Ìwọ Ha Lè Gbà Gbọ́ Nínú Ọlọ́run Kan Tí Ó Jẹ́ Ẹni Gidi Bí?
ÀLÙFÁÀ àgbà ní yunifásítì kan ní Britain ṣàlàyé pé: “Kò dìgbà tí o bá gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run kí o tó lè di Kristẹni . . . A jẹ́ apá kan ìyípadà tegbò tigaga kan ní báyìí, ṣùgbọ́n tí ó bá máa fi di ọ̀rúndún kọkànlélógún, ṣọ́ọ̀ṣì kò ní nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run mọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tẹ́lẹ̀.” Ó ń gbẹnu sọ fún àjọ Sea of Faith, tí ó kéré tán ọgọ́rùn-ún àlùfáà ọmọ Britain fọwọ́ sí. “Àwọn Kristẹni aláìgbọlọ́rungbọ́” wọ̀nyí jiyàn pé ìsìn jẹ́ ìṣẹ̀dá ènìyàn, àti pé “èrò orí” lásán ni Ọlọ́run jẹ́, gẹ́gẹ́ bí mẹ́ńbà kan ti sọ ọ́. Ọlọ́run kan tí ó ju ẹ̀dá lọ kò bá ọ̀nà ìrònú wọn mu mọ́.
“Ọlọ́run ti kú” jẹ́ ọ̀rọ̀ apàfiyèsí ní àwọn ọdún 1960. Ó gbé ojú ìwòye ọlọ́gbọ́n èrò orí ọ̀rúndún kọkàndínlógún ará Germany náà, Friedrich Nietzsche, yọ, ó sì fún ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ní àwáwí tí wọ́n ń fẹ́ láti ṣe ohun tí ó wù wọ́n, láti ṣèṣekúṣe, àti láti joògùnyó láìlo ìkóra-ẹni-níjàánu. Ṣùgbọ́n, irú òmìnira bẹ́ẹ̀ ha ṣamọ̀nà àwọn ọ̀dọ́mọdé abẹ́gbẹ́yodì, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ wọ́n sí, sí ìgbésí ayé aláyọ̀ tí ó túbọ̀ tẹ́ni lọ́rùn bí?
Ní ẹ̀wádún kan náà, bíṣọ́ọ̀bù Áńgílíkà náà, John A. T. Robinson, tẹ ìwé rẹ̀ tí ó ru awuyewuye sókè náà, Honest to God, jáde. Ọ̀pọ̀ lára àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe lámèyítọ́ rẹ̀ fún ríronú nípa Ọlọ́run “gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ju apá jíjinlẹ̀ kan nínú ìrírí ènìyàn.” Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìsìn náà, Keith Ward, béèrè pé: “Ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ha ti di ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tí kò bá ìgbà mu mọ́, tí àwọn ọlọgbọ́n ti pa tì nísinsìnyí bí?” Ní dídáhùn ìbéèrè ara rẹ̀, ó sọ pé: “Kò sí ohun tí ó ṣe pàtàkì nínú ìsìn lónìí ju pípadà jèrè ìmọ̀ nípa èrò tí a ní nípa Ọlọ́run tẹ́lẹ̀.”
Ìjìyà àti Ọlọ́run Kan Tí Ó Jẹ́ Ẹni Gidi
Ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ tí ó gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run kan tí ó jẹ́ ẹni gidi láti so ìgbàgbọ́ wọn mọ́ àwọn ọ̀ràn ìbìnújẹ́ àti ìjìyà tí wọ́n ń rí. Fún àpẹẹrẹ, ní March 1996, a yìnbọn pa àwọn ọmọdé 16 àti olùkọ́ wọn ní Dunblane, Scotland. Obìnrin kan tí ìpayà bá sọ pé: “N kò lóye ìfẹ́ inú Ọlọ́run rárá.” A kọ làásìgbò ọ̀ràn ìbìnújẹ́ náà sínú káàdì kan tí a fi pẹ̀lú àwọn òdòdó níwájú ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọdé náà. Gbólóhùn kan ṣoṣo ni ó wà nínú rẹ̀, “ÈÉ ṢE?” Ní dídáhùn, àlùfáà Kàtídírà tí ó wà ní Dunblane sọ pé: “Kò sí àlàyé kankan. A kò lè dáhùn ìdí tí èyí fi ní láti ṣẹlẹ̀.”
Ní ìparí ọdún kan náà, a pa àlùfáà ọ̀dọ́ gbígbajúmọ̀ kan ti Ṣọ́ọ̀ṣì England nípakúpa. Ìwé ìròyìn Church Times ròyìn pé, ìjọ kan tí ẹnu yà gbọ́ tí àlùfáà àgbà Liverpool sọ nípa “lílu ilẹ̀kùn Ọlọ́run gbàgbàgbà léraléra láti béèrè pé èé ṣe? èé ṣe?” Àlùfáà yí pẹ̀lú kò ní ọ̀rọ̀ ìtùnú kankan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kan tí ó jẹ́ ẹni gidi.
Nígbà náà, kí ni ó yẹ kí a gbà gbọ́? Ó bá ọgbọ́n mu láti gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run kan tí ó jẹ́ ẹni gidi. Òun ni ó lè jẹ́ kí a rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pípọn dandan tí a gbé dìde lókè. A ké sí ọ láti gbé àwọn ẹ̀rí tí a gbé kalẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yẹ̀ wò.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Káàdì náà béèrè pé, “Èé ṣe?”
[Credit Line]
NEWSTEAM No. 278468/Sipa Press