ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 9/1 ojú ìwé 4-7
  • Èrè Bíbọlá fún Àwọn Òbí Àgbàlagbà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èrè Bíbọlá fún Àwọn Òbí Àgbàlagbà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fífúnni Nípa ti Ara
  • Fífúnni Ní Ti Ìmọ̀lára
  • Fífúnni Nípa Tẹ̀mí
  • Ìwà Rere Máa Ń Fa Àwọn Ènìyàn Súnmọ́ Ọlọ́run
  • Bíbọlá fún Àwọn Òbí Wa Àgbàlagbà
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí N Sún Mọ́ Àwọn Òbí Mi Àgbà?
    Jí!—2001
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Lájọṣe Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Àwọn Òbí Mi Àgbà?
    Jí!—2001
  • Bíbójútó Àwọn Àgbàlagbà—Ojúṣe Àwọn Kristẹni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 9/1 ojú ìwé 4-7

Èrè Bíbọlá fún Àwọn Òbí Àgbàlagbà

ÀWỌN ojúlówó olùjọsìn Ọlọ́run ń bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wọn àgbàlagbà, wọ́n ń bọlá fún wọn, wọ́n sì ń ṣètọ́jú wọn, nítorí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn. Apá kan ìjọsìn wọn ni. Bíbélì sọ pé: “Kí [àwọn ọmọ tàbí àwọn ọmọ ọmọ] kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ láti máa fi ìfọkànsin Ọlọ́run ṣèwàhù nínú agbo ilé tiwọn kí wọ́n sì máa san ìsanfidípò yíyẹ fún àwọn òbí wọn àti àwọn òbí wọn àgbà, nítorí tí èyí ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run.” (Tímótì Kíní 5:4) Yálà a jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà, ó bójú mu pé kí a san “ìsanfidípò yíyẹ” fún àwọn òbí wa àti àwọn òbí wa àgbà. Ní ọ̀nà yí, a ń fi ìmọrírì hàn fún ìfẹ́, iṣẹ́ àṣekára, àti títọ́jú tí wọ́n tọ́jú wa fún ọ̀pọ̀ ọdún. Họ́wù, a jẹ àwọn òbí wa ní gbèsè ìwàláàyè wa gan-an!

Kíyè sí i pé sísan ìsanfidípò yíyẹ fún àwọn òbí àti àwọn òbí àgbà “ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run.” A so ó mọ́ “ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run” tí a ní. Nípa bẹ́ẹ̀, a ń san èrè fún wa nípa ṣíṣe ohun tí ìmọ̀ràn yí sọ, ní mímọ̀ pé a ń ṣe ohun tí ó wu Ọlọ́run. Èyí ń mú wa láyọ̀.

Ayọ̀ ń bẹ nínú fífún àwọn ẹlòmíràn ní nǹkan, pàápàá bí a bá fún àwọn tí wọ́n ti fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀. (Ìṣe 20:35) Nígbà náà, ẹ wo irú èrè tí ó wà nínú gbígbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Bíbélì náà pé: “Fún bàbá àti ìyá rẹ ní ìdí láti dunnú, jẹ́ kí ẹni tí ó bí ọ yọ̀”!—Òwe 23:25, The New English Bible.

Báwo ni a ṣe lè san ìsanfidípò yíyẹ fún àwọn òbí wa àti àwọn òbí wa àgbà? Ní ọ̀nà mẹ́ta: nípa ti ara, ní ti ìmọ̀lára, àti nípa tẹ̀mí. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń mú èrè tirẹ̀ wá.

Fífúnni Nípa ti Ara

Àwọn tí ń jọ́sìn Ọlọ́run mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì láti pèsè nípa ti ara fún àwọn mẹ́ńbà ìdílé tí ó sún mọ́ wọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbani níyànjú pé: “Bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn wọnnì tí wọ̀n jẹ́ tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, òun ti sẹ́ níní ìgbàgbọ́ ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.”—Tímótì Kíní 5:8.

Túnjí àti Joy ń gbé ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Bí nǹkan kò tilẹ̀ dán mọ́rán fún wọn nípa ti ara, wọ́n ké sí àwọn òbí Joy tí wọ́n ti dàgbà láti wá gbé pẹ̀lú wọn. Bàbá náà ṣàìsàn, ó sì kú lẹ́yìn-ọ̀-rẹ́yìn. Túnjí rántí pé: “Nígbà tí Bàbá kú, Màmá fọwọ́ gbá ìyàwó mi mọ́ra, ó sì sọ pé: ‘O ṣe gbogbo ohun tí ènìyàn lè ṣe. Kò sí ìdí fún ọ láti dá ara rẹ lẹ́bi nítorí ikú Bàbá.’ Bí a tilẹ̀ ń ṣàárò Bàbá, a mọ̀ pé a ra oògùn tí ó dára jù lọ fún un, a sì máa ń gbìyànjú nígbà gbogbo láti jẹ́ kí ó nímọ̀lára pé a fẹ́ ẹ, àti pé ó wúlò fún wa; a ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti ṣe ojúṣe tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́. Ìtẹ́lọ́rùn yẹn ń bẹ níbẹ̀.”

Àmọ́ ṣáá o, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ní ó wà nípò láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípa ti ara. Ọkùnrin kan tí ń gbé ní Nàìjíríà sọ pé: “Bí ọkùnrin kan kò bá lè gbọ́ bùkátà ara rẹ̀, báwo ni yóò ṣe gbọ́ bùkátà ẹlòmíràn?” Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn ipò nǹkan tilẹ̀ lè burú sí i ní àwọn ọdún tí ń bọ̀. Gẹ́gẹ́ bí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀, ìdajì àwọn olùgbé gúúsù Sàhárà Áfíríkà yóò máa gbé nínú òṣì paraku láìpẹ́.

Bí o bá bá ara rẹ nínú ìṣòro ipò ìṣúnná owó, o lè rí ìtùnú gbà láti inú ìtàn ìgbésí ayé opó aláìní kan. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó kíyè sí i bí opó kan ṣe ń ṣe ìtọrẹ kékeré sínú ìṣúra tẹ́ńpìlì. Ó sọ ìwọ̀nba “ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọ́n kéré gan-an” sínú àpótí ìṣúra. Síbẹ̀, ní mímọ ipò rẹ̀, Jésù sọ pé: “Lótìítọ́ ni mo sọ fún yín, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé opó yìí jẹ́ òtòṣì, ó sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ. Nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí sọ ẹ̀bùn sílẹ̀ láti inú àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n obìnrin yìí láti inú àìní rẹ̀ sọ gbogbo àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé tí ó ní sínú rẹ̀.”—Lúùkù 21:1-4.

Bákan náà, bí a bá ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe ní títọ́jú àwọn òbí wa tàbí àwọn òbí wa àgbà nípa ti ara, bí ó tilẹ̀ kéré, Jèhófà ń kíyè sí i, ó sì mọrírì rẹ̀. Kò retí pé kí a ṣe ju bí agbára wa ṣe mọ lọ. Ó ṣeé ṣe kí àwọn òbí wa tàbí àwọn òbí wa àgbà nímọ̀lára lọ́nà kan náà.

Fífúnni Ní Ti Ìmọ̀lára

Pípèsè fún àwọn òbí wa àti àwọn òbí wa àgbà ní nínú ju bíbójú tó àwọn àìní wọn nípa ti ara lọ. Gbogbo wa pátá ni ó ní àìní ní ti ìmọ̀lára. Gbogbo ènìyàn, títí kan àwọn àgbàlagbà, fẹ́ pé kí a nífẹ̀ẹ́ àwọn, pé kí àwọn nímọ̀lára pé àwọn wúlò, pé a fẹ́ àwọn, pé àwọn sì jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé tí a mọyì.

Mary, tí ń gbé ní Kẹ́ńyà, ti ń ṣètọ́jú ìyá ọkọ rẹ̀ àgbàlagbà fún ọdún mẹ́ta. Mary sọ pé: “Yàtọ̀ sí pípèsè fún àwọn àìní rẹ̀ nípa ti ara, a máa ń bá a sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo. Màmá kò lè ṣe púpọ̀ nínú ilé, ṣùgbọ́n a máa ń sọ̀rọ̀, a sì ti di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Nígbà míràn a máa ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, nígbà míràn nípa àwọn ará wa nílé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ní ẹni 90 ọdún, agbára ìrántí rẹ̀ ṣì jí pépé. Ó ń rántí, ó sì máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbésí ayé nígbà tí ó wà ní ọ̀dọ́mọdébìnrin, ṣáájú ọdún 1914.”

Mary ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Kò rọrùn láti tọ́jú àgbàlagbà, ṣùgbọ́n níní in lọ́dọ̀ wa ti mú èrè jìngbìnnì wá. A ń gbádùn àlàáfíà àti ìṣọ̀kan nínú ìdílé wa. Fífún tí mo ń fún un ti ru ẹ̀mí fífúnni sókè nínú àwọn mẹ́ńbà míràn nínú ìdílé wa. Ọ̀wọ̀ tí ọkọ mi ní fún mi túbọ̀ ga sí i. Bí Màmá bá sì gbọ́ tí ẹnì kan ń sọ̀rọ̀ líle sí mi, kíá ni yóò gbèjà mi. Kò sí ẹni tí ó lè sọ̀rọ̀ líle sí mi níbi tí ó bá wà!”

Fífúnni Nípa Tẹ̀mí

Gan-an gẹ́gẹ́ bí fífúnni nípa ti ara àti ní ti ìmọ̀lára ti ń mú èrè wá fún ẹni tí ń fúnni, bẹ́ẹ̀ náà ni nǹkan rí ní ti ọ̀ràn tẹ̀mí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ní Róòmù pé: “Aáyun ń yun mí láti rí yín, kí n lè fi ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀ fún yín kí a lè fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in; tàbí, kí a kúkú wí pé, kí pàṣípààrọ̀ ìṣírí lè wà láàárín yín, láti ọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnì kejì, tiyín àti tèmi.”—Róòmù 1:11, 12.

Ní ọ̀nà kan náà, ní ti pípèsè nípa tẹ̀mí fún àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ń sin Ọlọ́run, tọ̀túntòsì ni a sábà máa ń fún níṣìírí. Osondu, tí ó ń gbé ní Nàìjíríà, ròyìn pé: “Ohun tí mo lọ́kàn ìfẹ́ sí jù lọ nípa àwọn òbí mi àgbà ni pé, wọ́n fún mi láǹfààní láti mọ díẹ̀ nípa àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ayé àtijọ́. Bàbá bàbá mi, pẹ̀lú ayọ̀ tí ó hàn gbangba lójú rẹ̀, máa ń sọ nípa ìpínlẹ̀ tí ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ní àwọn ọdún 1950 àti 1960. Ó fi bí a ṣe ṣètò ìjọ lónìí wé bí ó ti wà nígbà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Ẹlẹ́rìí. Àwọn ìrírí wọ̀nyí ràn mi lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn mi gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà.”

Àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ Kristẹni pẹ̀lú lè ṣèrànwọ́ nínú fífún àwọn àgbàlagbà ní nǹkan. Túnjí, tí a mẹ́nu kàn níṣàájú, sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ìjọ rẹ̀: “Ọ̀dọ́kùnrin aṣáájú ọ̀nà kan tí a yan àsọyé fún gbogbo ènìyàn fún, mú ìlapa èrò náà tọ Bàbá wá, kí àwọn méjèèjì baà lè múra rẹ̀ pa pọ̀. Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ wá sọ́dọ̀ Bàbá, ó sì wí fún un pé: ‘Onírìírí ènìyàn ni yín. Kí ni ìmọ̀ràn tí ẹ ní fún mi, kí n lè ṣe dáradára sí i.’ Ó ṣeé ṣe fún Bàbá láti fún alàgbà náà ní ìmọ̀ràn tí ó múná dóko. Àwọn arákùnrin dárúkọ Bàbá nínú àdúrà nínú ìjọ lọ́pọ̀ ìgbà. Gbogbo ìwọ̀nyí mú kí ó nímọ̀lára pé a fẹ́ òun.”

Ìwà Rere Máa Ń Fa Àwọn Ènìyàn Súnmọ́ Ọlọ́run

Nígbà míràn, bí a ti ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn òbí wa àti àwọn òbí wa àgbà, tí a sì ń nífẹ̀ẹ́ wọn, a ń fa àwọn ènìyàn súnmọ́ Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé, nínú ohun náà tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín gẹ́gẹ́ bí aṣebi, kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà èyí tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí rẹ̀ yin Ọlọ́run lógo.”—Pétérù Kíní 2:12.

Andrew, Kristẹni alàgbà kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, rìrìn àjò kìlómítà 95 lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ láti lọ tọ́jú bàbá rẹ̀ tí ń ṣàìsàn, tí kì í ṣe onígbàgbọ́. Ó ròyìn pé: “Nígbà tí mo di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bàbá mi ṣàtakò púpọ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó kíyè sí i bí mo ṣe ń ṣe ìtọ́jú òun nígbà tí òun ń ṣàìsàn, ó bẹ̀rẹ̀ sí i rọ àwọn àbúrò mi pé, ‘Ẹ ní láti dara pọ̀ mọ́ ìsìn ẹ̀gbọ́n yín!’ Ìyẹn ru wọ́n lọ́kàn sókè, nísinsìnyí, gbogbo àwọn ọmọ mẹ́sẹ̀ẹ̀sán tí bàbá mi bí ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

Bíbọlá fún àwọn òbí wa àgbàlagbà àti ṣíṣe ìtọ́jú wọn lè jẹ́ ìpèníjà, pàápàá ní àkókò ọrọ̀ ajé líle koko. Ṣùgbọ́n bí àwọn Kristẹni ti ń làkàkà láti ṣe èyí, wọ́n ń rí èrè púpọ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, wọ́n ń gbádùn ìdùnnú fífúnni àti ìtẹ́lọ́rùn mímọ̀ pé wọ́n ń ṣe ohun tí ó wu Jèhófà Ọlọ́run, tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ “Bàbá gbogbo ènìyàn.”—Éfésù 4:6.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Ìmọ̀ràn Oníwà-bí-Ọlọ́run fún Àwọn Tí Ń Gba Ìtọ́jú àti fún Àwọn Tí Ń Fi Fúnni

Jẹ́ Ẹni Tí Ń Fúnni Níṣìírí: “Kí olúkúlùkù wa máa ṣe bí ó ti wu aládùúgbò rẹ̀ nínú ohun rere fún ìgbéniró rẹ̀.”—Róòmù 15:2.

Jẹ́ Ẹni Tí Ó Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.”—Gálátíà 6:9.

Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀: “Láìṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.”—Fílípì 2:3.

Jẹ́ Oníwàrere: “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá ire àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.”—Kọ́ríńtì Kíní 10:24.

Jẹ́ Afòyebánilò: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.”—Fílípì 4:5.

Jẹ́ Oníyọ̀ọ́nú: “Kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kíní kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín lẹ́nì kíní kejì fàlàlà.”—Éfésù 4:32.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn alàgbà tí kò dàgbà púpọ̀ lè jèrè láti inú ìrírí àwọn tí ó dàgbà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́