ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 6/1 ojú ìwé 5-8
  • Bi Ìgbàgbọ́ Ṣe Lè Ran Alaisan Lọwọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bi Ìgbàgbọ́ Ṣe Lè Ran Alaisan Lọwọ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbàgbọ́ Ha Lè Ṣeranwọ Nigba ti A Bá Dùbúlẹ̀ Aisan Bí?
  • Ki ni Nipa Imularada Nipa Ìgbàgbọ́?
  • Akoko Imularada Gidi
  • Ìwòsàn Ìyanu Aráyé Ti Sún Mọ́lé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ọlọrun Ha Fọwọsi Imularada Nipa Ìgbàgbọ́ Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Lagbára Ìwòsàn Tí Wọ́n Ń Pè Ní Iṣẹ́ Ìyanu Lónìí Ti Wá?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Fi Iṣẹ́ Ìyanu Ṣèwòsàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 6/1 ojú ìwé 5-8

Bi Ìgbàgbọ́ Ṣe Lè Ran Alaisan Lọwọ

AWỌN akọsilẹ iwosan oniṣẹ iyanu ninu    Bibeli tún mú un dá wa loju pe  Ọlọ   run bikita nipa wíwàlálàáfíà wa, wọn si fi agbara rẹ̀ lati ṣe iwosan han. Niwọn bi awọn iwosan onisẹ iyanu wọnyi ti fi ogo fun Ọlọrun ti o si mu ọpọ idunnu wá, o lọgbọn ninu lati beere pe, Njẹ ẹbun lati munilarada nipasẹ ẹmi mimọ ha ń ṣiṣẹ sibẹsibẹ bi?

Idahun si ibeere yẹn ni bẹẹkọ—idi ti o fi jẹ bẹẹ si lè ya awọn diẹ lẹnu. Awọn iwosan oniṣẹ iyanu wọnni ni ọrundun kìn-ín-ní ti mu ète wọn ṣẹ. Iwe naa The Illustrated Bible Dictionary lọna ti o jánà sọ pe: “Ète awọn imularada oniṣẹ iyanu jẹ́ ti isin, kì í ṣe ti iṣegun.” Ki ni diẹ ninu awọn ète onisin tí awọn iṣẹ iyanu wọnni ṣiṣẹ fun?

Fun ohun kan, awọn imularada oniṣẹ iyanu ti Jesu ṣe ṣiṣẹ fun ète ti dida a mọ̀ gẹgẹ bii Messia naa. Ati lẹhin iku rẹ̀, wọn ṣeranwọ lati fidi rẹ̀ mulẹ pe ibukun Ọlọrun wà lori ijọ Kristian titun naa. (Matteu 11:2-6; Heberu 2:3, 4) Siwaju sii, wọn ṣaṣefihan pe ileri Ọlọrun lati mu araye larada ninu aye titun naa ni a o muṣẹ. Wọn fidi ìgbàgbọ́ wa mulẹ pe akoko naa niti gidi yoo de nigba ti “awọn ara ibẹ̀ ki yoo wi pe, òótù n pa mi: a o dárí aiṣedeedee awọn eniyan ti ń gbe ibẹ̀ jì wọn.” (Isaiah 33:24) Gbàrà ti a ti mu awọn ète ọrundun kìn-ín-ní wọnyi ṣẹ, awọn iṣẹ iyanu ni a kò tún nilo mọ́.

O yẹ fun afiyesi pe awọn ọmọ-ẹhin Jesu ti ọrundun kìn-ín-ní funraawọn jiya ailera-ara ti a ko wòsàn lọna iṣẹ iyanu. Eyi jẹ́ ẹ̀rí siwaju sii pe igbokegbodo imularada oniṣẹ iyanu ti Jesu ati ti awọn aposteli bakan naa ni a ṣeto rẹ̀ lati kọni ní awọn otitọ pataki, kì í ṣe lati pese iṣẹ-isin iṣegun kan. Nigba ti o ń damọran itọju iṣegun fun iṣe lemọ́lemọ́ ọ̀ràn aisan ti Timoteu, Paulu gbẹnusọ fun ìlò waini fun itọju iṣegun, kì í ṣe imularada nipa ìgbágbọ̀. Paulu, ẹni ti o ṣe imularada oniṣẹ iyanu, ko ri itura kuro ninu ‘ẹgun kan ninu ara’ ti ń baa lọ ní ‘pipọn ọn loju.’—2 Kọrinti 12:7; 1 Timoteu 5:23.

Nigba ti awọn aposteli kú, ẹbun imularada kọja lọ. Paulu funraarẹ fihan pe eyi yoo ṣẹlẹ. Ni fifi ijọ Kristian we ọmọkekere jojolo kan, Paulu wi pe: “Nigba ti mo wà ni èwe, emi a maa sọrọ bi èwe, emi a maa moye bi èwe, emi a maa gbèrò bi èwe: ṣugbọn nigba ti mo di ọkunrin tan, mo fi iwa èwe silẹ.” Kókó inu àkàwé rẹ̀ ni pe awọn ẹbun oniṣẹ iyanu ti ẹmi jẹ apakan igba ọmọkekre jojolo ti ijọ Kristian. Wọn jẹ́ “iwa èwe.” Nitori idi eyi, oun sọ pe: “Wọn [awọn ẹbun oniṣẹ iyanu] yoo dopin.”—1 Kọrinti 13:8-11.

Ìgbàgbọ́ Ha Lè Ṣeranwọ Nigba ti A Bá Dùbúlẹ̀ Aisan Bí?

Bi o ti wu ki o ri, ani bi a ko tilẹ gbarale imularada nipa ìgbàgbọ́ paapaa, dajudaju o ṣe wẹ́kú lati gbadura si Ọlọrun fun iranwọ nigba ti a ba dùbùlẹ̀ aisan. O sì daju pe kò sí ohun ti o buru pẹlu adura awọn ẹlomiran nititori wa. Ṣugbọn awọn adura nilati jẹ olotiitọ gidi ati ni ibamu pẹlu ifẹ-inu Ọlọrun. (1 Johannu 5:14, 15) Ko si ibikibi ti Bibeli ti paṣẹ fun wa lati gbadura fun imularada nipa ìgbàgbọ́.a Kaka bẹẹ, awa ń gbadura fun itilẹhin onifẹẹ Jehofa nigba idanwo ti aisan bá múwá.

Bibeli fi ohun ti awọn oluṣotitọ lè gbadura fun ninu aisan hàn nigba ti o wi pe: “Oluwa yoo gbà á ni iyanju lori ẹní àrùn: iwọ yoo tẹ́ ẹní rẹ̀ ni gbogbo ìgbà ìdùbúlẹ̀ àrùn rẹ̀.” (Orin Dafidi 41:3) Rironu jinlẹ lori Ọrọ Ọlọrun yoo ran awọn wọnni ti ń jiya aisan ero-imọlara lọwọ. Olorin naa kọwe pe: “Ẹsẹ mi yọ́; Oluwa, aanu rẹ di mi mú. Ninu ọpọlọpọ ibanujẹ ti mo ni ninu mi, itunu rẹ ni o ń mú inu mi dun.”—Orin Dafidi 94:18, 19; tun wo 63:6-8.

Ni afikun, o yẹ ki a fi ọgbọn daradara han ninu awọn ọran ilera, Bibeli si gbà wá nimọran nipa eyi. O sàn pupọ lati gbe ni ibamu pẹlu awọn ọpa idiwọn Bibeli ju lati lọwọ ninu ilokulo oogun, mimu sìgá, amuju ọti, tabi àjẹkì ati lẹhin naa nigba ti aisan ba dé, ki a wa fi igbekuta yiju si imularada nipa ìgbàgbọ́. Gbigbadura fun iṣẹ iyanu kan nigba ti aisan ba kọluni kì í ṣe afidipo fun iwa ti o bọgbọnmu lati yèbọ́ kuro ninu aisan ti o ṣee yẹra fun, iru bii jíjẹ awọn ounjẹ eleroja afaralokun bi o ba wà larọọwọto tabi wiwa aranṣe iṣegun ti o tootun nibi ti o ba ti ṣeeṣe.

Ọrọ Ọlọrun pẹlu fun wa niṣiiri lati mú iṣarasihuwa ero-ori onilera dagba ti o lè ṣanfaani fun ilera ara wa. Iwe Owe gbaninimọran pe: “Àyà ti o yè korokoro ni iye ara; ṣugbọn ilara ni ibajẹ egungun.” “Inu-didun mu imularada rere wá: ṣugbọn ibinujẹ ọkàn mú egungun gbẹ.” (Owe 14:30; 17:22) Gbigbadura fun ẹmi mimọ lati mu iparọrọ ati idunnu dagba ninu wa lè ni kìkì awọn iyọrisi ti o ṣanfaani lori ilera ara iyara wa.—Filippi 4:6, 7.

Ki ni Nipa Imularada Nipa Ìgbàgbọ́?

Dajudaju, ani bi ẹnikan ba ń gbé igbesi-aye onilera bi ipo ọran rẹ̀ ti yọọda tó, sibẹ aisan le kọlu ú. Ki ni nigba naa? Ipalara eyikeyii ha wà ninu lilọ sọdọ olumunilarada nipa ìgbàgbọ́ ní ireti didi ẹni ti a mularada bi? Bẹẹni, ipalara wà. O ṣọwọn ki awọn olumunilarada nipa ìgbàgbọ́ ode-oni tó ṣewòsán lọfẹẹ laigbowo. Ninawo fun olumunilarada nipa ìgbàgbọ́ nigba ti a le lo owo yẹn fun iranlọwọ iṣegun si lè yọrisi ijiya ati ipadanu gidigidi fun wa. Yatọ si eyi, eeṣe ti a fi nilati fun ẹnikan ti ń kó awọn eniyan nífà nitori ìyára gbàgbọ́ laiwadii wọn lówó?

Awọn diẹ lè jiyan pe: ‘Dajudaju, imularada nipa ìgbàgbọ́ gbọdọ ní iniyelori diẹ ani bi ipin kekere kan ninu awọn wọnni ti wọn lọ sọdọ “awọn olumunilarada” ba ti di ẹni ti a mularada paapaa.’ Ṣugbọn o ṣee jiyan le lori boya awọn olumunilarada nipa ìgbàgbọ́ niti gidi ń mú ẹnikẹni larada lọna kan ti o wà titi lọ. Iwe gbedegbẹyọ naa Encyclopædia Britannica gbà pe: “Iwọnba iwadii ti a dari ni ibamu pẹlu awọn ilana ti a fi lélẹ̀ pato ni a ti ṣaṣeyọri rẹ̀ lori ọpọ awọn koko abajọ ti a kò mọ̀ ninu imularada nipa ìgbàgbọ́.”

Ani bi o ba tilẹ dabi ẹni pe a wo iye kekere kan sàn, eyi kì í ṣe ẹ̀rí ẹmi mimọ lẹnu iṣẹ. Ninu Iwaasu lori Oke, Jesu wi pe: “Ọpọlọpọ eniyan ni yoo wi fun mi ni ọjọ naa pe, Oluwa, Oluwa, awa ko ha sọtẹlẹ ni orukọ rẹ? ati orukọ rẹ ki a fi lé awọn ẹmi eṣu jade? ati ni orukọ rẹ ki a fi ṣe ọpọ iṣẹ iyanu nla? Nigba naa ni emi yoo si jẹwọ wi fun wọn pe, Emi kò mọ̀ yin ri, ẹ kuro lọdọ mi, ẹyin oniṣẹ ẹṣẹ.” (Matteu 7:22, 23) Jesu pẹlu sọ pe awọn ẹni pato kan, bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun kò tẹwọgba wọn, yoo fa afiyesi si araawọn nipasẹ awọn ami: “Nitori awọn eke Kristi, ati eke wolii yoo dide, wọn o si fi ami ati ohun iyanu nla hàn; tobẹẹ bi o lè ṣeeṣe wọn yoo tan awọn ayanfẹ paapaa.” (Matteu 24:24) Dajudaju, awọn olumunilarada nipa ìgbàgbọ́ ode-oni ni a lè fikun awọn wọnni ti ọrọ naa ń bawi, pẹlu awọn igbekalẹ amárasẹ́gìíìrì wọn, ibeere igba gbogbo fun owó, ati awọn imularada oniṣẹ iyanu ti wọn jẹwọ pe awọn ń ṣe.

Iru awọn ẹni bẹẹ ko tẹ̀lé ipasẹ Jesu. Nigba naa, ta ni wọn ń tẹ̀lé? Aposteli Paulu fun wa ní itọkasi kan nigba ti o wi pe: “Kì í sii ṣe ohun iyanu; nitori Satani tikaraarẹ ń pa araarẹ̀ dà di angẹli imọlẹ. Nitori naa kì í ṣe ohun nla bi awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu bá pa araawọn dà bi awọn iranṣẹ ododo; igbẹhin awọn ẹni ti yoo ri gẹgẹ bi iṣẹ wọn.” (2 Kọrinti 11:14, 15) Bi awọn olumunilarada nipa ìgbàgbọ́ kò ba ṣe awọn imularada ti wọn jẹwọ rẹ̀, nigba naa wọn jẹ atannijẹ, ni titẹle ipa ọna Satani, “ti ń tan gbogbo aye jẹ.” (Ifihan 12:9) Ṣugbọn ki ni, ninu awọn ọ̀ràn ti o kere, bi wọn ba ṣe iṣẹ imularada? Awa kò ha ni pari ero si pe “ọpọ iṣẹ iyanu nla” wọn ni wọn ṣe pẹlu agbara Satani ati ti awọn ẹmi eṣu rẹ̀ bi? Bẹẹni, iyẹn ni lati jẹ́ bi ọ̀ràn naa ti ri!

Akoko Imularada Gidi

Awọn iwosan oniṣẹ iyanu Jesu ni a ṣe pẹlu iranlọwọ ẹmi mimọ Ọlọrun. Wọn ṣaṣefihan ète rẹ̀ lati yanju gbogbo iṣoro ilera eniyan ni akoko títọ́. Jehofa ṣeleri “mimu awọn orilẹ-ede larada.” (Ifihan 22:2) Kì í ṣe pe oun yoo wo awọn aisan sàn nikan ṣugbọn yoo mu iku kuro. Johannu ṣalaye pe Jesu wá “ki ẹnikẹni ti o ba gbà á gbọ́ má baà ṣegbe, ṣugbọn ki o le ní iye ainipẹkun.” (Johannu 3:16) Ẹ wo imularada rere ti iyẹn yoo jẹ́! Jesu lẹẹkan sii yoo ṣe iwosan gẹgẹ bi awọn wọnni ti a kọsilẹ ninu Bibeli ṣugbọn lori ìwọ̀n ti o tobi lọpọlọpọ ju iyẹn lọ. Oun yoo tilẹ jí oku dide! (Johannu 5:28, 29) Nigba wo ni eyi yoo ṣẹlẹ?

Ninu aye titun ti Ọlọrun, eyi ti o ti sunmọle pẹkipẹki, ni ibamu pẹlu gbogbo ẹ̀rí. Aye titun yẹn, ti a o mu wọle wá lẹhin ti a ba ti mu iwa buruku eto igbekalẹ isinsinyi kuro titilae, ni yoo jẹ ibukun gidi fun araye ọlọkan titọ. Yoo jẹ́ aye kan laisi ijiya. “Ọlọrun yoo si nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn; ki yoo si si iku mọ́, tabi ọ̀fọ̀, tabi ẹkun, bẹẹni ki yoo si irora mọ́: nitori pe ohun atijọ ti kọja lọ.” (Ifihan 21:4) Ẹ wo bi o ti yatọ patapata tó si ohun ti a ń rí ni ayika wa lonii!

Nitori naa, ninu awọn ọran ti aisan, gbadura si Ọlọrun fun itilẹhin. Yala aisan ń ṣe ọ tabi araarẹ jípépé, kẹkọọ bi ìyè ayeraye laisi aisan yoo ti ṣeeṣe niti tootọ. Mu ìgbàgbọ́ rẹ lagbara ninu awọn ilera ti o ṣee gbarale ti Ọlọrun yii nipa kikẹkọọ ọpọ awọn itọka ti a ṣe si i ninu Bibeli. Kẹkọọ bi ète Ọlọrun ninu ọ̀ràn yii ti ń sunmọ imuṣẹ ní ibamu pẹlu itolẹsẹẹsẹ idiwọn akoko tirẹ. Maṣe ṣiyemeji, nitori Ọrọ Ọlọrun fi dá wa loju pe: “Oun yoo gbé iku mì laelae; Oluwa Jehofa yoo nu omije nù kuro ní oju gbogbo eniyan.”—Isaiah 25:8.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Awọn kan ronu pe awọn ọrọ ti o wa ní Jakobu 5:14, 15 nii ṣe pẹlu imularada nipa ìgbàgbọ́. Ṣugbọn ayika ọrọ naa fihan pe Jakobu nihin-in ń sọrọ nipa aisan tẹmi. (Jakọbu 5:15b, 16, 19, 20) Oun gba ẹnikọọkan ti ó ti di aláàárẹ̀ nipa ìgbàgbọ́ niyanju lati kesi awọn alagba fun iranlọwọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Awọn imularada oniṣẹ iyanu Jesu mú ète wọn ṣẹ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ọlọrun yoo tún awọn imularada oniṣẹ iyanu ṣe yoo si tún sọ wọn di pupọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́