọ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde àti jíjẹ oúnjẹ tẹ̀mí tí ń wá déédéé láti inú ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! Èyí fún un ní okun nípa tẹ̀mí, láti lè tọ́jú ọkọ rẹ̀ àyànfẹ́ títí tí ọkọ náà fi kú ní ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà.

12. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú ọ̀ràn Jobu, ipá wo ni ẹni tí ń ṣàìsàn náà lè sà nígbà míràn?

12 Nínú ọ̀ràn Jobu, òun tí ìyà ń jẹ gan-an, ni ó dúró bí alágbára. Ó bi aya rẹ̀ pé: “Àwa óò ha gba ire lọ́wọ́ Ọlọrun, kí a má sì gba ibi!” (Jobu 2:10) Abájọ tí ọmọ ẹ̀yìn náà Jakọbu fi sọ̀rọ̀ nípa Jobu lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ títayọ ní ti sùúrù àti ìpamọ́ra! Nínú Jakọbu 5:11 a kà pé: “Ẹ ti gbọ́ nipa ìfaradà Jobu ẹ sì ti rí àbárèbábọ̀ tí Jehofa mú wá, pé Jehofa jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi ninu ìfẹ́ni ó sì jẹ́ aláàánú.” Bákan náà lónìí, nínú àwọn ọ̀ràn púpọ̀, ìṣarasíhùwà onígboyà tí mẹ́ḿbà tí ń ṣàìsàn nínú ìdílé ní, ti ran àwọn mìíràn nínú agbo ilé náà lọ́wọ́ láti di ojú ìwòye rere mú.

13. Ìfiwéra wo ni kò yẹ kí ìdílé kan tí ń nírìírí àìsàn líle koko ṣe?

13 Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí wọ́n ti kojú àìsàn nínú ìdílé gbà pé, ní ìbẹ̀rẹ̀, kò ṣàjèjì pé kí ó má rọrùn fún àwọn mẹ́ḿbà ìdílé láti lè dojú kọ ọ̀ràn náà. Wọ́n tún fi hàn pé, ọ̀nà tí ẹnì kan gbà wo ipò náà ṣe pàtàkì gidigidi. Àwọn ìyípadà àti àtúnṣebọ̀sípò nínú ìgbòkègbodò agbo ilé lè ṣòro ní ìbẹ̀rẹ̀. Ṣùgbọ́n, bí ẹnì kan bá sapá gidigidi, ó lè mú ara rẹ̀ bá ipò tuntun náà mu. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí a má fi àwọn ipò wa wé tí àwọn ẹlòmíràn tí àìsàn kò yọ lẹ́nu nínú ìdílé wọn, ní ríronú pé ìgbésí ayé wọn rọrùn ju tiwa lọ, kí a sì máa ronú pé ‘ìrẹ́jẹ ni!’ Ní tòótọ́, kò sí ẹni tí ó mọ ẹrù ìnira tí àwọn ẹlòmíràn ń rù. Gbogbo Kristian ń rí ìtùnú nínú àwọn ọ̀rọ̀ Jesu náà pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú emi yoo sì tù yín lára.”​—Matteu 11:28.

GBÍGBÉ ÀWỌN OHUN ÀKỌ́MÚṢE KALẸ̀

14. Báwo ni a ṣe lè gbé àwọn ohun àkọ́múṣe kalẹ̀?

14 Nígbà tí àìsàn líle koko bá ṣẹlẹ̀, yóò dára kí ìdílé rántí àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí náà pé: “Ìkẹ́sẹjárí máa ń wà ní ibi tí ọ̀pọ̀ olùgbaninímọ̀ràn bá wà.” (Owe 15:22, NW) Àwọn mẹ́ḿbà ìdílé ha lè jókòó pọ̀, kí wọ́n sì jíròrò ipò tí àìsàn náà ti fà? Dájúdájú, yóò dára láti ṣe bẹ́ẹ̀ tàdúràtàdúrà, kí a sì yíjú sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fún ìtọ́sọ́nà. (Orin Dafidi 25:4) Kí ni a gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò nínú irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀? Ó dára, a ní láti ṣe àwọn ìpinnu tí ó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìṣègùn, ọ̀ràn ìnáwó, àti ọ̀ràn ìdílé. Ta ni yóò bójú tó aláìsàn náà? Báwo ni ìdílé ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti ti àbójútó náà lẹ́yìn? Báwo ni àwọn ètò tí a ṣe yóò ṣe nípa lórí mẹ́ḿbà ìdílé kọ̀ọ̀kan? Báwo ni a óò ṣe bójú tó àìní tẹ̀mí àti àwọn àìní mìíràn tí abójútóni náà bá ní?

15. Ìtìlẹyìn wo ni Jehofa ń pèsè fún àwọn ìdílé tí ń nírìírí àìsàn líle koko?

15 Fífi tọkàntọkàn gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Jehofa, ṣíṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti fífi tìgboyàtìgboyà tẹ̀ lé ọ̀nà tí Bibeli tọ́ka sí sábà máa ń yọrí sí ìbùkún tí ó ré kọjá ohun tí a ń retí. Ní ìgbà míràn, àrùn tí ń ṣe mẹ́ḿbà kan nínú ìdílé lè ṣàìṣẹ́ pẹ́rẹ́. Ṣùgbọ́n nínú ipò èyíkéyìí, gbígbára lé Jehofa sábà máa ń yọrí sí àbájáde dídára jù lọ. (Orin Dafidi 55:22) Onipsalmu kọ̀wé pé: “Oluwa, àánú rẹ dì mí mú. Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbìnújẹ́ mi nínú mi, ìtùnú rẹ ni ó ń mú inú mi dùn.”​—Orin Dafidi 94:​18, 19; tún wo Orin Dafidi 63:​6-8.

RÍRAN ÀWỌN ỌMỌ LỌ́WỌ́

16, 17. Àwọn kókó wo ni a lè sọ nígbà tí a bá ń jíròrò àìsàn ọmọdé kan pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ̀?

16 Àìsàn líle koko lè fa ìṣòro fún àwọn ọmọ nínú ìdílé. Ó ṣe pàtàkì pé, kí àwọn òbí ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti lóye àwọn àìní tí ó jẹ yọ àti ohun tí wọ́n lè ṣe láti ṣèrànwọ́. Bí ẹni tí ń ṣàìsàn náà bá jẹ́ ọmọdé, a gbọ́dọ̀ ran àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ̀ lọ́wọ́ láti lóye pé, àfiyèsí àti ìtọ́jú àrà ọ̀tọ̀ tí a ń fún ẹni tí ń ṣàìsàn náà kò túmọ̀ sí pé, a kò nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ yòókù tó bẹ́ẹ̀. Dípò yíyọ̀ọ̀da fún kùnrùngbùn tàbí ìbánidíje láti dàgbà, àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ yòókù lọ́wọ́ láti mú ìdè tímọ́tímọ́ dàgbà pẹ̀lú ara wọn lẹ́nì kíní-kejì, kí wọ́n sì mú ojúlówó ìfẹ́ni dàgbà bí wọ́n ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú yíyanjú ipò tí àìsàn náà fà.

17 Àwọn ọmọdé yóò tètè hùwà padà bí àwọn òbí wọn bá fọ̀ràn lọ ìmọ̀lára wọn dípò ṣíṣàlàyé rẹpẹtẹ tàbí dídíjú nípa àwọn ipò ìṣègùn. Nítorí náà, a lè sọ díẹ̀ fún wọn nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí mẹ́ḿbà ìdílé tí ń ṣàìsàn náà. Bí àwọn ọmọ tí ara wọ́n le bá rí bí àmódi náà ṣe ń ṣèdíwọ́ fún ẹni tí ń ṣàìsàn náà láti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tí àwọn fúnra wọ́n rò pé ó rọrùn, ó ṣeé ṣe kí wọ́n túbọ̀ ní “ìfẹ́ni ará” kí wọ́n sì fi “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” hàn.​—1 Peteru 3:8.

18. Báwo ni a ṣe lè ran àwọn ọmọ tí wọ́n ti dàgbà lọ́wọ́ láti lóye àwọn ìṣòro tí àìsàn ń fà, báwo sì ni èyí ṣe lè ṣe wọ́n láǹfààní?

18 A ní láti ran àwọn ọmọ tí wọ́n ti dàgbà lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ipò tí ó nira ń bẹ, ó sì ń béèrè ìrúbọ níhà ọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé. Pẹ̀lú owó dókítà àti owó ìṣègùn tí wọ́n fẹ́ san, ó lè má ṣeé ṣe fún àwọn òbí láti pèsè fún àwọn ọmọ yòókù tó bí wọ́n ṣe fẹ́. Àwọn ọmọ yóò ha wúgbọ nítorí èyí, kí wọ́n sì rò pé a ń fi nǹkan dù wọ́n bí? Àbí wọn yóò lóye ipò náà, tí wọn yóò sì múra tán láti ṣe àwọn ìrúbọ tí ó yẹ? Ọ̀pọ̀ sinmi lórí ọ̀nà tí a gbà jíròrò ọ̀ràn náà àti ẹ̀mí tí ìdílé náà ti mú dàgbà. Ní tòótọ́, nínú ọ̀pọ̀ ìdílé, àìsàn mẹ́ḿbà kan nínú ìdílé ti ṣèrànwọ́ nínú títọ́ àwọn ọmọ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Paulu pé: “[Ẹ má ṣe] ohunkóhun lati inú ẹ̀mí asọ̀ tabi lati inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣugbọn pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú kí ẹ máa kà á sí pé awọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ, kí ẹ máṣe máa mójútó ire ara-ẹni ninu kìkì awọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣugbọn ire ara-ẹni ti awọn ẹlòmíràn pẹlu.”​—Filippi 2:​3, 4.

OJÚ TÍ Ó YẸ KÍ A FI WO ÌTỌ́JÚ ÌṢÈGÙN

19, 20. (a) Àwọn ẹrù iṣẹ́ wo ni àwọn olórí ìdílé ń gbé nígbà tí mẹ́ḿbà kan nínú ìdílé bá ń ṣàìsàn? (b) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìwé ìṣègùn, ọ̀nà wo ni Bibeli gbà pèsè ìtọ́sọ́nà nínú bíbójú tó àìsàn?

19 Àwọn Kristian tí wọ́n wà déédéé kì í kọ ìtọ́jú ìṣègùn níwọ̀n ìgbà tí kò bá ti lòdì sí òfin Ọlọrun. Nígbà tí mẹ́ḿbà kan nínú ìdílé bá ń ṣàìsàn, wọ́n ń hára gàgà láti wá ìrànlọ́wọ́ láti pèsè ìtura fún ẹni tí àìsàn kọ lù náà. Síbẹ̀, àwọn èrò ìṣègùn tí ó ta kora lè wà tí a ní láti gbé yẹ̀ wò. Ní àfikún sí i, ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn àrùn àti òkùnrùn tuntun ti ń jẹ yọ láìròtẹ́lẹ̀, èyí tí ó sì pọ̀ jù nínú àwọn wọ̀nyí ni kò ní ìtọ́jú ìṣègùn kankan tí gbogbogbòò tẹ́wọ́ gbà. Kódà, nígbà míràn, ó máa ń ṣòro láti ṣe àyẹ̀wò pípéye. Bí ọ̀ràn bá rí báyìí, kí ni ó yẹ kí Kristian kan ṣe?

20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òǹkọ̀wé Bibeli kan jẹ́ oníṣègùn, tí aposteli Paulu sì fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ Timoteu ní ìmọ̀ràn arannilọ́wọ́ lórí ìṣègùn, Ìwé Mímọ́ jẹ́ amọ̀nà ní ti ìwà híhù àti nípa tẹ̀mí, kì í ṣe ìwé ìṣègùn. (Kolosse 4:14; 1 Timoteu 5:23) Nítorí náà, nínú àwọn ọ̀ràn ìtọ́jú ìṣègùn, àwọn Kristian olórí ìdílé ní láti ṣe ìpinnu ti ara wọn tí ó wà déédéé. Bóyá wọ́n lè rò pé wọ́n ní láti gbà ju èrò oníṣègùn kan lọ. (Fi wé Owe 18:17.) Dájúdájú, wọn yóò fẹ́ ìrànwọ́ dídára jù tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún mẹ́ḿbà ìdílé tí ń ṣàìsàn, ọ̀pọ̀ jù lọ sì máa ń wá èyí lọ sọ́dọ̀ àwọn dókítà. Àwọn ìtọ́jú àìlera àfidípò ń tẹ́ àwọn kan lọ́rùn. Ìpinnu ara ẹni ni èyí jẹ́ pẹ̀lú. Síbẹ̀, nígbà tí a bá ń bójú tó àwọn ìṣòro àìlera, àwọn Kristian kò ní dẹ́kun jíjẹ́ kí ‘ọ̀rọ̀ Ọlọrun jẹ́ fìtílà sí ẹsẹ̀ wọn, àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà wọn.’ (Orin Dafidi 119:105) Wọ́n yóò máa bá a nìṣó láti tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà tí a là sílẹ̀ nínú Bibeli. (Isaiah 55:​8, 9) Nípa báyìí, wọn yóò yẹra fún àwọn ọ̀nà ìṣàyẹ̀wò tí ó ní ìbẹ́mìílò nínú, wọn yóò sì yẹra fún àwọn ìtọ́jú tí ó ré àwọn ìlànà Bibeli kọjá.​—Orin Dafidi 36:9; Ìṣe 15:​28, 29; Ìṣípayá 21:8.

21, 22. Báwo ni obìnrin ará Asia kan ṣe ronú lórí ìlànà Bibeli kan, báwo sì ni ìpinnu tí ó ṣe ṣe jẹ́ ohun yíyẹ lójú ìwòye ipò rẹ̀?

21 Gbé ọ̀ràn obìnrin ará Asia kan yẹ̀ wò. Kó pẹ́ púpọ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bibeli, gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí kíkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ó bí ọmọbìnrin jòjòló kan tí kò póṣù, tí ó wọn kìkì 1.47 kìlógíráàmù. Ọkàn obìnrin náà bà jẹ́ nígbà tí dókítà sọ fún un pé, ọmọ náà kò ní lè yára dàgbà, ọpọlọ rẹ̀ kò sì ní jí pépé, òun kò sì ní lè rìn. Ó gbà á nímọ̀ràn láti gbé ọmọ náà lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn abirùn. Ọkọ rẹ̀ ń ṣiyè méjì lórí ọ̀ràn náà. Ta ni kí ó yíjú sí?

22 Ó sọ pé: “Mo rántí ohun tí mo kọ́ nínú Bibeli pé “àwọn ọmọ ni ìní Oluwa: ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.” (Orin Dafidi 127:3) Ó pinnu láti gbé ‘ohun ìní’ yìí lọ sílé, kí ó sì tọ́jú rẹ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀, nǹkan kò rọgbọ fún un, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Kristian nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àdúgbò, ó ṣeé ṣe fún obìnrin náà láti gbìyànjú, kí ó sì pèsè ìrànlọ́wọ́ àrà ọ̀tọ̀ tí ọmọ náà nílò. Ọdún 12 lẹ́yìn náà, ọmọ náà ń lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó sì ń gbádùn kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ògowẹẹrẹ tí ó wà níbẹ̀. Ìyá náà sọ pé: “Mo dúpẹ́ pé àwọn ìlànà Bibeli sún mi láti ṣe ohun tí ó tọ́. Bibeli ràn mí lọ́wọ́ láti di ẹ̀rí ọkàn mímọ́ gaara mú níwájú Jehofa Ọlọrun, kí n má sì ṣe kábàámọ̀ tí ì bá ti nípa lórí mi jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé mi.”

23. Ìtùnú wo ni Bibeli fún àwọn tí ń ṣàìsàn àti àwọn tí ń bójú tó wọn?

23 Àìsàn kì yóò wà pẹ̀lú wa títí láé. Wòlíì Isaiah tọ́ka sí àkókò kan nígbà tí “àwọn ará ibẹ̀ kì yóò wí pé, Òtútù ń pa mí.” (Isaiah 33:24) A óò mú ìlérí yẹn ṣẹ nínú ayé tuntun tí ń yára sún mọ́lé. Ṣùgbọ́n, títí di ìgbà náà, a ní láti kojú àìsàn àti ikú. Ó dùn mọ́ni pé, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fún wa ní ìtọ́sọ́nà àti ìrànlọ́wọ́. Àwọn òfin ìhùwàsí pàtàkì tí Bibeli pèsè ń bẹ títí láé, wọ́n sì ga ju àwọn èrò ẹ̀dá ènìyàn aláìpé tí kì í dúró sójú kan lọ. Nítorí náà, ọlọgbọn ènìyàn yóò gbà pẹ̀lú onipsalmu tí ó kọ̀wé pé: “Òfin Oluwa pé, ó ń yí ọkàn padà: ẹ̀rí Oluwa dáni lójú, ó ń sọ òpè di ọlọgbọ́n. . . . Ìdájọ́ Oluwa ni òtítọ́, òdodo ni gbogbo wọn. . . . Ní pípa mọ́ wọn, èrè púpọ̀ ń bẹ.”​—Orin Dafidi 19:​7, 9, 11.

BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN . . . ÌDÍLÉ LÁTI KOJÚ ÀMÓDI LÍLE KOKO ÀTI ÀWỌN WÀHÁLÀ TÍ Ń MÚ WÁ?

Ìfẹ́ ní ìpamọ́ra, ó sì ń fara da ohun gbogbo.​—1 Korinti 13:4-7.

Ó ṣe pàtàkì láti mú ẹ̀mí rere dàgbà.​—Owe 18:14.

Ó dára láti wá ìmọ̀ràn kí a tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì.​—Owe 15:22.

Jehofa ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí ìgbésí ayé bá nira.​—Orin Dafidi 55:22.

Ọ̀rọ̀ Jehofa jẹ́ amọ̀nà nínú gbogbo ipò.​—Orin Dafidi 119:105.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 118]

Àwọn Kristian ń fi bí ìfẹ́ wọ́n ti jinlẹ̀ tó hàn nígbà tí ẹnì kejì wọn bá ń ṣàìsàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 125]

Nígbà tí ìdílé bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, wọ́n lè yanjú àwọn ìṣòro

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́