ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Àwọn Ọba

      • Jèhófà tún fara han Sólómọ́nì (1-9)

      • Ẹ̀bùn tí Sólómọ́nì fún Ọba Hírámù (10-14)

      • Oríṣiríṣi iṣẹ́ ìkọ́lé tí Sólómọ́nì ṣe (15-28)

1 Àwọn Ọba 9:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 8:1; Onw 2:4
  • +2Kr 7:11

1 Àwọn Ọba 9:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 3:5

1 Àwọn Ọba 9:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 12:5, 6; 1Ọb 8:28, 29
  • +2Kr 6:40; 16:9; Sm 132:13

1 Àwọn Ọba 9:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 3:6
  • +Sm 78:70, 72
  • +1Kr 29:17
  • +Onw 12:13
  • +2Kr 7:17, 18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2012, ojú ìwé 7

    8/15/2007, ojú ìwé 12

    5/1/1997, ojú ìwé 5

1 Àwọn Ọba 9:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 7:16, 17; 1Ọb 2:4; Sm 89:20, 29

1 Àwọn Ọba 9:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 11:4; 2Kr 7:19-22

1 Àwọn Ọba 9:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àfipòwe.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:28; Di 4:26; 2Sa 7:14; 2Ọb 17:22, 23; Sm 89:30-32
  • +2Ọb 25:9, 10; 2Kr 15:2
  • +Di 28:37; Sm 44:14

1 Àwọn Ọba 9:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:19; Ais 64:11
  • +Di 29:24, 25; Jer 22:8, 9

1 Àwọn Ọba 9:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:64; Jer 5:19; 12:7

1 Àwọn Ọba 9:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:37-7:1; 2Kr 8:1, 2

1 Àwọn Ọba 9:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:1, 7
  • +1Ọb 5:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2005, ojú ìwé 29

1 Àwọn Ọba 9:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “wọn kò dára ní ojú rẹ̀.”

1 Àwọn Ọba 9:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Ilẹ̀ Tí Kò Dára fún Ohunkóhun.”

1 Àwọn Ọba 9:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 10:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2008, ojú ìwé 22

1 Àwọn Ọba 9:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

  • *

    Tàbí “Mílò.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “iyẹ̀pẹ̀ tí a kó jọ gègèrè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 4:6; 5:13
  • +1Ọb 6:37
  • +2Sa 5:9; 1Ọb 11:27; 2Ọb 12:20
  • +Joṣ 19:32, 36
  • +Joṣ 17:11; Ond 5:19; 2Ọb 9:27
  • +Ond 1:29

1 Àwọn Ọba 9:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹ̀bùn ìgbéyàwó; nǹkan ìyàwó.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 16:10
  • +1Ọb 3:1

1 Àwọn Ọba 9:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mọ odi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 16:1, 3; 2Kr 8:4-6

1 Àwọn Ọba 9:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 19:44, 48

1 Àwọn Ọba 9:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 4:26

1 Àwọn Ọba 9:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 13:29; Di 7:1; Ond 1:21
  • +2Kr 8:7-10

1 Àwọn Ọba 9:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 9:25

1 Àwọn Ọba 9:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 25:39

1 Àwọn Ọba 9:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:16; 2Kr 2:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2005, ojú ìwé 19

1 Àwọn Ọba 9:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Mílò.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “iyẹ̀pẹ̀ tí a kó jọ gègèrè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 3:1; 7:8; 2Kr 8:11
  • +2Sa 5:9
  • +1Ọb 9:15

1 Àwọn Ọba 9:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:14
  • +2Kr 8:12, 13
  • +2Kr 8:16

1 Àwọn Ọba 9:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 2:8
  • +2Kr 8:17, 18

1 Àwọn Ọba 9:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:12

1 Àwọn Ọba 9:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 10:29; 1Kr 29:3, 4; Sm 45:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2008, ojú ìwé 22

Àwọn míì

1 Ọba 9:12Kr 8:1; Onw 2:4
1 Ọba 9:12Kr 7:11
1 Ọba 9:21Ọb 3:5
1 Ọba 9:3Di 12:5, 6; 1Ọb 8:28, 29
1 Ọba 9:32Kr 6:40; 16:9; Sm 132:13
1 Ọba 9:41Ọb 3:6
1 Ọba 9:4Sm 78:70, 72
1 Ọba 9:41Kr 29:17
1 Ọba 9:4Onw 12:13
1 Ọba 9:42Kr 7:17, 18
1 Ọba 9:52Sa 7:16, 17; 1Ọb 2:4; Sm 89:20, 29
1 Ọba 9:61Ọb 11:4; 2Kr 7:19-22
1 Ọba 9:7Le 18:28; Di 4:26; 2Sa 7:14; 2Ọb 17:22, 23; Sm 89:30-32
1 Ọba 9:72Ọb 25:9, 10; 2Kr 15:2
1 Ọba 9:7Di 28:37; Sm 44:14
1 Ọba 9:82Kr 36:19; Ais 64:11
1 Ọba 9:8Di 29:24, 25; Jer 22:8, 9
1 Ọba 9:9Di 28:64; Jer 5:19; 12:7
1 Ọba 9:101Ọb 6:37-7:1; 2Kr 8:1, 2
1 Ọba 9:111Ọb 5:1, 7
1 Ọba 9:111Ọb 5:8
1 Ọba 9:141Ọb 10:21
1 Ọba 9:151Ọb 4:6; 5:13
1 Ọba 9:151Ọb 6:37
1 Ọba 9:152Sa 5:9; 1Ọb 11:27; 2Ọb 12:20
1 Ọba 9:15Joṣ 19:32, 36
1 Ọba 9:15Joṣ 17:11; Ond 5:19; 2Ọb 9:27
1 Ọba 9:15Ond 1:29
1 Ọba 9:16Joṣ 16:10
1 Ọba 9:161Ọb 3:1
1 Ọba 9:17Joṣ 16:1, 3; 2Kr 8:4-6
1 Ọba 9:18Joṣ 19:44, 48
1 Ọba 9:191Ọb 4:26
1 Ọba 9:20Nọ 13:29; Di 7:1; Ond 1:21
1 Ọba 9:202Kr 8:7-10
1 Ọba 9:21Jẹ 9:25
1 Ọba 9:22Le 25:39
1 Ọba 9:231Ọb 5:16; 2Kr 2:18
1 Ọba 9:241Ọb 3:1; 7:8; 2Kr 8:11
1 Ọba 9:242Sa 5:9
1 Ọba 9:241Ọb 9:15
1 Ọba 9:25Ẹk 23:14
1 Ọba 9:252Kr 8:12, 13
1 Ọba 9:252Kr 8:16
1 Ọba 9:26Di 2:8
1 Ọba 9:262Kr 8:17, 18
1 Ọba 9:271Ọb 5:12
1 Ọba 9:28Jẹ 10:29; 1Kr 29:3, 4; Sm 45:9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Àwọn Ọba 9:1-28

Àwọn Ọba Kìíní

9 Gbàrà tí Sólómọ́nì parí kíkọ́ ilé Jèhófà àti ilé* ọba+ àti gbogbo ohun tó wu Sólómọ́nì láti ṣe,+ 2 Jèhófà wá fara han Sólómọ́nì nígbà kejì, bó ṣe fara hàn án ní Gíbíónì.+ 3 Jèhófà sọ fún un pé: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ àti ẹ̀bẹ̀ tí o bẹ̀ fún ojú rere níwájú mi. Mo ti ya ilé tí o kọ́ yìí sí mímọ́ torí mo ti fi orúkọ mi síbẹ̀ títí lọ,+ ojú mi àti ọkàn mi á sì máa wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.+ 4 Ní tìrẹ, tí o bá rìn níwájú mi bí Dáfídì bàbá rẹ ṣe rìn+ pẹ̀lú òtítọ́ ọkàn+ àti ìdúróṣinṣin,+ tí ò ń ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ,+ tí o sì ń pa àwọn ìlànà mi àti àwọn ìdájọ́ mi mọ́,+ 5 ìgbà náà ni màá fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ lórí Ísírẹ́lì múlẹ̀ títí láé, bí mo ti ṣèlérí fún Dáfídì bàbá rẹ pé, ‘Kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.’+ 6 Àmọ́ tí ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín bá pa dà lẹ́yìn mi, tí ẹ kò sì pa àwọn àṣẹ àti òfin tí mo fún yín mọ́, tí ẹ wá lọ ń sin àwọn ọlọ́run míì, tí ẹ sì ń forí balẹ̀ fún wọn,+ 7 ṣe ni màá ké Ísírẹ́lì kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn,+ màá gbé ilé tí mo ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi sọ nù kúrò níwájú mi,+ Ísírẹ́lì yóò sì di ẹni ẹ̀gàn* àti ẹni ẹ̀sín láàárín gbogbo èèyàn.+ 8 Ilé yìí á di àwókù.+ Gbogbo ẹni tó bá gba ibẹ̀ kọjá á wò ó tìyanutìyanu, á súfèé, á sì sọ pé, ‘Kì nìdí tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí àti sí ilé yìí?’+ 9 Nígbà náà, wọ́n á sọ pé, ‘Torí pé wọ́n fi Jèhófà Ọlọ́run wọn sílẹ̀ ni, ẹni tó mú àwọn baba ńlá wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n yíjú sí àwọn ọlọ́run míì, wọ́n ń forí balẹ̀ fún wọn, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi mú gbogbo àjálù yìí bá wọn.’”+

10 Ní òpin ogún (20) ọdún tí Sólómọ́nì fi kọ́ ilé méjèèjì, ìyẹn ilé Jèhófà àti ilé* ọba,+ 11 Hírámù+ ọba Tírè fún Sólómọ́nì ní àwọn gẹdú igi kédárì àti ti júnípà pẹ̀lú ọ̀pọ̀ wúrà tí ó béèrè,+ Ọba Sólómọ́nì sì fún Hírámù ní ogún (20) ìlú ní ilẹ̀ Gálílì. 12 Torí náà, Hírámù jáde kúrò ní Tírè láti lọ wo àwọn ìlú tí Sólómọ́nì fún un, àmọ́ wọn kò tẹ́ ẹ lọ́rùn.* 13 Ó sọ pé: “Irú àwọn ìlú wo ni o fún mi yìí, arákùnrin mi?” Torí náà, Ilẹ̀ Kábúlù* ni à ń pè wọ́n títí di òní yìí. 14 Ní àkókò yẹn, Hírámù fi ọgọ́fà (120) tálẹ́ńtì* wúrà+ ránṣẹ́ sí ọba.

15 Èyí ni ìròyìn nípa àwọn tí Ọba Sólómọ́nì ní kó máa ṣiṣẹ́ fún òun+ láti kọ́ ilé Jèhófà,+ ilé* tirẹ̀, Òkìtì,*+ ògiri Jerúsálẹ́mù, Hásórì,+ Mẹ́gídò+ àti Gésérì.+ 16 (Fáráò ọba Íjíbítì ti wá gba Gésérì, ó dáná sun ún, ó sì pa àwọn ọmọ Kénáánì+ tó ń gbé ìlú náà. Nítorí náà, ó fi ṣe ẹ̀bùn ìdágbére* fún ọmọbìnrin rẹ̀,+ aya Sólómọ́nì.) 17 Sólómọ́nì kọ́* Gésérì, Bẹti-hórónì Ìsàlẹ̀,+ 18 Báálátì+ àti Támárì ní aginjù, ó kọ́ wọn sórí ilẹ̀ náà, 19 Sólómọ́nì tún kọ́ gbogbo àwọn ìlú tó ń kó nǹkan pa mọ́ sí, àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin,+ àwọn ìlú àwọn agẹṣin àti ohunkóhun tó wu Sólómọ́nì láti kọ́ sí Jerúsálẹ́mù, sí Lẹ́bánónì àti sí gbogbo ilẹ̀ tó ń ṣàkóso lé lórí. 20 Ní ti gbogbo èèyàn tó ṣẹ́ kù lára àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ tí wọn kì í ṣe ara àwọn èèyàn Ísírẹ́lì,+ 21 àwọn àtọmọdọ́mọ wọn tó ṣẹ́ kù sí ilẹ̀ náà, ìyẹn àwọn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lè pa run, Sólómọ́nì ní kí wọ́n máa ṣíṣẹ́ fún òun bí ẹrú títí di òní yìí.+ 22 Àmọ́ Sólómọ́nì kò fi ọmọ Ísírẹ́lì kankan ṣe ẹrú,+ àwọn ló fi ṣe jagunjagun, ìránṣẹ́, ìjòyè, olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun, olórí àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ti àwọn agẹṣin rẹ̀. 23 Ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé àádọ́ta (550) olórí àwọn alábòójútó ló ń darí iṣẹ́ Sólómọ́nì, àwọn ló sì ń darí àwọn òṣìṣẹ́.+

24 Ọmọbìnrin Fáráò+ wá láti Ìlú Dáfídì+ sí ilé tirẹ̀ tí Sólómọ́nì kọ́ fún un; lẹ́yìn náà ó mọ Òkìtì.*+

25 Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún+ ni Sólómọ́nì máa ń rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ lórí pẹpẹ tó mọ fún Jèhófà,+ ó tún ń mú ẹbọ rú èéfín lórí pẹpẹ náà, tí ó wà níwájú Jèhófà. Bí ó sì ṣe parí ilé náà nìyẹn.+

26 Ọba Sólómọ́nì tún ṣe ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun ní Esioni-gébérì,+ tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Élótì, ní èbúté Òkun Pupa ní ilẹ̀ Édómù.+ 27 Hírámù kó ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun+ rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òkun tó mọṣẹ́, láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì. 28 Wọ́n lọ sí Ófírì,+ wọ́n sì kó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ogún (420) tálẹ́ńtì wúrà láti ibẹ̀ wá fún Ọba Sólómọ́nì.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́