ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 9/1 ojú ìwé 3
  • Nǹkan Kò Fara Rọ fún Àwọn Àgbàlagbà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nǹkan Kò Fara Rọ fún Àwọn Àgbàlagbà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìdílé Kristian Ń Ran Àwọn Àgbàlagbà Lọ́wọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Bíbójútó Àwọn Àgbàlagbà—Ojúṣe Àwọn Kristẹni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Hùwà Sí Àwọn Àgbàlagbà?
    Jí!—2004
  • Bíbọlá fún Àwọn Òbí Wa Àgbàlagbà
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 9/1 ojú ìwé 3

Nǹkan Kò Fara Rọ fún Àwọn Àgbàlagbà

MÀMÁ ONÍYÁN, tí ó jẹ́ ẹni ọdún 68, ń gbé ní ìlú ńlá kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Nígbà tí ó ṣì wà ní sisí, ó ronú gbígbádùn ọjọ́ ogbó rẹ̀ ní pẹ̀lẹ́tù lẹ́yìn ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́, tí àwọn ọmọ àti ọmọ ọmọ rẹ̀ yóò sì rọ̀gbà yí i ká. Dípò èyí, ó ń fi ọjọ́ ogbó rẹ̀ ta omi tútù nínú oòrùn tí ń mú hanhan. Ìwọ̀nba owó tí ń wọlé fún un ló fi ń tọ́jú ara rẹ̀. Orílẹ̀-èdè kan tí ó jìnnà réré ni àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì ń gbé. Ó ti pẹ́ tí wọ́n fowó ránṣẹ́ sí i kẹ́yìn.

Ní ìgbà àtijọ́, a mọyì àwọn àgbà gidigidi ní Áfíríkà. A ń bọ̀wọ̀ fún wọn fún ìrírí àti ìmọ̀ tí wọ́n ní, pa pọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ tí ìwọ̀nyí máa ń mú wá. Wọ́n máa ń ṣèrànwọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ ọmọ dàgbà. Àwọn ọ̀dọ́ máa ń wá ìmọ̀ràn àti ìtẹ́wọ́gbà wọn. Àwọn ènìyàn máa ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Bíbélì tí ó sọ pé: “Kí ìwọ kí ó sì dìde dúró níwájú orí ewú, kí o sì bọ̀wọ̀ fún ojú arúgbó.”—Léfítíkù 19:32.

Àkókò ti yí pa dà. Òṣì, ọ̀wọ́n gógó ọjà, àìríṣẹ́ṣe, àti ṣíṣí tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń ṣí lọ sí àwọn ìlú ńláńlá tí sọ àwọn àgbàlagbà di ẹni tí ń gbọ́ bùkátà ara wọn. Olùdarí Ètò Ìrànlọ́wọ́ Arúgbó ní Kẹ́ńyà, Camillus Were, sọ pé: “Àṣà ṣíṣètìlẹ́yìn fún àwọn arúgbó àti títọ́jú wọn ti ń kásẹ̀ nílẹ̀.”

Dájúdájú, kì í ṣe ní àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà nìkan ni ìdè ìdílé kò ti lágbára mọ́. Ní sísọ̀rọ̀ nípa Japan, ìwé agbéròyìnjáde Guardian Weekly sọ pé: “Fífara ẹni jìn fún òbí ẹni fìgbà kan jẹ́ òpómúléró ètò ìlànà àwọn ará Japan tí ẹ̀sìn Confucius ta látaré, ṣùgbọ́n ó ti pòórá bí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ní àwọn ìlú ńláńlá, tí ìdè ìdílé sì túbọ̀ ń dẹ̀ sí i: lónìí, ìpín 85 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ Japan ní ń kú sí ilé ìwòsàn tàbí sí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó.”

Ohun yòó wù kí ipò náà jẹ́, àwọn tí wọ́n fẹ́ láti wu Ọlọ́run lójú méjèèjì ń làkàkà láti bọlá fún àwọn òbí wọn. Wọ́n ń kọbi ara sí ìmọ̀ràn Bíbélì tí ó sọ pé: “Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ . . . kí nǹkan lè lọ dáadáa fún ọ kí ìwọ sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀ ayé.” (Éfésù 6:2, 3) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti bọlá fún àwọn òbí àgbàlagbà, kí a sì tọ́jú wọn, ó lè mú èrè jìngbìnnì wá.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́