ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 9/1 ojú ìwé 4-7
  • Ṣé Èṣù Ló Ń Jẹ́ Ká Ṣàìsàn Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Èṣù Ló Ń Jẹ́ Ká Ṣàìsàn Ni?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipa Tí Sátánì Kó
  • Báwo Ni Sátánì Ṣe Ń Ṣiṣẹ́?
  • Onírúurú Ohun Tí Ń Fa Àìsàn
  • Ojútùú Tí Yóò Wà Pẹ́ Títí
  • Ohun Tó Rúni Lójú Nípa Àìlera
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Nígbà Tí Mẹ́ḿbà Kan Nínú Ìdílé Bá Ń Ṣàìsàn
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Jóòbù Jẹ́ Olóòótọ́ Sí Ọlọ́run
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Gbé Ìgbé Ayé Tó Múnú Ọlọ́run Dùn
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 9/1 ojú ìwé 4-7

Ṣé Èṣù Ló Ń Jẹ́ Ká Ṣàìsàn Ni?

KÒ YẸ KÍ ÀÌSÀN TIẸ̀ WÀ RÁRÁ. Ọlọ́run dá wa láti wà láàyè títí láé nínú ìlera pípé. Ẹ̀dá ẹ̀mí kan ni, ìyẹn Sátánì, ló fa àìsàn, ìrora, àti ikú láti pọ́n ìdílé ènìyàn lójú nígbà tó ti àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, sínú ẹ̀ṣẹ̀.—JẸ́NẸ́SÍSÌ 3:1-5, 17-19; RÓÒMÙ 5:12.

ṢÉ Ó wá túmọ̀ sí pé ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí àìrí ni gbogbo àìsàn ti ń wá ní tààràtà ni? Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ọ̀pọ̀ ló rò bẹ́ẹ̀ lónìí. Ìyá baba Owmadji rò bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ṣe lóòótọ́ ni ìgbẹ́ gbuuru tí Owmadji ń yà—ìyẹn àrùn kan tó máa ń pa àwọn ọmọdé tó wà nílẹ̀ olóoru nígbà mìíràn—wá látọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí àìrí?

Ipa Tí Sátánì Kó

Bíbélì jẹ́ kí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí yéni yékéyéké. Lákọ̀ọ́kọ́, ó fi hàn pé ẹ̀mí àwọn àgbàlagbà tó ti kú kò lè ṣe nǹkankan fún alààyè. Nígbà tí àwọn ènìyàn bá kú, “wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” Wọn kò ní ẹ̀mí kankan tí kì í kú. Wọ́n ń sùn nínú ibojì, níbi tí “kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n.” (Oníwàásù 9:5, 10) Kò sí ọ̀nà tí òkú fi lè mú kí alààyè ṣàìsàn láé!

Àmọ́ ṣá o, Bíbélì fi hàn pé àwọn ẹ̀mí búburú wà. Ẹ̀dá ẹ̀mí sáà ni ọlọ̀tẹ̀ àkọ́kọ́ ní gbogbo àgbáyé, ẹni táa wá mọ̀ sí Sátánì báyìí. Àwọn mìíràn tún dara pọ̀ mọ́ ọn, àwọn yẹn là ń pè ní àwọn ẹ̀mí èṣù. Ṣé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù lè fa àìsàn ni? Ó ti ṣẹlẹ̀ rí. Lílé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde wà lára àwọn iṣẹ́ ìyanu kan tí Jésù fi mú àwọn ènìyàn lára dá. (Lúùkù 9:37-43; 13:10-16) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ ìwòsàn tí Jésù ṣe ni kì í ṣe ti àìsàn tó wá látọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù ní tààràtà. (Mátíù 12:15; 14:14; 19:2) Bákan náà lónìí, ohun tó jóòótọ́ níbi gbogbo ni pé, ipò tí ẹ̀dá ènìyàn wà ló ń fa àìsàn, kì í ṣe agbára kan tó ju ti ẹ̀dá lọ.

Àwọn àjẹ́ wá ńkọ́? Òwe 18:10 mú un dá wa lójú pé: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.” Jákọ́bù 4:7 sọ pé: “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” Dájúdájú, Ọlọ́run lè gba àwọn tí ń fi tòótọ́tòótọ́ sìn ín lọ́wọ́ àwọn àjẹ́ àti lọ́wọ́ agbára abàmì èyíkéyìí. Ọ̀nà kan tí a lè gbà túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nìyẹn pé: “Òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—Jòhánù 8:32.

Àwọn kan lè béèrè pé: ‘Jóòbù wá ńkọ́?’ ‘Ṣe kì í ṣe ẹ̀mí búburú kan ló mú kó ṣàìsàn ni?’ Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì sọ pé Sátánì ló fa àìsàn Jóòbù. Ṣùgbọ́n ọ̀ràn ti Jóòbù yàtọ̀ pátápátá. Ó pẹ́ tí Ọlọ́run ti ń dáàbò bo Jóòbù lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀yìn ìyẹn ni Sátánì wá pe Jèhófà níjà láti kọ lu Jóòbù, nígbà tó sì ti ní àríyànjiyàn ńláǹlà nínú, Jèhófà fawọ́ ààbò rẹ̀ sẹ́yìn díẹ̀ lọ́dọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí.

Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run fi ààlà sí i. Nígbà tó gba Sátánì láyè láti pọ́n Jóòbù lójú, Sátánì lè mú kí Jóòbù ṣàìsàn fúngbà díẹ̀, ṣùgbọ́n kò lè pa á. (Jóòbù 2:5, 6) Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìrora Jóòbù dópin, Jèhófà sì san èrè ńlá fún un nítorí ó pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́. (Jóòbù 42:10-17) Àkọsílẹ̀ nípa ẹ̀kọ́ tí ìwà títọ́ Jóòbù fi hàn ti wà nínú Bíbélì láti ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, ó sì ṣe kedere sí gbogbo gbòò. A kò nílò irú àdánwò bẹ́ẹ̀ mọ́.

Báwo Ni Sátánì Ṣe Ń Ṣiṣẹ́?

Ká ṣáà sọ pè ní gbogbo ọ̀nà, ohun kan ṣoṣo tó kan Sátánì pẹ̀lú àìsàn ènìyàn ni òtítọ́ náà pé Sátánì dán tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́ wò, wọ́n sì ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀. Kì í ṣe òun àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ló ń fa àrùn èyíkéyìí ní tààràtà. Àmọ́ ṣá o, Sátánì ò kọjá ẹni tó lè tì wá ṣe àwọn ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ juwọ́ sílẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ wa, èyí tó lè pa ìlera wa lára. Kò fi àjẹ́ da Ádámù àti Éfà láàmú, kò pa wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò fi àìsàn kọ lù wọ́n. Ó yí Éfà lérò padà láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, Ádámù wá tẹ̀ lé ipa ọ̀nà àìgbọràn rẹ̀. Bí àìsàn àti ikú ṣe di ara àbájáde rẹ̀ nìyẹn.—Róòmù 5:19.

Ìgbà kan wà tí ọba Móábù bẹ aláìṣòótọ́ wòlíì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Báláámù lọ́wẹ̀ láti fi orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì bú, níwọ̀n bí dídó tí wọ́n dó sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù ti ń kó jìnnìjìnnì bá àwọn aráàlú. Báláámù gbìyànjú láti fi Ísírẹ́lì bú, ṣùgbọ́n kò rí wọn gbé ṣe, nítorí pé orílẹ̀-èdè náà wà lábẹ́ ààbò Jèhófà. Àwọn ará Móábù wá ṣètò láti fẹ̀tàn mú Ísírẹ́lì bọ̀rìṣà, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣèṣekúṣe. Ọgbọ́n tí wọ́n dá yìí wọlé, Ísírẹ́lì sì pàdánù ààbò Jèhófà.—Númérì 22:5, 6, 12, 35; 24:10; 25:1-9; Ìṣípayá 2:14.

A lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kan kọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbàanì yẹn. Ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá máa ń dáàbò bo àwọn olóòótọ́ olùjọsìn Ọlọ́run lọ́wọ́ ogun àwọn ẹ̀mí búburú. Bó ti wù kó rí, Sátánì lè mú kí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan juwọ́ sílẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ wọn. Ó lè gbìyànjú láti fọgbọ́n tàn wọ́n sínú ìṣekúṣe. Tàbí, bíi kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó lè gbìyànjú láti dáyà fò wọ́n kí wọ́n lè máa hùwà lọ́nà tí wọn kò fi ní í rí ààbò Ọlọ́run mọ́. (1 Pétérù 5:8) Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi pe Sátánì ní “ẹni tí ó ní ọ̀nà àtimú ikú wá.”—Hébérù 2:14.

Ìyá baba Owmadji gbìyànjú láti yí Hawa lérò padà kó lè so ońdè àti gbékúdè mọ́ ọmọ rẹ̀ lọ́rùn, kí àìsàn má bàa ṣe é. Kí ni ì bá ṣẹlẹ̀ ká ní Hawa lọ gbà fún un? Ìyẹn ì bá ti fi hàn pé obìnrin náà kò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run rárá, ọkàn rẹ̀ kò sì ní balẹ̀ lórí ààbò rẹ̀ mọ́.—Ẹ́kísódù 20:5; Mátíù 4:10; 1 Kọ́ríńtì 10:21.

Sátánì gbìyànjú láti yí Jóòbù náà lérò padà. Mímú kó pàdánù ìdílé rẹ̀, ọrọ̀ rẹ̀, àti ìlera rẹ̀ kò tó. Ìyàwó Jóòbù tún fún un ní ìmọ̀ràn tó burú jáì nígbà tó sọ pé: “Bú Ọlọ́run, kí o sì kú!” (Jóòbù 2:9) Ẹ̀yìn ìyẹn ni “àwọn ọ̀rẹ́” mẹ́ta bẹ̀ ẹ́ wò, àwọn tí wọ́n sa gbogbo ipá wọn láti yí i lọ́kan padà kí ó lè gbà pé òun ló jẹ̀bi àìsàn tó ń ṣe é. (Jóòbù 19:1-3) Nípa báyìí, Sátánì lo àǹfààní àìlera Jóòbù láti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a kí ó sì mi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nínú Jèhófà. Síbẹ̀, Jóòbù ń tẹ̀ síwájú láti gbára lé Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo tó ní.—Fi wé Sáàmù 55:22.

Ìdààmú ọkàn lè bá àwa náà nígbà tí àìsàn bá ń ṣe wá. Lábẹ́ irú ipò bẹ́ẹ̀, Sátánì máa ń yára gbìyànjú àtimú kí a ṣe àwọn nǹkan kan tó lè mú wa juwọ́ sílẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ wa. Nítorí náà, nígbà tí àìsàn bá ń ṣe wá, ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ nínú ọkàn wa pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àìpé tí a jogún bá ló fà á, kì í ṣe àwọn agbára àìrí kan. Rántí pé Ísákì olóòótọ́ kò ríran mọ́ ní ọdún bíi mélòó kan ṣáájú ikú rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 27:1) Kì í ṣe àwọn ẹ̀mí búburú ló fà á bí kò ṣe ọjọ́ ogbó. Kì í ṣe Sátánì ló pa Rákélì nígbà tó ń bímọ lọ́wọ́, bí kò ṣe jíjẹ́ tí ènìyàn jẹ́ aláìlera. (Jẹ́nẹ́sísì 35:17-19) Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, gbogbo àwọn olóòótọ́ ìgbàanì kú tán pátá—kì í ṣe nítorí pé àwọn kan fi èèdì dì wọ́n tàbí wọ́n ta wọ́n láṣẹ bí kò ṣe nítorí àìpé tí wọ́n jogún.

Fífinú wòye pé gbogbo àìsàn tó bá ń ṣe wá ló wá látọ̀dọ̀ ẹ̀mí àìrí jẹ́ ìdẹkùn kan. Ó lè múni máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí àwọn ẹ̀mí wọ̀nyẹn. Lẹ́yìn náà, tí àìsàn bá wá ń ṣe wá, a lè máa gbìyànjú àtitu àwọn ẹ̀mí èṣù lójú dípò kí á jìnnà sí wọn. Bí Sátánì bá ti lè sún wa sínú bíbá ẹ̀mí lò, a jẹ́ pé a ti da Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́ náà, nìyẹn. (2 Kọ́ríńtì 6:15) Ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run ló yẹ kó máa tọ́ wa sọ́nà, kì í ṣe ìbẹ̀rù ìgbàgbọ́ nínú ohun asán nípa Elénìní rẹ̀.—Ìṣípayá 14:7.

Ṣáájú àkókò yìí ni Owmadji ti ní ààbò tó dára jù lọ. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, Ọlọ́run kà á sí ẹni “mímọ́” nítorí pé ó ní ìyá tó jẹ́ onígbàgbọ́, ìyá rẹ̀ sì lè gbàdúrà pé kí Ọlọ́run wà pẹ̀lú ọmọ òun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 7:14) Níwọ̀n bí Hawa ti jẹ́ ẹni tí a fi irú ìmọ̀ pípéye bẹ́ẹ̀ jíǹkí, ó ṣeé ṣe fún un láti wá ìtọ́jú tó gbéṣẹ́ fún Owmadji dípò kó gbẹ́kẹ̀ lé síso ońdè mọ́ ọn lọ́rùn.

Onírúurú Ohun Tí Ń Fa Àìsàn

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn ni kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹ̀mí àìrí. Bí wọ́n bá ń ṣàìsàn, ọ̀dọ̀ dókítà ni wọ́n máa ń lọ—bí wọ́n bá lè rówó ẹ̀ san. Ní ti tòótọ́, ẹnì kan tó ń ṣàìsàn lè lọ sọ́dọ̀ dókítà síbẹ̀ kó máà gbádùn. Àwọn dókítà kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu. Àmọ́, ọ̀pọ̀ tó ní ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ló jẹ́ pé ìgbà tí ẹ̀pa kò bá bóró mọ́ ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń lọ sọ́dọ̀ dókítà. Wọ́n lè kọ́kọ́ máa yalé adáhunṣe kiri, ìgbà tí ìyẹn bá kùnà ni wọ́n á ṣẹ̀ṣẹ̀ wá lọ sọ́dọ̀ dókítà. Ọ̀pọ̀ ti kú ikú tí kò yẹ kí wọ́n kú.

Àìmọ̀kan ló tún ń fa ikú àìtọ́jọ́ fún àwọn mìíràn. Wọn ò mọ àmì tó fi hàn pé àrùn báyìí ló fẹ́ ṣe wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe láti dènà àìsàn. Ìmọ̀ ń ṣèrànwọ́ láti dènà ìyà tó ṣeé yẹra fún. Abájọ tó fi jẹ́ pé ọmọ àwọn púrúǹtù tí àìsàn ń pa máa ń pọ̀ ju ọmọ àwọn ọ̀mọ̀wé tí àìsàn ń pa. Dájúdájú, àìmọ̀kan lè ṣekú pani.

Àìka-ǹkan-sí tún jẹ́ ohun mìíràn tó ń fa àìsàn. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ló ń ṣàìsàn nítorí pé wọ́n jẹ́ kí àwọn kòkòrò rìn lórí oúnjẹ wọn kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ ẹ́, tàbí kò jẹ́ pé àwọn tó ń gbọ́ oúnjẹ náà kò fọwọ́ wọn kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀. Sísùn láìlo àpò ẹ̀fọn ní àwọn àgbègbè tí àìsàn ibà ti ń ranni tún léwu.a Nígbà tó bá kan ọ̀ràn nípa ìlera, ó sábà má ń jẹ́ òótọ́ pe “ohun díẹ̀ tó náni láti dènà àìsàn níye lórí ju owó gọbọi tí a fi ń wo àìsàn lọ.”

Gbígbé ìgbésí ayé òmùgọ̀ ti fa àìsàn fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́, ó sì ti yọrí sí kíkú ní rèwerèwe fún wọn. Mímu ọtí àmupara, ṣíṣèṣekúṣe, jíjoògùnyó, àti tábà mímu ti ba ìlera ọ̀pọ̀ ènìyàn jẹ́. Bí ẹni kan bá kópa nínú àwọn ìwà abèṣe wọ̀nyí, tí àìsàn wá dé, ṣe nítorí pé ẹni kan fèèdì dì í ni àbí ẹ̀mí kan gbógun tì í? Ó tì o. Òun ló jẹ̀bi àìsàn tó ń ṣe é. Dídẹ́bi fún àwọn ẹ̀mí àìrí yóò túmọ̀ sí kíkọ̀ láti tẹ́wọ́ gba ẹ̀bi fún gbígbé ìgbésí ayé òpònú.

Láìsí àní-àní, àwọn nǹkan kan wà tí a kò lè kápá. Fún àpẹẹrẹ, a lè ní àìsàn tí àwọn kòkòrò àrùn tàbí àyíká bíbàjẹ́ ń fà. Èyí ló ṣẹlẹ̀ sí Owmadji. Ìyá rẹ̀ kò mọ ohun tó fa ìgbẹ́ gbuuru náà. Àwọn ọmọ tirẹ̀ kì í sábà ṣàìsàn bíi ti àwọn ọmọ mìíràn nítorí pé ó máa ń mú ilé rẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní, tí àyíká rẹ̀ yóò sì wà nigínnigín, ó sì máa ń fọwọ́ rẹ̀ kó tó gbọ́únjẹ. Ṣùgbọ́n gbogbo ọmọdé ló máa ń ṣàìsàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Nǹkan bí oríṣi mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n kòkòrò àkóràn ló lè fa ìgbẹ́ gbuuru. Ó ṣeé ṣe kí ẹnikẹ́ni má mọ èyí tó fa ìṣòro tí Owmadji ní.

Ojútùú Tí Yóò Wà Pẹ́ Títí

Àìsàn kì í ṣe ẹ̀bi Ọlọ́run. “A kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13) Bí ọ̀kan nínú àwọn olùjọ́sìn Jèhófà bá ń ṣàìsàn, yóò fún un lókun nípa tẹ̀mí. “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò gbé e ró lórí àga ìnàyìn ti àmódi; gbogbo ibùsùn rẹ̀ ni ìwọ yóò yí padà dájúdájú nígbà àìsàn rẹ̀.” (Sáàmù 41:3) Dájúdájú, Ọlọ́run ní ìyọ́nú. Ó fẹ́ ràn wá lọ́wọ́, kò fẹ́ pa wá lára.

Ní tòótọ́, Jèhófà ní ojútùú tó wà pẹ́ títí fún mímú àìsàn kúrò—ìyẹn ni ikú àti àjíǹde Jésù. Nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù, àwọn ọlọ́kàn títọ́ ti di ẹni tí a rà padà kúrò nínú ipò ẹ̀ṣẹ̀ wọn, níkẹyìn wọn yóò sì ní ìlera pípé àti ìyè ayérayé nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 5:5; Jòhánù 3:16) Iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ìfihàn ìwòsàn tí Ìjọba Ọlọ́run yóò mú wá. Ọlọ́run yóò tún mú Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò. (Róòmù 16:20) Lóòótọ́, Jèhófà ní àwọn ohun àgbàyanu ní ìpamọ́ fún àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ká ṣáà máa ní sùúrù àti ìfaradà.

Ní báyìí ná, Ọlọ́run ń pín ọgbọ́n tó ṣeé mú lò àti ìtọ́sọ́nà nípa tẹ̀mí nípasẹ̀ Bíbélì àti ẹgbẹ́ ará àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ tòótọ́ jákèjádò ayé. Ó ń jẹ́ ká mọ ọ̀nà tí a lè gbà yẹra fún àwọn ìwà abèṣe tí ń fa ìṣòro fún ìlera wa. Ó sì tún fún wa ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tó lè ṣèrànwọ́ nígbà tí ìṣòro bá dìde.

Ronú nípa Jóòbù lẹ́ẹ̀kan sí i. Ì bá mà ti burú jáì o, ká ní Jóòbù gba ilé babaláwo lọ! Ì bá ti mú kó pàdánù ààbò Ọlọ́run, ì bá sì ti pàdánù àwọn ìbùkún tó dúró dè é lẹ́yìn ìdánwò líle koko tó ní. Ọlọ́run kò gbàgbé Jóòbù, bẹ́ẹ̀ ni kò ní gbàgbé àwa náà. Ọmọlẹ́yìn náà Jákọ́bù sọ pé: “Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ìyọrísí tí Jèhófà mú wá.” (Jákọ́bù 5:11) Bí a kò bá juwọ́ sílẹ̀, àwa náà yóò gba ìbùkún àgbàyanu nígbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run.

Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí Owmadji? Màmá rẹ̀ rántí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn tó ń jáde pẹ̀lú Ilé Ìṣọ́, ìyẹn ni Jí!, nípa lílo àpòpọ̀ ohun mímu fún ìdápadà omi ara.b Ó tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà níbẹ̀, ó sì fún Owmadji ní àpòpọ̀ ohun mímu náà mu. Ara ọmọdébìnrin náà ti wá yá gágá báyìí, ó ti ń ṣeré.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ènìyàn tó ní ibà lára fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì bílíọ̀nù. Nǹkan bí mílíọ̀nù méjì ni àìsàn náà ń pa lọ́dún, èyí tó pọ̀ jù lọ níbẹ̀ ló ń ṣẹlẹ̀ ní Áfíríkà.

b Wo “Ohun-mimu Oníyọ̀ Tí N gba Ẹmi Là!” nínú Jí! ti August 22, 1986, ojú ìwé 23 sí 25.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Jèhófà ti ṣètò ojútùú tó wà pẹ́ títí fún mímú ìṣòro àìsàn kúrò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́