Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 19
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 19
Orin 11 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 18 ìpínrọ̀ 6 sí 11 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jeremáyà 8-11 (10 min.)
No. 1: Jeremáyà 10:17–11:5 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Jésù Kristi Jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run àti Ọba Tí Ọlọ́run Yàn—td 35A (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Ìgbàgbọ́ Nínú Jésù Fi Ṣe Kókó fún Ìgbàlà—td 35B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
15 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Mátíù 6:19-34. Ẹ jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
15 min: “Fi Ìgboyà Wàásù Níbi Táwọn Èèyàn Ti Ń Ṣiṣẹ́ Ajé.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tó máa ń wàásù dáadáa níbi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé.
Orin 108 àti Àdúrà