ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 6/1 ojú ìwé 3-4
  • Ọlọrun Ha Fọwọsi Imularada Nipa Ìgbàgbọ́ Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọrun Ha Fọwọsi Imularada Nipa Ìgbàgbọ́ Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Igbagbọ—Ohun Kan Ti A Beere Fun?
  • Awọn Imularada Ode-oni O Ha Dabi Awọn Wọnni Ti Jesu Ṣe Bi?
  • Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Lagbára Ìwòsàn Tí Wọ́n Ń Pè Ní Iṣẹ́ Ìyanu Lónìí Ti Wá?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìwòsàn Ìyanu Aráyé Ti Sún Mọ́lé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Bi Ìgbàgbọ́ Ṣe Lè Ran Alaisan Lọwọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Fi Iṣẹ́ Ìyanu Ṣèwòsàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 6/1 ojú ìwé 3-4

Ọlọrun Ha Fọwọsi Imularada Nipa Ìgbàgbọ́ Bi?

“AWA ti ri awọn ohun ṣiṣajeji lonii!”    Bẹẹni, awọn oluworan ni a wulori.    Ọkunrin kan ti o rọ tapá-tasẹ̀ lọna lilekenka ni a ti mularada níṣojúu wọn kòrókòró. Olumunilarada naa sọ fun ọkunrun naa pe: “Dide si gbe àkéte rẹ, ki o si maa lọ si ile rẹ.” Ọkunrin naa si ṣe bẹẹ gẹlẹ! Oun kò rọ tápa-tẹsẹ̀ mọ́. Abajọ ti awọn wọnni ti o wà nibẹ “fi ń yin Ọlọrun logo”! (Luku 5:18-26) Iwosan yii, ti Jesu Kristi ṣe ni eyi ti o fẹrẹẹ tó 2,000 ọdun sẹhin, lọna ti o han kedere ní ifọwọsi Ọlọrun.

Ki ni nipa toni? Imularada oniṣẹ iyanu ha ṣì jẹ́ iṣeeṣe ti o ṣanfaani kan fun awọn wọnni ti wọn ko lè ri iwosan iṣegun bi? Jesu ṣe imularada oniṣẹ iyanu. Awọn olumularada nipa ìgbàgbọ́ lonii jẹwọsọ pe awọn ń ṣafarawe rẹ̀. Oju wo ni awa nilati fi wo ijẹwọsọ wọn?

Imularada nipa ìgbàgbọ́ ni a tumọ si “ọna igbaṣe kan lati tọju awọn aisan nipasẹ adura ati lilo ìgbàgbọ́ ninu Ọlọrun.” Iwe gbedegbẹyọ naa Encyclopædia Britannica tẹnumọ ọn pe: “Ọrọ ìtàn nipa imularada nipa ìgbàgbọ́ ninu isin Kristian bẹrẹ pẹlu awọn iṣẹ-ojiṣẹ yiyanilẹnu gidigidi ti Jesu funraarẹ ati awọn aposteli rẹ̀ ṣe.” Bẹẹni, Jesu ṣe awọn iwosan titayọ. Njẹ awọn olumunilarada nipa igbgbọ lonii ha ń ṣe awọn iṣẹ iyanu gẹgẹ bi oun ti ṣe bi?

Igbagbọ—Ohun Kan Ti A Beere Fun?

Gẹgẹ bi iwe Black’s Bible Dictionary ṣe sọ, Jesu “mẹnukan [igbagbọ] ni pato gẹgẹ bi ohun akọkọ-beere fun imularada oniṣẹ iyanu rẹ̀.” Ṣugbọn iyẹn ha jẹ bi ọran ti rí bi? Jesu ha beere pe ki ẹnikan ti ń ṣaisan ní ìgbàgbọ́ ṣaaju ki oun to mú un láradá bi? Bẹẹkọ ni idahun naa. Ìgbàgbọ́ ni a nilo niha ọ̀dọ̀ olumunilarada naa ṣugbọn kò pọndandan kí ó jẹ́ niha ọ̀dọ̀ ẹni naa ti n ṣaisan. Ni akoko iṣẹlẹ kan awọn ọmọ-ẹhin Jesu kùnà lati wo ọmọdekunrin oníwárápá kan sàn. Jesu mu ọmọdekunrin naa larada o si sọ lẹhin naa fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ idi ti ko fi ṣeeṣe fun wọn lati mun un larada. “Jesu si wi fun wọn pe: Nitori aigbagbọ yin ni.”—Matteu 17:14-20.

Gẹgẹ bi Matteu 8:16, 17 ti wi, Jesu “mu awọn olókùnrùn laradá.” Nitootọ, awọn eniyan wọnyi ni ìwọ̀n ìgbàgbọ́ kan ninu Jesu ti o mu ki wọn wá sọdọ rẹ̀. (Matteu 8:13; 9:22, 29) Ninu awọn ọran ti o pọ̀ julọ wọn nilati wá ki wọn si beere ṣaaju ki o tó wò wọn sàn. Bi o ti wu ki o ri, ko si ijẹwọ ìgbàgbọ́ ti a beere fun lati lè ṣe iṣẹ iyanu naa. Ni akoko iṣẹlẹ kan Jesu wo ọkunrin arọ kan ti ko tilẹ mọ iru ẹni ti Jesu jẹ́ sàn. (Johannu 5:5-9, 13) Ni oru ọjọ ifaṣẹ ọba muni rẹ̀, Jesu mu etí iranṣẹ olori alufaa ti a ti gé dànù-fáú padabọsipo, bi o tilẹ jẹ pe ọkunrin yii jẹ́ ọ̀kan ninu awujọ awọn ọ̀tá Jesu ti wọn ti wá lati faṣẹ ọba mú un. (Luku 22:50, 51) Niti tootọ, ni akoko iṣẹlẹ kan Jesu tilẹ jí oku dide!—Luku 8:54, 55; Johannu 11:43, 44.

Bawo ni Jesu ṣe lè ṣe iru awọn iṣẹ iyanu bẹẹ? Nitori pe oun gbarale ẹmi mimọ, tabi ipá agbekankanṣiṣẹ ti Ọlọrun. Eyi ni ohun ti o ṣe iwosan naa, kì í ṣe ìgbàgbọ́ ẹnikọọkan ti ara rẹ̀ kò dá. Bi iwọ ba ka akọsilẹ iṣẹlẹ ninu awọn Ihinrere, iwọ pẹlu yoo ṣakiyesi pe awọn imularada lati ọwọ́ Jesu ni a kò ṣe pẹlu ààtò pẹ́pẹ́fúrú kan. Ko si ipafiyesi si ara-ẹni tabi ṣiṣamulo awọn ero-imọlara lọna aitọ. Siwaju sii, ohun yoowu ki aisan naa jẹ́, Jesu ko figbakanri kùnà. Oun maa ń ṣaṣeyọri nigba gbogbo, oun kò sì figbakanri beere owó.—Matteu 15:30, 31.

Awọn Imularada Ode-oni O Ha Dabi Awọn Wọnni Ti Jesu Ṣe Bi?

Aisan jẹ iṣoro ti o banilẹru, nigba ti o ba si kọluni, awa lọna ti ẹ̀dá yoo wá itura. Bi o ti wu ki o ri, ki ni, bi awa ba ń gbé ní ibikan nibi ti “a ti ń tọju awọn eniyan, ni pataki awọn wọnni ti wọn kò ni owo pupọ, nipasẹ awọn oṣiṣẹ ilera amọṣẹ́dunjú bii awọn nǹkan alailẹmii ti kì í si ṣe bii ẹ̀dá alààyè”? Ipo ọran ti dokita kan ṣakiyesi ni orilẹ-ede Latin-America niyẹn. Ki ni bi a ba ń gbé ni ibikan ti, gẹgẹ bi o ṣe ri ni orilẹ-ede yẹn kan-naa, ‘kiki ipin 40 ninu ọgọrun-un awọn dokita iṣegun ni wọn tootun lati ṣe iṣẹ àkọ́mọ̀ọ́ṣe wọn’?

Kò yanilẹnu pe ọpọlọpọ, ni ṣiṣairi ọna abajade miiran, wo imularada nipa igbagbọ gẹgẹ bi ohun ti o yẹ fun igbidanwo ó keretan. Sibẹsibẹ, awọn iwosan tí awọn olumunilarada nipa igbagbọ jẹwọ rẹ̀ ń fa ariyanjiyan. Fun apẹẹrẹ, iye ti a foju diwọn si 70,000 lọ si ipade kan ní São Paulo, Brazil, nibi ti awọn olumunilarada meji ‘ti fẹsẹ tẹ ọgọrọọrun awọn awò-ojú tí awọn awujọ naa dájọ mọ́lẹ̀, ní ṣiṣeleri imupadabọsipo iriran fun awọn agbàgbọ́ laiwadii ti o ni wọn.’ Ọ̀kan ninu awọn olumunilarada naa fi ailabosi gbà ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe: “Emi ko le sọ pe gbogbo awọn wọnni ti araawọn kò dá ti awa gbadura fun ni a o wosan. O sinmi lori ìgbàgbọ́ wọn. Bi ẹnikan ba gbàgbọ́, oun ni a o wosan.” Ó dẹbi ikuna lati di ẹni ti a mularada lori aini ìgbàgbọ́ niha ọ̀dọ̀ ẹni ti ara rẹ̀ kò dá naa. Bi o ti wu ki o ri, ranti, gẹgẹ bi a ti rí i ni iṣaaju, pe Jesu dẹbi ikuna lati munilarada lori aini ìgbàgbọ́ awọn wọnni ti ń ṣe imularada naa!

Olumunilarada miiran ṣeleri lati wo àrùn jẹjẹrẹ ati rọparọsẹ sàn. Ki ni ohun ti o ṣẹlẹ? Gẹgẹ bi iwe irohin Veja ṣe sọ, “ileri naa, lọna ti o han gbangba, ni a ko muṣẹ.” Sì fetisilẹ si ọ̀nà ti ọkunrin naa gbà huwa: “Fun eyi ti o fẹrẹẹ to wakati meji, [olumunilarada nipa ìgbàgbọ́ naa] dá awọn awujọ naa laraya pẹlu iwaasu, adura, igbe rara, orin kíkọ—o tilẹ ń lo ìkúùkú paapaa, pẹlu ireti lati lé awọn ẹmi eṣu ti o farapamọ si awọn oluṣotitọ lara jade. Ni opin rẹ̀, ó ju táì ọrùn rẹ̀ ati aṣọ pelebe ìnujú rẹ̀ si awọn awujọ ti a ti mú nimọlara idunnu lọna lilekenka naa o sì gbé igbá ọrẹ kan kaakiri ki o ba lè gba ‘awọn itọrẹ owo afinnun-findọ ṣe.’” Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ko figbakanri beere fun owo fun awọn imularada oniṣẹ iyanu, bẹẹ ni wọn kò sì lọwọ si iru awọn ifaraṣapejuwe onípẹ́pẹ́fúrú bẹẹ.

Nigba naa, lọna ti o han kedere, iru awọn oluminilarada nipa ìgbàgbọ́ ode-oni bẹẹ ko ṣe ohun ti Jesu ṣe. O sì ṣoro lati ri, pe Ọlọrun yoo fọwọsi ohun ti wọn ń ṣe. Bi o tilẹ ri bẹẹ, oun ha fọwọsi imularada oniṣẹ iyanu eyikeyii lonii bi? Tabi ọna eyikeyii ha wà ti ìgbàgbọ́ wa fi lè ràn wa lọwọ nigba ti awa tabi awọn ololufẹ wa bá dùbúlẹ̀ aisan bi?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́