ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 5/15 ojú ìwé 22-25
  • Bí A Ṣe Lè Rí Ìrètí Nínú Àìsírètí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí A Ṣe Lè Rí Ìrètí Nínú Àìsírètí
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrètí Láìka Onírúurú Àdánwò Sí
  • Ohun Rere Kankan Ha Lè Ti Inú Àdánwò Wá Bí?
  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
  • “Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Láìfi Àdánwò Pè, Rọ̀ Mọ́ Ìgbàgbọ́ Rẹ!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Jóòbù Jẹ́ Oníwà Títọ́ ó Sì Ní Ìfaradà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Irú Ojú Wo Ló Yẹ Ká Máa Fi Wo Àdánwò?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 5/15 ojú ìwé 22-25

Bí A Ṣe Lè Rí Ìrètí Nínú Àìsírètí

FINÚ wòye pé o ní ìrírí tí ó tẹ̀ lé e yìí: Gbogbo ohun ìní rẹ pa run, o di òtòṣì pátápátá. Àwọn ọmọ rẹ—ìdùnnú ayé rẹ—kò sí mọ́. Alábàáṣègbéyàwó rẹ kò fún ọ níṣìírí kankan. O kò ní Ìlera tí ó jí pépé mọ́. Ọjọ́ kọ̀ọ̀kan kún fún ìrora agbonijìgì.

Bí ó bá jẹ́ ipò ìgbésí ayé rẹ nìyẹn, ìwọ yóò ha rí ìdí láti máa bá ìgbésí ayé lọ bí? Àbí ìwọ yóò sọ ìrètí nù?

Àgbákò burúkú tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ júwe tán jẹ́ ìtàn ìgbésí ayé Jóòbù, ọkùnrin kan tí ó gbáyé ní àkókò tí a kọ Bíbélì. (Jóòbù, orí 1, 2) Nígbà tí ó sorí kọ́ gidigidi, Jóòbù kédàárò pé: “Dájúdájú, ọkàn mi kórìíra ìgbésí ayé mi tẹ̀gbintẹ̀gbin.” Ká ní ikú lè pa á ni, ì bá ti tẹ́ ẹ lọ́rùn jù. (Jóòbù 10:1, NW; 14:13) Ṣùgbọ́n, láìka ìyà ńlá tí ó ń jẹ sí, Jóòbù pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ sí Ọlọ́run. Nítorí náà, Jèhófà “bù kún ìgbẹ̀yìn Jóòbù ju ìṣáájú rẹ̀ lọ.” Nípa bẹ́ẹ̀, ó kú wọ́ọ́rọ́, “ó gbó, ó sì kún fún ọjọ́.”—Jóòbù 42:12, 17.

Jóòbù fi àpẹẹrẹ ìfaradà, tí a ṣì ń kan sáárá sí títí di òní, lẹ́lẹ̀. Àdánwò rẹ̀ mú àkópọ̀ ìwà rẹ̀ sunwọ̀n sí i, ó sì sún àwọn ẹlòmíràn sí iṣẹ́ rere. (Jákọ́bù 5:10, 11) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìwà títọ́ Jóòbù, tí kò lábùkù, mú inú Jèhófà dùn. (Òwe 27:11) Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe wá jẹ́ pé, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ìrora tí ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni wá di ìṣẹ́gun ńlá fún ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, àti ìwà títọ́, tí ó mú ìbùkún wá fún Jóòbù àti gbogbo àwọn tí àpẹẹrẹ rẹ̀ ti sún ṣiṣẹ́.

Ìrètí Láìka Onírúurú Àdánwò Sí

Irú àdánwò tí ó dé bá Jóòbù lè dé bá ọ. Pípàdánù olólùfẹ́ kan lè ti dà ọ́ lọ́kàn rú. Àìsàn burúkú lè ti mú kí ìgbésí ayé rẹ kún fún ìrora agbonijìgì. Gbogbo ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ lè ti dà bí ẹni pé ó ti dà rú, nítorí ìkọ̀sílẹ̀ tí ó fa ìrora ọkàn. Ìjórẹ̀yìn ọrọ̀ ajé lè ti sọ ọ́ di òtòṣì. Àwọn aṣòdì sí ìjọsìn tòótọ́ lè máa ṣe inúnibíni gbígbóná janjan sí ọ. Ìjàkadì láti kojú àwọn àdánwò tí ó dé bá ọ lè ti mú kí o ronú pé o kò nírètí fún ọjọ́ ọ̀la.—Pétérù Kíní 1:6.

Dípò sísọ ìrètí nù, bi ara rẹ pé, ‘Èé ṣe tí mo fi ń jìyà?’ O ń jìyà nítorí pé o ń gbé nínú ayé tí ó “wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” Sátánì Èṣù. (Jòhánù 5:19) Nítorí èyí, gbogbo ènìyàn ni ó ń jìyà. Ìkórìíra tí Èṣù mí sí nítorí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà, ọ̀rọ̀ tí kò fi ìfẹ́ hàn tí àwọn ẹlòmíràn ń sọ, tàbí ìwà burúkú bùrùjà aláìwà-bí-Ọlọ́run tí ó wọ́pọ̀ ní “àwọn àkókò lílekoko” wọ̀nyí, ń nípa lórí gbogbo wa, ní ọ̀nà kan ṣáá.—Tímótì Kejì 3:1-5.

Bí ohun ìbànújẹ́ kan bá ti ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ, ó lè ti jẹ́ nítorí “ìgbà àti èṣì.” (Oníwàásù 9:11) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn nǹkan máa ń yíwọ́ nínú ìgbésí ayé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí àwa fúnra wá ti jogún bá. (Róòmù 5:12) Bí o bá tilẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀ tí ó wúwo gidigidi, ṣùgbọ́n tí o ti ronú pìwà dà, tí o sì ti wá ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, má ṣe rò pé Ọlọ́run ti pa ọ́ tì. (Orin Dáfídì 103:10-14; Jákọ́bù 5:13-15) Ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ, ó bìkítà nípa wa. (Pétérù Kíní 5:6, 7) Jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé, “Olúwa ń bẹ létí ọ̀dọ̀ àwọn tí í ṣe oníròbìnújẹ́ ọkàn; ó sì gba irú àwọn tí í ṣe onírora ọkàn là.” (Orin Dáfídì 34:18) Láìka bí àdánwò rẹ ṣe lè burú tó tàbí bí ó ṣe lè le koko tó sí, Jèhófà lè fún ọ ní ọgbọ́n láti kojú rẹ̀. (Jákọ́bù 1:5-8) Má ṣe gbàgbé láé pé Jèhófà lè wo gbogbo ọgbẹ́ san. Nígbà tí o bá rí ojú rere rẹ̀, kò sí ohun tí ó lè dí ọ lọ́wọ́ láti jèrè ẹ̀bùn ìyè.—Róòmù 8:38, 39.

Ohun Rere Kankan Ha Lè Ti Inú Àdánwò Wá Bí?

Òwe àwọn àgbà kan sọ pé, “Kì í burú burú kí ó má ku ẹnì kan mọ́ni.” Ọ̀nà rírọrùn kan nìyẹn láti sọ pé kò sí bí nǹkan ṣe lè burú tó, tí ìwọ kò ní rí ìdí kan láti nírètí. Ète gbogbo ohun tí a kọ sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni “kí àwa lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Láìka bí ipò rẹ ti lè burú tó, àwọn ìlérí àti ìlànà inú Bíbélì lè mú kí o ní àkọ̀tun ìdùnnú àti ìrètí.

Ìwé Mímọ́ fi hàn pé, ‘ìpọ́njú jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, ó sì fúyẹ́,’ nígbà tí a bá fi wé àwọn ìbùkún ayérayé tí a gbé ka iwájú àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. (Kọ́ríńtì Kejì 4:16-18) Bíbélì tún fi hàn pé àwọn ànímọ́ oníwà-bí-Ọlọ́run, tí a mú dàgbà nígbà tí a ń dán wa wò, ṣe pàtàkì gan-an ju òkìkí tàbí ọrọ̀ ti ara lọ. (Jòhánù Kíní 2:15-17) Nítorí náà, ìjìyà pàápàá lè ṣeni láǹfààní. (Hébérù 5:8) Ní tòótọ́, lílo ohun tí o kọ́ nígbà tí a dán ọ wò lè mú àwọn ìbùkún tí o kò retí wá.

Àdánwò lílekoko lè mú kí o túbọ̀ jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́. O lè gbà pé, tẹ́lẹ̀ rí, o ní àkópọ̀ ìwà tí ó máa ń mú àwọn ẹlòmíràn bínú, tí ó tilẹ̀ ṣèdíwọ́ fún ìtẹ̀síwájú rẹ nípa tẹ̀mí. Bóyá, dídára ẹni lójú ju bí ó ti yẹ lọ ni. Lẹ́yìn tí àjálù kan dé bá ọ, o lè wá mọ̀ lójijì bí o ṣe jẹ́ aláìlera tó, àti bí o ṣe nílò àwọn ẹlòmíràn tó. Bí àdánwò tí o kó sí bá ti kọ́ ọ ní irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀, tí o sì ti ṣe àtúnṣe tí ó yẹ, ó ti ṣe ọ́ láǹfààní nìyẹn.

Bí ó bá ṣòro fún àwọn ẹlòmíràn, tẹ́lẹ̀ rí, láti bá ọ lò nítorí pé o máa ń tètè bínú ńkọ́? Èyí tilẹ̀ lè ti ṣàkóbá fún ìlera rẹ. (Òwe 14:29, 30) Ṣùgbọ́n, nísinsìnyí, ipò nǹkan lè ti sunwọ̀n sí i gan-an nítorí pé o ń gbára lé ẹ̀mí Ọlọ́run láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lo ìkóra-ẹni-níjàánu.—Gálátíà 5:22, 23.

Bí àwọn ẹlòmíràn, ó ṣeé ṣe kí ìwọ pẹ̀lú, ní àwọn ìgbà kan, ṣaláìní ìyọ́nú láti fi àánú hàn fún àwọn tí ó ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n, bí ìwọ fúnra rẹ bá bá ara rẹ nínú ipò kan tí o ti nílò àánú gidigidi, ó ṣeé ṣe kí o tètè máa fi àánú hàn sí àwọn ẹlòmíràn nísinsìnyí. Ìbákẹ́dùn, àníyàn, àti àánú àmọ́kànyọ̀ tí a fi hàn sí ọ, ti mú kí o mọ̀ pé ó yẹ kí o fi ànímọ́ kan náà hàn sí àwọn oníwà àìtọ́ tí wọ́n ronú pìwà dà. Bí ìrora tí o jẹ bá ti mú kí o ṣàtúnṣe àwọn àìlera wọ̀nyí nínú àkópọ̀ ìwà rẹ, èyí jẹ́ àǹfààní kan tí ó ti jẹ láti inú ìrírí rẹ. O ti kẹ́kọ̀ọ́ pé, “àánú a máa yọ ayọ̀ àṣeyọrí lọ́nà ìṣẹ́gun lórí ìdájọ́.”—Jákọ́bù 2:13; Mátíù 5:7.

Bí bíbá tí ìjọ Kristẹni bá ọ wí bá ti ná ọ ní àwọn àǹfààní ẹrù iṣẹ́ tí o ṣìkẹ́, àti ọ̀wọ̀ àwọn ẹlòmíràn ńkọ́? Má ṣe sọ ìrètí nù. Ìgbésẹ̀ tí a fi báni wí ń ṣèrànwọ́ láti pa ìjọ mọ́ ní mímọ́, ṣùgbọ́n mímú oníwà àìtọ́ náà pa dà bọ̀ sípò nípa tẹ̀mí wà lára ète rẹ̀. A gbà pé, “kò sí ìbáwí tí ó dà bí [ohun ìdùnnú] nísinsìnyí, bí kò ṣe akó ẹ̀dùn ọkàn báni; síbẹ̀ nígbà tí ó bá yá fún àwọn wọnnì tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀ a máa so èso ẹlẹ́mìí-àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.” (Hébérù 12:11) Bí ìbáwí tilẹ̀ lè jẹ́ àjálù tí ń bani lọ́kàn jẹ́, kì í fi onírẹ̀lẹ̀ tí ó ronú pìwà dà sílẹ̀ láìnírètí. A bá Dáfídì, Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì, wí gidigidi nítorí ìwà àìtọ́, ṣùgbọ́n, ó ronú pìwà dà nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó sì gba oríyìn àkànṣe gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ìgbàgbọ́ kíkàmàmà.—Sámúẹ́lì Kejì 12:7-12; Orin Dáfídì 32:5; Hébérù 11:32-34.

Àdánwò lè ní ipa lílágbára lórí ojú ìwòye rẹ. Tẹ́lẹ̀ rí, o lè ti kó àfiyèsí rẹ jọ sórí àwọn góńgó onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì àti àwọn àṣeyọrí tí ó mú kí o gbajúmọ̀, tí ó sì sọ ọ́ di ènìyàn pàtàkì láwùjọ. Ó ṣeé ṣe kí àdánwò kan, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìjórẹ̀yìn nínú ìṣúnná owó tàbí àdánù ohun ìní, ti mú kí o pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù. (Fi wé Fílípì 1:10.) Nísinsìnyí, o ti wá mọ̀ pé àwọn ìlànà àti góńgó tẹ̀mí nínú iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ ni kìkì ohun tí ń mú ayọ̀ tòótọ́ àti ìtẹ́lọ́rùn pípẹ́ títí wá.

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

Ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Jèhófà lè yọrí sí inúnibíni àti ìjìyà láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ó ta ko ìgbàgbọ́ Kristẹni rẹ. O lè sorí kọ́ nítorí àdánwò yí, ṣùgbọ́n, rere lè ti inú rẹ̀ wá. Àdánwò yí lè fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun. Ní àfikún sí i, àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ń fojú gbiná inúnibíni lè rí ìṣírí àti okun gbà nípa kíkíyèsí ìforítì rẹ. A lè sún àwọn tí ń fojú rí ìwà àtàtà rẹ láti yin Ọlọ́run lógo. Ojú lè ti àwọn alátakò rẹ pàápàá, kí wọ́n sì jẹ́wọ́ àwọn iṣẹ́ àtàtà rẹ!—Pétérù Kíní 2:12; 3:16.

Kí o má baà sọ ìrètí nù nígbà tí a bá ń ṣenúnibíni sí ọ, o ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi hàn pé ìtura kúrò lọ́wọ́ àdánwò yóò wá dájúdájú, ṣùgbọ́n, ó lè má tètè dé bí ìwọ ṣe ń fẹ́ kí ó tètè dé. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, “má ṣe juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́.” (Tẹsalóníkà Kejì 3:13) Máa bá a nìṣó ní wíwá àwọn ọ̀nà tí o lè gbà kojú àdánwò tí o sì lè gbà fara dà á. Àní nígbà tí àwọn nǹkan bá dà bí èyí tí kò sí ìrètí pàápàá, “kó ẹrù rẹ lọ sára Olúwa, òun ni yóò sì mú ọ dúró: òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ olódodo kí ó yẹ̀ láé.” (Orin Dáfídì 55:22) Dípò jíjẹ́ kí àánú ara rẹ ṣe ọ́ ju bí ó ṣe yẹ lọ, ronú nípa bí o ṣe jẹ́ alábùkún tó láti mọ Jèhófà, láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ènìyàn rẹ̀, àti láti ní ìrètí ìyè tí kò lópin.—Jòhánù 3:16, 36.

Pa ọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun ṣíṣe kókó. Tọ Jèhófà lọ lójoojúmọ́ nínú àdúrà, ní bíbéèrè fún okun àti ìfaradà. (Fílípì 4:6, 7, 13) Mú èrò èyíkéyìí láti gbẹ̀san lára àwọn tí ó fa ìjìyà rẹ kúrò lọ́kàn. Fi ọ̀ràn lé Jèhófà lọ́wọ́. (Róòmù 12:19) Máa bá a nìṣó láti wá ọ̀nà láti yọ́ àkópọ̀ ìwà rẹ mọ́, ní mímú àwọn ànímọ́ Kristẹni dàgbà. (Pétérù Kejì 1:5-8) Mọrírì gbogbo ohun tí àwọn ẹlòmíràn ṣe fún ọ, títí kan àwọn alàgbà tí wọ́n ń fi ìfẹ́ bójú tó àwọn àìní rẹ nípa tẹ̀mí. (Hébérù 13:7, 17) Jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, kí o sì tẹ ojú rẹ mọ́ ẹ̀bùn ìyè, ní níní ìdánilójú pé ikú pàápàá kò lè fi dù ọ́.—Jòhánù 5:28, 29; 17:3.

Bí o bá ń nírìírí ìbìnújẹ́ ńlá tàbí àdánwò líle koko ní lọ́ọ́lọ́ọ́, “fi gbogbo àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa,” ìdùnnú ńlá yóò sì rọ́pò ẹ̀dùn ọkàn rẹ àti ìnira tí o ń nírìírí rẹ̀, nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Òwe 3:5, 6; Jòhánù 16:20) Ayọ̀ yóò rọ́pò ìsoríkọ́, nígbà tí Ọlọ́run bá bù kún ọ gẹ́gẹ́ bí ó ti bù kún Jóòbù. Ìyà ìsinsìnyí kò tó nǹkankan bí a bá fi wọ́n wé èrè tí ìwọ yóò jẹ. (Fi wé Róòmù 8:18.) Ìfaradà olóòótọ́ rẹ lè fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí, kí ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú àwọn ànímọ́ dídára Kristẹni, tí ń bá “àkópọ̀ ìwà tuntun” rìn dàgbà. (Éfésù 4:23, 24; Kólósè 3:10, 12-14) Nítorí náà, fa okun láti inú ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n àpọ́sítélì Pétérù pé: “Kí àwọn wọnnì pẹ̀lú tí ń jìyà ní ìbáramuṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ inú Ọlọ́run máa bá a nìṣó ní fífi ọkàn wọn sí abẹ́ ìtọ́jú Ẹlẹ́dàá olùṣòtítọ́ bí wọ́n ti ń ṣe rere.”—Pétérù Kíní 4:19.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Dà bíi Jóòbù. Má ṣe sọ ìrètí nù láé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Fi gbogbo ọkàn àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́