“Ẹ Máa Ṣe Èyí”—April 5 La Máa Ṣe Ìrántí Ikú Kristi
1. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi?
1 “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí ló fi jẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣe ìrántí ikú ìrúbọ òun. Nítorí àwọn nǹkan tí ìràpadà Jésù mú kó ṣeé ṣe, kò sí ọjọ́ kan láàárín ọdún tá a lè sọ pé ó ṣe pàtàkì tàbí tó ṣeyebíye fún àwa Kristẹni tó ọjọ́ tá a máa ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún. Bí April 5 tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi ṣe ń sún mọ́lé, báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọ oore tí Jèhófà ṣe fún wá?—Kól. 3:15.
2. Báwo la ṣe lè fi ìmoore wa hàn fún Ìrántí Ikú Kristi nípasẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣàṣàrò?
2 Múra Sílẹ̀: A sábà máa ń múra sílẹ̀ fún ohun tá a bá kà sí pàtàkì. A lè múra ọkàn wa sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi tá a bá ń jíròrò àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé tá a sì ń ṣàṣàrò lórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé. (Ẹ́sírà 7:10) Díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tẹ́ ẹ lè kà wà nínú kàlẹ́ńdà àti ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́. Àmọ́, tẹ́ ẹ bá fẹ́ rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tẹ́ ẹ lè kà lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹ̀lú àwọn àkòrí tá a ti jíròrò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà nínú ìwé Ọkunrin Titobilọla, ẹ wo Ilé Ìṣọ́ February 1, 2011, ojú ìwé 23 àti 24.
3. Báwo la ṣe lè fi ìmoore wa hàn fún Ìrántí Ikú Kristi nípa títúbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
3 Máa Wàásù: A lè fi ìmoore wa hàn nípa lílo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Lúùkù 6:45) Bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Saturday, March 17, kárí ayé la máa bẹ̀rẹ̀ sí í pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Ṣé o lè ṣètò àkókò rẹ kó o lè lo àkókò tó pọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, tàbí kẹ̀, kó o ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́? Ẹ ò ṣe jíròrò ọ̀rọ̀ yìí nígbà tẹ́ ẹ bá tún máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé yín?
4. Àǹfààní wo la máa ń rí bá a ṣe ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi?
4 Ẹ ò rí i pé ó máa ń ṣe wá láǹfààní gan-an bá a ṣe máa ń pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún! Ayọ̀ wa àti ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run máa ń pọ̀ sí i bá a ṣe ń ronú lórí ìwà ọ̀làwọ́ Jèhófà ní ti bó ṣe fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fún wa gẹ́gẹ́ bí ìràpadà. (Jòhánù 3:16; 1 Jòhánù 4:9, 10) Èyí wá sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa láti má ṣe tún wà láàyè fún ara wa mọ́. (2 Kọ́r. 5:14, 15) Ó tún mú kó máa wù wá láti yin Jèhófà ní gbangba. (Sm. 102:19-21) Kò sí àní-àní pé àwa ìránṣẹ́ Jèhófà moore, tayọ̀tayọ̀ la sì fi ń fojú sọ́nà fún Ìrántí Ikú Kristi ní April 5, nígbà tá a máa ní àǹfààní láti “pòkìkí ikú Olúwa.”—1 Kọ́r. 11:26.