ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 10/1 ojú ìwé 4-8
  • Mọ Jèhófà—Ọlọ́run Náà Tí Ó Jẹ́ Ẹni Gidi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mọ Jèhófà—Ọlọ́run Náà Tí Ó Jẹ́ Ẹni Gidi
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jèhófà àti Mósè “Ní Ojúkojú”
  • Jèhófà—Ọlọ́run Tí Ó Jẹ́ Gidi sí Èlíjà
  • Ẹ̀mí Mímọ́ Darí Pọ́ọ̀lù
  • Àìgbọlọ́rungbọ́ Kò Dí Ìfẹ́ Tí Jèhófà Ní Nínú Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Lọ́wọ́
  • “Àwọn Aṣiwèrè” àti Ọlọ́run
  • Ìkìlọ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wa Tí Ó Jẹ́ Ẹni Gidi
  • Ó Rí Ìtùnú Gbà Lọ́dọ̀ Ọlọ́run Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìwọ Yóò Ha Jẹ́ Olùṣòtítọ́ Bí Èlíjà Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ọlọ́run Rẹ̀ Tù Ú Nínú
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀rù Máa Ń Bà Ẹ́ Tó O Bá Dá Wà?
    Kọ́ Ọmọ Rẹ
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 10/1 ojú ìwé 4-8

Mọ Jèhófà—Ọlọ́run Náà Tí Ó Jẹ́ Ẹni Gidi

NÍ FÍFI èròǹgbà ẹ̀sìn Híńdù nípa Ọlọ́run wé ti àwọn ẹ̀sìn míràn, Ọ̀mọ̀wé S. Radhakrishnan ti ilẹ̀ Íńdíà sọ pé: “Ọlọ́run àwọn Hébérù yàtọ̀ pátápátá. Òun jẹ́ ẹni gidi kan, a sì ń rí ọwọ́ rẹ̀ nínú ìtàn, ó sì lọ́kàn ìfẹ́ nínú ìyípadà àti èèṣì inú ayé tí ń gòkè àgbà yí. Ó jẹ́ Ẹnì Kan, tí ń bá wa sọ̀rọ̀.”

Orúkọ Ọlọ́run Bíbélì ní èdè Hébérù ni יהוה, tí a sábà máa ń tú sí “Jèhófà.” Ó ga lọ́lá ju gbogbo ọlọ́run yòó kù lọ. Kí ni a mọ̀ nípa rẹ̀? Ọ̀nà wo ni ó gbà bá àwọn ènìyàn lò lákòókò tí a kọ Bíbélì?

Jèhófà àti Mósè “Ní Ojúkojú”

Ipò ìbátan tímọ́tímọ́ “ní ojúkojú” wà láàárín Jèhófà àti ìránṣẹ́ rẹ̀ Mósè, bí Mósè kò tilẹ̀ lè rí Ọlọ́run sójú ní ti gidi. (Diutarónómì 34:10; Ẹ́kísódù 33:20) Nígbà tí ó wà léwe, ọkàn Mósè wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n ń sìnrú ní àkókò náà ní Íjíbítì. Ó kẹ̀yìn sí ìgbésí ayé tí ó ń gbé gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà agbo ilé Fáráò, “ó yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run.” (Hébérù 11:25) Nítorí èyí, Jèhófà fún Mósè ní ọ̀pọ̀ àǹfààní àkànṣe.

Gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà agbo ilé Fáráò, “Mósè ni a fún ní ìtọ́ni nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì.” (Ìṣe 7:22) Ṣùgbọ́n láti jẹ́ aṣáájú fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, òun tún gbọ́dọ̀ mú ànímọ́ ìrẹ̀lẹ̀, sùúrù, àti ìwà tútù dàgbà. Ó ṣe èyí láàárín 40 ọdún tí ó lò gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ní Mídíánì. (Ẹ́kísódù 2:15-22; Númérì 12:3) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ẹni tí a kò lè fojú rí, Jèhófà ṣí ara rẹ̀ àti ète rẹ̀ payá fún Mósè, Ọlọ́run sì fi Òfin Mẹ́wàá lé e lọ́wọ́, nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì. (Ẹ́kísódù 3:1-10; 19:3–20:20; Ìṣe 7:53; Hébérù 11:27) Bíbélì sọ fún wa pé “OLÚWA sì bá Mósè sọ̀rọ̀ ní ojúkojú, bí ènìyàn ti ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀.” (Ẹ́kísódù 33:11) Ní tòótọ́, Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ pé: “Òun ni èmi ń bá sọ̀rọ̀ ní ẹnu ko ẹnu.” Ẹ wo irú ipò ìbátan tímọ́tímọ́, ṣíṣọ̀wọ́n tí Mósè gbádùn pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ ẹni gidi!—Númérì 12:8.

Ní àfikún sí ìtàn àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, Mósè ṣe àkọsílẹ̀ àkójọ Òfin pẹ̀lú gbogbo àbájáde rẹ̀. A tún fi àǹfààní iyebíye kan síkàáwọ́ rẹ̀—ti kíkọ ìwé Jẹ́nẹ́sísì. Àwọn apá tí ó gbẹ̀yìn ìwé náà jẹ́ ìtàn tí ìdílé rẹ̀ mọ̀ dáradára, nítorí náà, ó rọrùn láti kọ wọ́n sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, ibo ni Mósè ti rí kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn ènìyàn ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ gbà? Ó ṣeé ṣe kí Mósè ní àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́, tí àwọn baba ńlá rẹ̀ pa mọ́, tí ó lò gẹ́gẹ́ bí orísun ìsọfúnni. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ó lè ti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ láti inú ìtàn àtẹnudẹ́nu tàbí ní tààràtà nípasẹ̀ ìṣípayá àtọ̀runwá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Tipẹ́tipẹ́ ni àwọn ẹni àbọ̀wọ̀fún lọ́mọdé lágbà ti sọ nípa ipò ìbátan tímọ́tímọ́ tí Mósè gbádùn pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀ nínú ọ̀ràn yí.

Jèhófà—Ọlọ́run Tí Ó Jẹ́ Gidi sí Èlíjà

Wòlíì Èlíjà pẹ̀lú mọ Jèhófà sí Ọlọ́run kan tí ó jẹ́ ẹni gidi. Èlíjà jẹ́ onítara fún ìjọsìn mímọ́ gaara, ó sì sin Jèhófà láìka pé àwọn olùjọ́sìn Báálì, olórí ọlọ́run àwọn ará Kénáánì, kórìíra rẹ̀ gidigidi, tí wọ́n sì ta kò ó sí.—Àwọn Ọba Kìíní 18:17-40.

Áhábù, ọba Ísírẹ́lì, àti aya rẹ̀, Jésíbẹ́lì, wá ọ̀nà láti pa Èlíjà. Nítorí ẹ̀mí rẹ̀, Èlíjà sá lọ sí Bíá-ṣébà, ìwọ̀ oòrùn Òkun Òkú. Níbẹ̀, ó rìn gbéregbère lọ sínú aginjù, ó sì gbàdúrà fún ikú. (Àwọn Ọba Kìíní 19:1-4) Jèhófà ha ti pa Èlíjà tì bí? Òun kò ha lọ́kàn ìfẹ́ nínú ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́ mọ́? Èlíjà lè ti rò bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ wo bí ó ti kùnà tó! Lẹ́yìn náà, Jèhófà bá a sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ní bíbi í pé: “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí, Èlíjà?” Lẹ́yìn fífi agbára tí ó ju ti ẹ̀dá lọ pitú, “ohùn kan tọ̀ ọ́ wá [lẹ́ẹ̀kan sí i] wí pé, ‘Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí Èlíjà?’” Jèhófà fi ìfẹ́ hàn sí Èlíjà gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan láti lè fún ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó ṣeé gbára lé níṣìírí. Ọlọ́run ṣì ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ fún un láti ṣe, kíá sì ni Èlíjà dáhùn ìpè náà! Èlíjà fi òtítọ́ ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún un, ó sọ orúkọ Jèhófà, Ọlọ́run rẹ̀ tí ó jẹ́ ẹni gidi, di mímọ́.—Àwọn Ọba Kìíní 19:9-18.

Lẹ́yìn tí ó kọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀, Jèhófà kò bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé sọ̀rọ̀ ní tààràtà mọ́. Èyí kò túmọ̀ sí pé ìfẹ́ tí ó ní sí wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ti dín kù. Ó ṣì ń darí wọn, ó sì ń fún wọn lókun nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, wo àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ sí Sọ́ọ̀lù.

Ẹ̀mí Mímọ́ Darí Pọ́ọ̀lù

Tásù, ìlú gbígbajúmọ̀ kan ní Sìlíṣíà, ni Sọ́ọ̀lù ti wá. Hébérù ni àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n ọmọ ilẹ̀ Róòmù ni láti ìgbà ìbí rẹ̀. Ṣùgbọ́n, a tọ́ Sọ́ọ̀lù dàgbà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ aláìṣeéyípadà ti àwọn Farisí. Lẹ́yìn náà, ní Jerúsálẹ́mù, ó ní àǹfààní gbígba ẹ̀kọ́ “lẹ́bàá ẹsẹ̀ Gàmálíẹ́lì,” gbajúmọ̀ olùkọ́ Òfin.—Ìṣe 22:3, 26-28.

Nítorí ìtara òdì tí Sọ́ọ̀lù ní fún òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù, ó lọ́wọ́ nínú ìgbétásì oníkà tí a gbé dìde sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi. Ó tilẹ̀ fọwọ́ sí ìṣekúpa Sítéfánù, Kristẹni ajẹ́rìíkú àkọ́kọ́. (Ìṣe 7:58-60; 8:1, 3) Lẹ́yìn náà, ó jẹ́wọ́ pé, bí òun tilẹ̀ jẹ́ asọ̀rọ̀ òdì àti onínúnibíni àti aláfojúdi ènìyàn tẹ́lẹ̀ rí, “a fi àánú hàn sí [òun], nítorí tí [òun] jẹ́ aláìmọ̀kan tí [òun] sì gbé ìgbésẹ̀ pẹ̀lú àìnígbàgbọ́.”—Tímótì Kíní 1:13.

Ojúlówó ìfẹ́ láti sin Ọlọ́run ni ó sún Sọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́. Lẹ́yìn ìyíléròpadà Sọ́ọ̀lù lójú ọ̀nà sí Damásíkù, Jèhófà lò ó lọ́nà lílágbára. Kristi tí a ti jí dìde rán Ananíà, Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn ìjímìjí kan, láti lọ ràn án lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ṣamọ̀nà Pọ́ọ̀lù (orúkọ Sọ́ọ̀lù tí a fi mọ̀ ọ́n lédè Róòmù gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni) láti ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ gígùn, tí ó méso jáde, jákèjádò apá kan Europe àti Éṣíà Kékeré.—Ìṣe 13:2-5; 16:9, 10.

A ha lè dá irú ìdarí ẹ̀mí mímọ́ bẹ́ẹ̀ mọ̀ yàtọ̀ lónìí bí? Bẹ́ẹ̀ ni, a lè ṣe bẹ́ẹ̀.

Àìgbọlọ́rungbọ́ Kò Dí Ìfẹ́ Tí Jèhófà Ní Nínú Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Lọ́wọ́

Joseph F. Rutherford ni ààrẹ kejì Watch Tower Society. Ó ṣe ìrìbọmi ní 1906 gẹ́gẹ́ bí Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì—orúkọ tí a mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà náà—a yàn án sípò olùgba Society nímọ̀ràn nípa òfin ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, ó sì di ààrẹ rẹ̀ ní January 1917. Síbẹ̀, ọ̀dọ́ amòfin yìí ti fìgbà kan jẹ́ aláìgbọlọ́rungbọ́. Báwo ni ó ṣe di Kristẹni ìránṣẹ́ Jèhófà tí a sún ṣiṣẹ́ lọ́nà lílágbára tó bẹ́ẹ̀?

Ní July 1913, Rutherford sìn gẹ́gẹ́ bí alága àpéjọpọ̀ àgbègbè Ẹgbẹ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kárí Ayé, tí a ṣe ní Springfield, Massachusetts, U.S.A. Oníròyìn kan láti ilé iṣẹ́ ìwé agbéròyìnjáde àdúgbò náà, The Homestead, fọ̀rọ̀ wá Rutherford lẹ́nu wò, a sì tẹ ìròyìn náà jáde nínú ìwé pẹlẹbẹ tí ó ròyìn àpéjọpọ̀ náà.

Rutherford ṣàlàyé pé, nígbà tí òun wéwèé láti fẹ́ ìyàwó, ojú ìwòye òun ní ti ìsìn jẹ́ ti ìjọ Baptist, ṣùgbọ́n ti àfẹ́sọ́nà òun jẹ́ ti Presbyterian. Nígbà tí àlùfáà ìjọ Rutherford sọ pé “ọ̀run àpáàdì ni ọmọbìnrin náà ń lọ, nítorí kò tí ì ṣe ìrìbọmi, pé Rutherford ní tirẹ̀ yóò lọ sí ọ̀run tààràtà, nítorí òun ti ṣe bẹ́ẹ̀, ìrònú rẹ̀ tí ó bọ́gbọ́n mu kọ̀ ọ́, ó sì di aláìgbọlọ́rungbọ́.”

Ó gba Rutherford ní ọ̀pọ̀ ọdún ìwádìí jinlẹ̀ láti gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run kan tí ó jẹ́ ẹni gidi ró lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sọ pé, èrò òun ni pé “ohun tí kò bá ti bọ́gbọ́n mu kò gbọ́dọ̀ tẹ́ni lọ́rùn.” Rutherford ṣàlàyé pé, àwọn Kristẹni “gbọ́dọ̀ rí i dájú pé Ìwé Mímọ́ tí wọ́n gbà gbọ́ jẹ́ òtítọ́,” ó fi kún un pé: “Wọ́n gbọ́dọ̀ mọ ìpìlẹ̀ tí wọ́n dúró lé lórí.”—Wo Tímótì Kejì 3:16, 17.

Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe lónìí pàápàá fún aláìgbọlọ́rungbọ́ tàbí onígbàgbọ́ Ọlọ́run-kò-ṣeé-mọ̀ láti wá inú Ìwé Mímọ́, láti gbé ìgbàgbọ́ ró, kí ó sì mú ipò ìbátan tímọ́tímọ́ tí ó lágbára pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run dàgbà. Lẹ́yìn fífarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìrànwọ́ ìtẹ̀jáde Watch Tower náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, ọ̀dọ́kùnrin kan jẹ́wọ́ pé: “N kò gba Ọlọ́run gbọ́ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mo rí i pé ìmọ̀ Bíbélì ti yí ìrònú mi látòkè délẹ̀ pa dà. Mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í mọ Jèhófà báyìí, mo sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́kẹ̀ lé e.”

“Àwọn Aṣiwèrè” àti Ọlọ́run

Ọ̀mọ̀wé James Hastings, nínú A Dictionary of the Bible, sọ pé: “Kò là sọ́kàn èyíkéyìí nínú àwọn òǹkọ̀wé Májẹ̀mú Láéláé [Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù] rí láti fẹ̀rí hàn pé Ọlọ́run ń bẹ, tàbí láti jiyàn nípa rẹ̀. Kì í ṣe àṣà àwọn ènìyàn ìgbà àtijọ́ ní gbogbogbòò láti sẹ́ wíwà Ọlọ́run, tàbí láti lo iyàn láti fẹ̀rí rẹ̀ hàn. Ìgbàgbọ́ náà bá èrò inú ènìyàn mu, ó sì wọ́pọ̀ láàárín gbogbo ènìyàn.” Àmọ́ ṣáá o, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé gbogbo ènìyàn tí ń gbé nígbà yẹn ni ó bẹ̀rù Ọlọ́run. Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Orin Dáfídì 14:1 àti 53:1 (NW) mẹ́nu kan “òpònú,” tàbí gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ King James Version ti sọ, “aṣiwèrè,” tí ó sọ nínú ọkàn àyà rẹ̀ pé, “Jèhófà kò sí.”

Irú ènìyàn wo ni aṣiwèrè yí, ẹni tí ó sẹ́ wíwà Ọlọ́run? Kì í ṣe àìní ọpọlọ ló ń yọ ọ́ lẹ́nu. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ Hébérù náà, na·valʹ, tọ́ka sí àìní ìwà rere. Ọ̀jọ̀gbọ́n S. R. Driver, nínú ìwé rẹ̀ sí The Parallel Psalter, sọ pé ẹ̀bi náà “kì í ṣe àìlèronú dáradára, ṣùgbọ́n ti àìnírònú ní ti ìwà híhù àti ní ti ìsìn, àìní ọpọlọ tàbí òye rárá.”

Onísáàmù náà tẹ̀ síwájú láti ṣàpèjúwe ìwà ìbàjẹ́ tí ó jẹ́ ìyọrísí irú ẹ̀mí ìrònú bẹ́ẹ̀: “Wọ́n bà jẹ́, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìríra, kò sí ẹni tí ń ṣe rere.” (Orin Dáfídì 14:1) Ọ̀mọ̀wé Hastings parí ọ̀rọ̀ náà pé: “Ní ríronú pé Ọlọ́run kò mọ ohun tí ń lọ nínú ayé mọ́ àti pé ohun gbogbo ti di àṣegbé, àwọn ènìyàn ti wá bà jẹ́, wọ́n sì ń ṣe àwọn ohun tí etí kò gbọ́dọ̀ gbọ́.” Wọ́n tẹ́wọ́ gba àwọn ìlànà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, wọ́n sì kọ Ọlọ́run tí ó jẹ́ ẹni gidi, tí wọn kò fẹ́ jíhìn fún, sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, irú ìrònú bẹ́ẹ̀ jẹ́ tí aṣiwèrè àti ti òpònú lónìí, gan-an bí ó ti jẹ́ nígbà tí onísáàmù kọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ohun tí ó lé ní 3,000 ọdún sẹ́yìn.

Ìkìlọ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wa Tí Ó Jẹ́ Ẹni Gidi

Ẹ jẹ́ kí a pa dà nísinsìnyí sí àwọn ìbéèrè tí a gbé dìde nínú àpilẹ̀kọ wa ìṣáájú. Èé ṣe tí kò fi ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ ènìyàn láti so ọ̀ràn Ọlọ́run kan tí ó jẹ́ ẹni gidi pọ̀ mọ́ ìjìyà tí ó kún inú ayé òde òní?

Àwọn ìsọfúnni láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ń “sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn,” ni ó wà nínú Bíbélì. (Pétérù Kejì 1:21) Òun nìkan ṣoṣo ni ó ṣí Ọlọ́run náà tí ó jẹ́ ẹni gidi, Jèhófà, payá fún wa. Ó tún kìlọ̀ fún wa nípa ẹni burúkú kan, tí ènìyàn kò lè fojú rí, tí ó lágbára nínú dídarí àti ṣíṣàkóso ìrònú ènìyàn—Sátánì Èṣù. Lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n ìrònú mu, bí a kò bá gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run kan tí ó jẹ́ ẹni gidi, báwo ni a ṣe lè gbà gbọ́ pé Èṣù, tàbí Sátánì, tí ó jẹ́ ẹni gidi ń bẹ pẹ̀lú?

Lábẹ́ ìmísí, àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì . . . ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9) Lẹ́yìn náà, Jòhánù sọ pé: “Àwa mọ̀ pé a pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (Jòhánù Kíní 5:19) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí gbé àwọn ọ̀rọ̀ Jésù, tí Jòhánù fúnra rẹ̀ kọ sílẹ̀ nínú Ìhìn Rere rẹ̀ jáde pé: “Olùṣàkóso ayé ń bọ̀. Kò sì ní ìdìmú kankan lórí mi.”—Jòhánù 14:30.

Ẹ wo bí ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ yìí ti jìnnà tó sí ohun tí àwọn ènìyàn gbà gbọ́ lónìí! Ìwé agbéròyìnjáde Catholic Herald sọ pé: “Ó ṣe kedere pé sísọ̀rọ̀ nípa Èṣù kò bágbà mu mọ́ lónìí. Ayé ọ̀làjú àti ti onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí a ń gbé ti gbàgbé Sátánì pátápátá.” Síbẹ̀, Jésù fi agbára sọ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n lọ́kàn àtipa á pé: “Láti ọ̀dọ̀ Èṣù bàbá yín ni ẹ ti wá, ẹ sì ń fẹ́ láti ṣe àwọn ìfẹ́-ọkàn baba yín.”—Jòhánù 8:44.

Àlàyé Bíbélì lórí agbára tí Sátánì ní bọ́gbọ́n mu. Ó mú kí ìdí tí ìkórìíra, ogun, àti ìwà ipá tí kò nídìí, bí irú èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní Dunblane (tí a mẹ́nu kàn ní ojú ìwé 3 àti 4), fi kún inú ayé ṣe kedere, láìka ìfẹ́ ọkàn ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn láti gbé ní àlàáfíà àti ìrẹ́pọ̀ sí. Síwájú sí i, kì í ṣe Sátánì nìkan ni ọ̀tá tí a gbọ́dọ̀ gbéjà kò. Bíbélì kìlọ̀ síwájú sí i nípa àwọn ẹ̀mí burúkú, tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù—àwọn ẹ̀mí búburú, tí wọ́n lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Sátánì nígbà pípẹ́ sẹ́yìn, láti ṣi aráyé lọ́nà, kí wọ́n sì ṣe wọ́n níkà. (Júúdà 6) Jésù Kristi dojú kọ agbára àwọn ẹ̀mí wọ̀nyí lọ́pọ̀ ìgbà, ó sì ṣeé ṣe fún un láti borí wọn.—Mátíù 12:22-24; Lúùkù 9:37-43.

Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà, ti pète láti fọ ìwà burúkú mọ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé, kí ó sì fòpin sí ìgbòkègbodò Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Látàrí ìmọ̀ tí a ní nípa Jèhófà, a lè ní ìgbàgbọ́ dídúró gbọn-in àti ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó dájú nínú ìlérí rẹ̀. Ó sọ pé: “A kò mọ Ọlọ́run kan ṣáájú mi, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan kì yóò sì hù lẹ́yìn mi. Èmi, àní èmi ni Olúwa; àti lẹ́yìn mi, kò sí olùgbàlà kan.” Ní tòótọ́, Ọlọ́run kan tí ó jẹ́ ẹni gidi ni Jèhófà jẹ́ fún gbogbo àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́n, tí wọ́n ń jọ́sìn rẹ̀, tí wọ́n sì ń sìn ín. Òun nìkan, àní òun nìkan ṣoṣo, ni a lè yíjú sí fún ìgbàlà wa.—Aísáyà 43:10, 11.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwòrán kan tí a gbẹ́ sára ògiri ní ọ̀rúndún kejìdínlógún tí ń fi bí Mósè ti ń kọ Jẹ́nẹ́sísì 1:1 lábẹ́ ìmísí hàn

[Credit Line]

Láti inú Bíbélì The Holy Bible láti ọwọ́ J. Baskett, Oxford

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Jésù Kristi borí àwọn ẹ̀mí èṣù lọ́pọ̀ ìgbà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́