Ohun Tó Rúni Lójú Nípa Àìlera
OWMADJI KÉKERÉ JÒJÒLÓ Ń YÀGBẸ́ GBUURU. Èyí wá kó jìnnìjìnnì bá Hawa tó jẹ́ ìyá rẹ̀, ó ń bẹ̀rù pé kí omi má lọ tán lára rẹ̀; nítorí ó gbọ́ pé bí ọmọ ṣe kú mọ́ ìbátan òun kan tó wà lábúlé lọ́wọ́ láìpẹ́ yìí nìyẹn. Ìyá baba Owmadji, ìyẹn ìyá ọkọ Hawa, fẹ́ gbé Owmadji lọ sọ́dọ̀ babaláwo. Ó sọ pé: “Ẹ̀mí èṣù kan ló ń yọ ọmọ yìí lẹ́nu. O sì kọ̀ oò so ońdè mọ́ ọn lọ́rùn, láti dáàbò bò ó, ojú ẹ ti wá já a báyìí, ìṣòro náà ló délẹ̀ yìí!”
ÌṢẸ̀LẸ̀ yìí jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ ní àwọn apá ibi púpọ̀ lágbàáyé. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn ló gbà pé àwọn ẹ̀mí èṣù ló ń dá àìsàn sáwọn èèyàn lára. Ṣé òótọ́ ni?
Bí Ohun Tó Rúni Lójú Náà Ṣe Bẹ̀rẹ̀
Ìwọ alára lè má gbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀mí àìrí ló ń fa àrùn. Ó tilẹ̀ lè yà ọ́ lẹ́nu pé a rí ẹni tó ń ronú bẹ́ẹ̀, nítorí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn kòkòrò tín-ín-tìn-ìn-tín tí wọ́n ń pè ní fáírọ́ọ̀sì àti bakitéríà ló ń fa àrùn tó pọ̀ jù lọ. Àmọ́ ṣá o, rántí pé ó pẹ́ káwọn èèyàn tó mọ̀ nípa àwọn kòkòrò àrùn tín-ín-tìn-ìn-tín wọ̀nyí. Ṣe bí ìgbà tí Antonie van Leeuwenhoek ṣe awò-asọhun-kékeré-di-ńlá ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún ni àwọn ohun tín-ín-tìn-ìn-tín wọ̀nyẹn tó di ohun tí àwọn ènìyàn ń rí. Pẹ̀lú ìyẹn náà, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn àwárí tí Louis Pasteur ṣe ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún ló mú kí sáyẹ́ǹsì bẹ̀rẹ̀ sí í lóye ìbátan tó wà láàárín àwọn kòkòrò tín-ín-tìn-ìn-tín àti àrùn.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ọdún tí èèyàn ti lò lórí ilẹ̀ ayé ni kò fi sẹ́ni tó mọ ohun tó ń fa àìsàn, ọ̀pọ̀ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ló ti dìde, títí kan èrò náà pé àwọn ẹ̀mí búburú ló ń fa gbogbo àrùn ara. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ ohun kan tó ní láti mú kí èyí rí bẹ́ẹ̀. Ó ní, àwọn oníṣègùn ìjímìjí máa ń gbìyànjú láti fi onírúurú gbòǹgbò igi, àwọn ewé, àti ohunkóhun mìíràn tó bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó wọn tọ́jú aláìsàn. Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì máa ń ṣiṣẹ́ nígbà mìíràn. Lẹ́yìn èyí ni oníṣègùn náà yóò wá fi àwọn ètùtù tó jẹ́ ti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán kún ìtọ́jú náà láti da ojúlówó ohun tó fi ṣe ìwòsàn náà rú mọ́ àwọn ènìyàn lójú. Nípa bẹ́ẹ̀, ọkàn oníṣègùn náà yóò balẹ̀ pé àwọn ènìyàn yóò máa wá bá òun fún ìtọ́jú ṣáá ni. Nípa báyìí, ìṣègùn wá di ohun táa fi rúni lójú, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sọ àwọn ènìyàn di ẹni tí ń yíjú sí agbára tó ju ti ẹ̀dá lọ fún ìrànlọ́wọ́.
Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ṣì ń lo ọ̀nà ìtọ́jú àbáláyé wọ̀nyí títí di oní olónìí. Ọ̀pọ̀ ló sọ pé ẹ̀mí àwọn àgbàlagbà tó ti kú ló ń fa àìsàn. Àwọn mìíràn sọ pé Ọlọ́run ló ń jẹ́ ká ṣàìsàn àti pé àìsàn jẹ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wa. Kódà nígbà tí àwọn ènìyàn tó kàwé pàápàá bá mọ̀ nípa bí àìsàn ṣe jẹ́ tán, wọ́n sì tún lè máa bẹ̀rù àwọn agbára tó kọjá ti ẹ̀dá.
Àwọn adáhunṣe àti àwọn oníṣègùn àbáláyé máa ń lo ìbẹ̀rù yìí láti kó àwọn ènìyàn nífà. Kí ni ká wá gbà gbọ́? Ǹjẹ́ ó yẹ ká máa yíjú sí àwọn ẹ̀mí fún àbójútó ìlera? Kí ni Bíbélì sọ?