Ẹ̀mí Ayé Ha Ń bà Ọ́ Jẹ́ Bí?
NÍ September 12, 1990, ìbúgbàù kan ṣẹlẹ̀ ní ilé iṣẹ́ kan ní Kazakstan. A tú ìgbì ìtànṣán olóró sínú atẹ́gùn, ní wíwu ìlera 120,000 àwọn olùgbé àdúgbò náà léwu, ọ̀pọ̀ lára wọn sì tú yẹ́ẹ́yẹ́ sójú pópó láti fẹ̀hónú wọn hàn nípa májèlé olóró náà.
Ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe túbọ̀ rí ọ̀pọ̀ ìsọfúnni gbà sí i, wọ́n rí i pé àwọn ti ń gbé ní àyíká onímájèlé fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún. Jálẹ̀ ọ̀pọ̀ ọdún, 100,000 tọ́ọ̀nù pàǹtírí ìgbì ìtànṣán olóró ni a ti kó sí ibi gbàgede kan, tí a kò bò mọ́lẹ̀. Bí ewu náà tilẹ̀ wà lẹ́nu ọ̀nà wọn, kò sí ẹnì kan tí ó fọwọ́ danin-danin mú un. Èé ṣe?
Lójoojúmọ́, nínú pápá ìṣeré àdúgbò, àwọn òṣìṣẹ́ máa ń lẹ iye ìgbì ìtànṣán olóró tí ó wà láyìíká mọ́ ara ògiri, tí ń múni lérò pé kò séwu rárá. Iye náà péye, ṣùgbọ́n kìkì ìtànṣán gamma nìkan ni wọ́n fi hàn. Ìtànṣán alpha, tí a kò wọn iye tí ó jẹ́, sì lè ṣekú pani lọ́nà kan náà. Ọ̀pọ̀ ìyá bẹ̀rẹ̀ sí í lóye ìdí tí àwọn ọmọ wọn fi ń ṣàìsàn.
Nípa tẹ̀mí, májèlé tí a kò lè fojú rí lè ṣekú pa wá pẹ̀lú. Gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn ará Kazakstan wọ̀nyẹn tí wọ́n kàgbákò, ọ̀pọ̀ jù lọ kò mọ̀ nípa jàǹbá tí ń wu ìwàláàyè léwu yìí. Bíbélì pe ohun tí ń bani jẹ́ yìí ní “ẹ̀mí ayé,” tí ó dájú pé Sátánì Èṣù ni ó wà nídìí rẹ̀. (Kọ́ríńtì Kíní 2:12) Elénìní Ọlọ́run ń fi ẹ̀tanú lo ẹ̀mí—tàbí ẹ̀mí ìrònú tí ó gbòde kan—ti ayé yìí láti ba ìfọkànsìn wa sí Ọlọ́run jẹ́.
Báwo ni ẹ̀mí ayé ṣe lè gba okun wa nípa tẹ̀mí? Nípa ríru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú sókè àti nípa lílo ìmọtara-ẹni-nìkan tí a bí mọ́ wa. (Éfésù 2:1-3; Jòhánù Kíní 2:16) Lọ́nà àpẹẹrẹ, a óò gbé ọ̀nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí ìrònú ayé fi lè ba ipò tẹ̀mí wa jẹ́ díẹ̀díẹ̀ yẹ̀ wò.
Wíwá Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́
Jésù rọ àwọn Kristẹni láti ‘wá Ìjọba náà àti òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́.’ (Mátíù 6:33) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹ̀mí ayé lè sún wa láti gbé ìjẹ́pàtàkì tí kò yẹ karí ìfẹ́ ọkàn àti ìtura tiwa fúnra wa. Kì í ṣe pípa ire tẹ̀mí tì pátápátá ni ewu àkọ́kọ́, bí kò ṣe fífọwọ́ rọ́ ọ tì sí ipò kejì. A lè ṣàìka ewu náà sí—bí àwọn ará Kazakstan ti ṣe—nítorí èrò títan ara wọn jẹ pé kò séwu. Ọ̀pọ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn tí a ti fòtítọ́ ṣe àti ìmọrírì tí a ní fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí lè mú kí a jọ̀gọ̀nù ní ríronú pé a kò lè fi ọ̀nà òtítọ́ sílẹ̀ láé. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ tí ń bẹ ní ìjọ Éfésù ti ronú lọ́nà yẹn.
Ní nǹkan bí ọdún 96 Sànmánì Tiwa, Jésù fún wọn nímọ̀ràn tí ó tẹ̀ lé e yìí: “Mo ní èyí lòdì sí ọ, pé ìwọ ti fi ìfẹ́ tí ìwọ ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.” (Ìṣípayá 2:4) Àwọn Kristẹni tí wọ́n ti ń sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún wọ̀nyí ti fara da ọ̀pọ̀ ìṣòro. (Ìṣípayá 2:2, 3) Àwọn alàgbà olùṣòtítọ́, títí kan àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ni wọ́n kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Ìṣe 20:17-21, 27) Ṣùgbọ́n, bí ọdún ti ń gorí ọdún, ìfẹ́ wọn fún Jèhófà dín kù, wọ́n sì pàdánù ìsúnniṣe wọn tẹ̀mí.—Ìṣípayá 2:5.
Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé, ẹ̀mí ìṣòwò àti aásìkí ìlú náà ti nípa lórí àwọn kan lára àwọn ará Éfésù. Ó bani nínú jẹ́ pé, ìtẹ̀sí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì ti àwùjọ òde òní ti gbé àwọn Kristẹni kan lọ pẹ̀lú. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìpinnu láti lépa ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ yóò mú kí a yà bàrá kúrò nínú lílépa àwọn góńgó tẹ̀mí.—Fi wé Mátíù 6:24.
Ní kíkìlọ̀ nípa ewu yìí, Jésù wí pé: “Fìtílà ara ni ojú. Nígbà náà, bí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan, gbogbo ara rẹ yóò mọ́lẹ̀ yòò; ṣùgbọ́n bí ojú rẹ bá burú pin [“bá ń ṣe ìlara,” àlàyé ẹsẹ̀ ìwé], gbogbo ara rẹ yóò ṣókùnkùn.” (Mátíù 6:22, 23) Ojú tí ó “mú ọ̀nà kan” ni ojú tí ó gbébìkan nípa tẹ̀mí, ojú tí a tẹ̀ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ojú tí ó “burú pin” tàbí èyí tí ó “bá ń ṣe ìlara” kò lè ríran jìnnà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹran ara tí ń bẹ lọ́kàn rẹ̀ nìkan ni ó lè rí. Kò lè rí àwọn góńgó tẹ̀mí àti èrè ọjọ́ ọ̀la.
Jésù sọ nínú ẹsẹ tí ó ṣáájú pé: “Níbi tí ìṣúra rẹ bá wà, níbẹ̀ ni ọkàn àyà rẹ yóò wà pẹ̀lú.” (Mátíù 6:21) Báwo ni a ṣe lè mọ̀ bóyá a fi ọkàn àyà wa sórí ohun tẹ̀mí tàbí sórí ohun ti ara? Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ tí a ń sọ jẹ́ ohun dídára jù lọ ti a fi lè mọ̀, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ‘lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn àyà ni ẹnu ń sọ.’ (Lúùkù 6:45) Bí ó bá jẹ́ pé ohun ti ara tàbí àṣeyọrí ti ayé ni ọ̀rọ̀ wa sábà máa ń dá lé lórí, ó ṣe kedere pé ọkàn àyà wa ti pínyà àti pé agbára ìríran wa nípa tẹ̀mí kù-díẹ̀-káà-tó.
Carmen, arábìnrin ará Sípéènì kan, bá ìṣòro yìí wọ̀jà.a Carmen ṣàlàyé pé: “A tọ́ mi dàgbà nínú òtítọ́, ṣùgbọ́n nígbà tí mo di ẹni ọdún 18, mo dá ilé ẹ̀kọ́ jẹ́lé-ó-sinmi tèmi sílẹ̀. Mo ti ní òṣìṣẹ́ mẹ́rin ni ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, òwò náà ń lọ geerege, ọ̀pọ̀ owó sì ń wọlé fún mi. Ṣùgbọ́n, ó jọ pé ohun tí ó mú ìtẹ́lọ́rùn jù lọ wá fún mi ni òtítọ́ náà pé mo lè dá gbọ́ bùkátà ara mi, mo sì ‘kẹ́sẹ járí.’ Ní tòótọ́, ìdí òwò mi ni ọkàn mi wà—òun ni ohun tí mo nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ.
“Mo rò pé mo ṣì lè jẹ́ Ẹlẹ́rìí bí mo tilẹ̀ ń ya èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú àkókò mi sọ́tọ̀ fún òwò mi. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, èrò pé mo lè ṣe púpọ̀ sí i láti sin Jèhófà tún máa ń wá sí mi lọ́kàn léraléra. Ohun tí ó yí mi lérò pa dà nígbẹ̀yìngbẹ́yín láti fi ire Ìjọba náà sí ipò kíní ni, àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rẹ́ mi méjì tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Ọ̀kan lára wọn, Juliana, wà nínú ìjọ mi. Kò fipá mú mi wọnú ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ayọ̀ tí ó hàn gbangba pé ó ń rí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ràn mí lọ́wọ́ láti tún àwọn ohun tí ó jẹ́ pàtàkì fún mi nípa tẹ̀mí gbé yẹ̀ wò.
“Nígbà tí ó yá, tí mo lọ lo ìsinmi mi ní United States, mo dé sọ́dọ̀ Gloria, arábìnrin aṣáájú ọ̀nà kan. Kò tí ì pẹ́ púpọ̀ tí ọkọ rẹ̀ kú, ó sì ń tọ́jú ọmọdébìnrin rẹ̀ ọlọ́dún márùn-ún àti màmá rẹ̀ tí àrùn jẹjẹrẹ ń yọ lẹ́nu. Síbẹ̀ ó ń ṣe aṣáájú ọ̀nà. Àpẹẹrẹ rẹ̀ àti ìmọrírì àtọkànwá tí ó ní fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ gbún ọkàn àyà mi ní kẹ́ṣẹ́. Ọjọ́ mẹ́rin péré tí mo lò nínú ilé rẹ̀ mú kí n pinnu láti ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Lákọ̀ọ́kọ́, mo di aṣáájú ọ̀nà déédéé, ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, a pe èmi àti ọkọ mi láti wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Mo fi òwò mi—ìdènà kan fún ìtẹ̀síwájú mi nípa tẹ̀mí—sílẹ̀ mo sì nímọ̀lára nísinsìnyí pé ìgbésí ayé mi kẹ́sẹ járí lójú Jèhófà, èyí tí ó jẹ́ ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ.”—Lúùkù 14:33.
Kíkọ́ láti “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” gẹ́gẹ́ bí Carmen ti ṣe, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tí ó yè kooro nípa iṣẹ́, ẹ̀kọ́ ìwé, ilé gbígbé, àti ọ̀nà tí a ń gbà gbé ìgbésí ayé wa. (Fílípì 1:10) Ṣùgbọ́n a ha máa ń wádìí dájú nípa àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù nígbà tí ó bá di ọ̀ràn eré ìnàjú bí? Ọ̀nà míràn tún nìyí tí ẹ̀mí ayé gbà ń nípa lórí wa lọ́nà kíkàmàmà.
Fi Fàájì Sí Àyè Tí Ó Yẹ Ẹ́
Ẹ̀mí ayé ń fọgbọ́n ẹ̀wẹ́ lo ìfẹ́ ọkàn tí a dá mọ́ ènìyàn fún ìsinmi àti fàájì. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn kò ti ní ìrètí tòótọ́ fún ọjọ́ ọ̀la, ìdí tí wọ́n fi ń wá ọ̀nà láti lo àkókò ìsinsìnyí fún eré ìnàjú àti eré ìtura yéni. (Fi wé Aísáyà 22:13; Kọ́ríńtì Kíní 15:32.) A ha rí ara wa tí a túbọ̀ ń fún fàájì ní ìjẹ́pàtàkì gíga sí i bí? Ìyẹn lè jẹ́ àmì kan pé ọ̀nà ìrònú ti ayé ti ń nípa lórí ojú ìwòye wa.
Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́ [“eré ìnàjú,” Lamsa] yóò di tálákà.” (Òwe 21:17) Gbígbafẹ́ kò burú, ṣùgbọ́n nínífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tàbí kíkà á sí ohun tí ó ṣe pàtàkì jù, yóò yọrí sí dídi tálákà nípa tẹ̀mí. A kò ní lè jẹun tààrà nípa tẹ̀mí mọ́, àkókò tí a óò sì ní fún wíwàásù ìhìn rere náà yóò kéré jọjọ.
Látàrí èyí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá láti “fi èrò orí gbára dì fún ìgbésẹ̀, kí a sì lo ìkóra-ẹni-níjàánu lọ́nà pípé.” (Pétérù Kíní 1:13, The New English Bible) A nílò ìkóra-ẹni-níjàánu láti lè fi àkókò tí a ń lò fún fàájì mọ sí èyí tí ó mọ níwọ̀n. Gbígbáradì fún ìgbésẹ̀ túmọ̀ sí wíwà ní sẹpẹ́ fún ìgbòkègbodò tẹ̀mí, yálà fún ìkẹ́kọ̀ọ́, ìpàdé, tàbí iṣẹ́ ìsìn pápá.
Ìsinmi tí a nílò ńkọ́? Ọkàn rẹ ha dá ọ lẹ́bi nígbà tí a bá gba àkókò láti sinmi bí? Rárá o. Ìsinmi ṣe kókó, ní pàtàkì nínú ayé onímásùnmáwo òde òní. Síbẹ̀síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni olùṣèyàsímímọ́, a kò lè yọ̀ǹda kí fàájì gba gbogbo ìgbésí ayé wa. Fàájì tí ó pọ̀ jù lè mú kí a jọ̀gọ̀nù ní dídín bí a ṣe ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò pàtàkì kù. Ó lè dín òye ìjẹ́kánjúkánjú wa kù, ó sì lè fún ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́ níṣìírí pàápàá. Nígbà náà, báwo ni a ṣe lè ní ojú ìwòye tí ó wà déédéé nípa ìsinmi?
Bíbélì dámọ̀ràn sísinmi díẹ̀ dípò ṣíṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó—ní pàtàkì bí iṣẹ́ ti ara náà kò bá pọn dandan. (Oníwàásù 4:6) Bí ìsinmi tilẹ̀ ń ran ara wa lọ́wọ́ láti jèrè okun, ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ni orísun agbára tẹ̀mí. (Aísáyà 40:29-31) A ń rí ẹ̀mí mímọ́ yìí gbà nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni wa. Ìdákẹ́kọ̀ọ́ ń bọ́ ọkàn àyà wa, ó sì ń ru ìfẹ́ ọkàn tí ó tọ́ sókè nínú wa. Wíwá sí àwọn ìpàdé ń mú kí ìmọrírì wa fún Ẹlẹ́dàá wa gbilẹ̀ sí i. Lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni túbọ̀ ń jẹ́ kí a ní ìmọ̀lára fun àwọn ẹlòmíràn. (Kọ́ríńtì Kíní 9:22, 23) Bí Pọ́ọ̀lù ti ṣàlàyé láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, “ẹni tí a jẹ́ ní òde ń bà jẹ́, ṣùgbọ́n ẹni tí a jẹ́ ní inú ń gba okun àkọ̀tun.”—Kọ́ríńtì Kejì 4:16, Phillips.
Ileana, màmá ọmọ mẹ́fà tí ó sì jẹ́ aya ọkọ aláìgbàgbọ́, ń gbé ìgbésí ayé tí ó dí fọ́fọ́. Ó ní ojúṣe tí yóò ṣe fún ìdílé rẹ̀ àti àwọn mọ̀lẹ́bí mìíràn, tí ó túmọ̀ sí pé ìgbà gbogbo ni ó jọ bí ẹni pé ó ń sá kìtàkìtà kiri. Síbẹ̀síbẹ̀, ó tún fi àpẹẹrẹ tí ó gba àfiyèsí lélẹ̀ nínú wíwàásù àti mímúra ìpàdé sílẹ̀. Báwo ni ó ṣe lè bójú to ìgbòkègbodò púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀?
Ileana ṣàlàyé pé: “Àwọn ìpàdé àti iṣẹ́ ìsìn pápá máa ń ràn mí lọ́wọ́ ní ti gidi láti bójú tó àwọn ojúṣe mi mìíràn. Fún àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí mo bá ti òde ìwàásù dé, mo máa ń ní ọ̀pọ̀ nǹkan tí n óò ronú lé lórí nígbà tí mo bá ń ṣiṣẹ́ ilé. Lọ́pọ̀ ìgbà mo máa ń kọrin bí mo ti ń ṣe é. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí mo bá pa ìpàdé jẹ tàbí tí n kò bá fi bẹ́ẹ̀ jáde fún iṣẹ́ ìsìn pápá, iṣẹ́ ilé máa ń di ohun tí ó ń béèrè ìsapá gidigidi.”
Ẹ wo bí èyí ti yàtọ̀ pátápátá tó sí gbígbé ìjẹ́pàtàkì rírékọjá ààlà karí fàájì!
Ẹwà Tẹ̀mí Ń Dùn Mọ́ Jèhófà Nínú
A ń gbé nínú ayé kan tí ìrísí òde ti túbọ̀ ń gbani lọ́kàn. Àwọn ènìyàn ń náwó gọbọi lórí ìtọ́jú tí a ṣètò láti mú kí ìrísí wọn sunwọ̀n sí i, kí ó sì dín ipa tí ọjọ́ ogbó ń ní lórí ara kù. Èyí ní nínú, fífi irun àtọwọ́dá sí ibi tí orí ti pá àti fífi dáì pa irun, iṣẹ́ abẹ àfikún ọmú, àti ti sísọ ojú di ojú ọ̀dọ́. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ń lọ sí àwọn ibùdó tí a ti ń dín ìwọ̀n ara kù, gbọ̀ngàn ìṣeré ìfarapitú àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ eré ìmárale, tàbí kí wọ́n ra fídíò tí ń kọ́ni ní eré ìmárale àti àwọn ìwé tí ó dá lórí ìdíwọ̀n oúnjẹ. Ayé yóò mú kí a gbà gbọ́ pé ìrísí òde wa nìkan ni ó lè mú wa láyọ̀, pé “ìrínisí” wa ni ó ṣe pàtàkì jù.
Ní United States, ìwádìí kan tí ìwé ìròyìn Newsweek ṣe rí i pé ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́langba ará America aláwọ̀ funfun ni “bí ara wọ́n ṣe rí kò tẹ́ lọ́rùn.” Ìyánhànhàn lílékenkà fún ìrísí tí ó pegedé láìkọ ohun tí yóò náni sí lè nípa lórí ipò tẹ̀mí wa. Dora jẹ́ ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tí ìrísí rẹ̀ ń tì lójú nítorí pé ó sanra díẹ̀. Ó ṣàlàyé pé: “Tí mo bá lọ raṣọ, ó máa ń ṣòro fún mi láti rí ẹ̀wù tí yóò bá mi mu. Ó dà bíi pé àwọn ọ̀dọ́langba ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́ nìkan ni a ṣe àwọn ẹwu tí ó bóde mu fún. Èyí tí ó burú jù lọ ni pé, àwọn ènìyàn máa ń sọ̀rọ̀ kòbákùngbé nípa bí mo ṣe sanra tó, tí ó sì ń mú mi bínú gan-an, ní pàtàkì, bí ó bá tẹnu àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi nípa tẹ̀mí jáde.
“Àbájáde rẹ̀ ni pé, ìrísí mi túbọ̀ ń gbà mí lọ́kàn, títí débi pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ohun tẹ̀mí ṣíṣeyebíye sí ipò kejì nínú ìgbésí ayé mi. Ó wá dà bíi pé ayọ̀ mi sinmi lórí ìwọ̀n ìbàdí mi. Nísinsìnyí, ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá, mo ti di obìnrin, mo sì ti di Kristẹni kan tí ó dàgbà dénú, mo ti wá ní ojú ìwòye tí ó yàtọ̀. Bí mo tilẹ̀ ń tọ́jú ìrísí mi, mo mọ̀ pé ẹwà tẹ̀mí ni ó ṣe pàtàkì jù, ìyẹn sì ni ó ń fún mi ní ìtẹ́lọ́rùn gíga lọ́lá. Gbàrà tí mo ti lóye ìyẹn, ó ṣeé ṣe fún mi láti fi ire Ìjọba sí àyè tí ó yẹ ẹ́.”
Sárà jẹ́ olùṣòtítọ́ obìnrin ìgbàanì kan tí ó ní ojú ìwòye tí ó wà déédéé yìí. Bí Bíbélì tilẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ẹwà rẹ̀ nípa ti ara nígbà tí ó lé ní ẹni 60 ọdún, ó darí àfiyèsí ní pàtàkì sí àwọn ànímọ́ rere rẹ̀—ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn àyà. (Jẹ́nẹ́sísì 12:11; Pétérù Kíní 3:4-6) Ó fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìwà tútù hàn, ó sì fi ìtẹríba ṣègbọràn sí ọkọ rẹ̀. Sárà kò ṣàníyàn tí kò yẹ nípa ojú tí àwọn ẹlòmíràn fi ń wò ó. Bí ó tilẹ̀ wá láti ìdílé ọlọ́rọ̀, ó fínnú fíndọ̀ gbé nínú àgọ́ fún ohun tí ó lé ní 60 ọdún. Ó fi ìwà tútù àti àìmọtara-ẹni-nìkan ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn; ó jẹ́ obìnrin ìgbàgbọ́. Ohun ni ó mú kí ó jẹ́ arẹwà obìnrin ní tòótọ́.—Òwe 31:30; Hébérù 11:11.
Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a nífẹ̀ẹ́ nínú mímú kí ẹwà wa nípa tẹ̀mí sunwọ̀n sí i, ẹwà kan tí ó jẹ́ pé bí a bá tọ́jú rẹ̀ dáradára, yóò pọ̀ sí i, yóò sì wà pẹ́ títí. (Kólósè 1:9, 10) Ọ̀nà pàtàkì méjì ni a lè gbà tọ́jú ìrísí wa nípa tẹ̀mí.
A túbọ̀ ń di arẹwà lójú Jèhófà bí a ti ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa tí ń gbẹ̀mí là. (Aísáyà 52:7; Kọ́ríńtì Kejì 3:18–4:2) Síwájú sí i, bí a ti ń kọ́ láti fi àwọn ànímọ́ Kristẹni hàn, ẹwà wa ń jinlẹ̀ sí i. Àwọn àǹfààní tí a ní láti mú ẹwà wa nípa tẹ̀mí sunwọ̀n sí i kò lóǹkà: “Ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kíní kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kíní kejì ẹ mú ipò iwájú. . . . Kí iná ẹ̀mí máa jó nínú yín. . . . Ẹ máa tẹ̀ lé ìlà ipa ọ̀nà aájò àlejò. . . . Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀; ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún. . . . Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. . . . Ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:10-18) Mímú irú àwọn ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ dàgbà yóò mú kí a jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún Ọlọ́run àti àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa, yóò sì dín ìrísí bíburẹ́wà ti ìtẹ̀sí ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti jogún kù.—Gálátíà 5:22, 23; Pétérù Kejì 1:5-8.
A Lè Gbógun Ti Ẹ̀mí Ayé!
Ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí a kò lè tètè fura sí, ẹ̀mí ayé onímájèlé lè ba ìwà títọ́ wa jẹ́. Ó lè mú kí a máà ní ìtẹ́lọ́rùn mọ́ pẹ̀lú ohun tí a ní, kí a sì máa ṣàníyàn láti fi àìní wa àti ire wa ṣáájú ti Ọlọ́run. Tàbí kí ó sún wa láti ní ìrònú ènìyàn dípò ti Ọlọ́run, ní fífi fàájì tàbí ìrísí ti ará sí àyè tí ó ṣe pàtàkì jù.—Fi wé Mátíù 16:21-23.
Sátánì ti pinnu láti pa ipò tẹ̀mí wa run, ẹ̀mí ayé sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ohun ìjà rẹ̀. Rántí pé Èṣù lè yí àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀ pa dà kúrò ní ti kìnnìún tí ń ké ramúramù sí ti ejò tí ó gbọ́n féfé. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1; Pétérù Kíní 5:8) Nígbà míràn, ayé ń ṣẹ́gun Kristẹni kan nípa lílo inúnibíni rírorò, ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà májèlé díẹ̀díẹ̀ ni ó ń fún un jẹ. Pọ́ọ̀lù ṣàníyàn gidigidi nípa ewu tí a mẹ́nu kàn kẹ́yìn yí: “Mo ń fòyà pé lọ́nà kan ṣáá, bí ejò náà ti sún Éfà dẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀, a lè sọ èrò inú yín di ìbàjẹ́ kúrò nínú òtítọ́ inú àti ìwà mímọ́ tí ó tọ́ sí Kristi.”—Kọ́ríńtì Kejì 11:3.
Láti dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ejò náà, ó ṣe pàtàkì pé kí a mọ ìgbékèéyíde tí “ó pilẹ̀ ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé,” kí a sì kọ̀ ọ́ pátápátá. (Jòhánù Kíní 2:16) A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí a tàn wá jẹ láti bẹ̀rẹ̀ sí í rò pé ọ̀nà ìrònú ayé kò léwu. Atẹ́gùn onímájèlé ti ètò ìgbékalẹ̀ Sátánì ti dé ìwọ̀n tí ń bani lẹ́rù.—Éfésù 2:2.
Gbàrà tí a bá ti dá ìrònú ayé mọ̀, a lè kojú rẹ̀ nípa fífi ẹ̀kọ́ mímọ́ gaara ti Jèhófà kún èrò inú àti ọkàn àyà wa. Gẹ́gẹ́ bí Ọba Dáfídì, ẹ jẹ́ kí a sọ pé: “Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, Olúwa; kọ́ mi ní ipa tìrẹ. Sìn mí ní ọ̀nà òtítọ́ rẹ, kí o sì kọ́ mi: nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi.”—Orin Dáfídì 25:4, 5.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti lo àwọn orúkọ àfidípò.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Lílépa ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ lè mú kí a yà bàrá kúrò nínú lílépa àwọn góńgó tẹ̀mí