Fi Ìgboyà Wàásù Níbi Táwọn Èèyàn Ti Ń Ṣiṣẹ́ Ajé
1. Kí nìdí tí a kò fi gbọ́dọ̀ sọ̀rètí nù tó bá dà bíi pé ẹ̀rù ń bà wá láti wàásù níbi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé?
1 Ṣé ẹ̀rù máa ń bà ọ́ tó bá di pé kó o lọ wàásù níbi tí àwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé? Má sọ̀rètí nù, torí pé Pọ́ọ̀lù pàápàá ní láti “máyàle” kó tó lè wàásù, láìka ti pé ó jẹ́ oníwàásù tó nígboyà sí. (1 Tẹs. 2:2) Ní báyìí, a máa jíròrò díẹ̀ lára àwọn ohun tó máa ń dẹ́rù bani àti àwọn àbá tó ṣeé múlò.
2. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa bẹ̀rù pé a máa múnú bí àwọn òṣìṣẹ́?
2 Ṣé Àwọn Òṣìṣẹ́ Kò Ní Bínú Pé À Ń Dí Àwọn Lọ́wọ́? Ní ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ ajé, àwọn tó máa ń dá oníbàárà lóhùn ti mọ̀ pé àwọn èèyàn máa dí àwọn lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́. Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni wọ́n máa kí ọ torí wọ́n á rò pé o fẹ́ bá àwọn ra ọjà ni. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n fọ̀wọ̀ wọ̀ ọ́ tó o bá múra lọ́nà tó bójú mu, tí ojú rẹ kóni mọ́ra tó o sì ṣe ọ̀yàyà sí wọn.
3. Kí la lè ṣe tá ò fi ní múnú bí àwọn oníbàárà?
3 Ṣé Nígbà Tí Àwọn Oníbàárà Bá Wà Níbẹ̀ Ni Màá Wàásù fún Àwọn Òṣìṣẹ́? Tó bá ṣeé ṣe, lọ nígbà tí àwọn oníbàárà kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ níbẹ̀, èyí sì lè jẹ́ ìgbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí ṣọ́ọ̀bù wọn. Mú sùúrù dìgbà tó bá ku àwọn òṣìṣẹ́ nìkan kó o tó lọ wàásù fún wọn. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe ṣókí.
4. Kí la lè sọ fún àwọn tó wà níbi iṣẹ́ ajé?
4 Kí Ni Kí N Sọ? Ẹni tó jẹ́ ọ̀gá ni kó o bá sọ̀rọ̀ tó bá jẹ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ pọ̀ níbẹ̀. O lè sọ pé: “Kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti bá àwọn oníṣòwò nílé, ìdí nìyí tá a fi wá rí yín níbi iṣẹ́ yín. Mo mọ̀ pé ẹnu iṣẹ́ lẹ wà, torí náà ọ̀rọ̀ mi kò ní pọ̀.” Kí wọ́n má bàa rò pé ńṣe ni àwa náà ń tajà, ó máa dára pé kí á má ṣe sọ̀rọ̀ nípa ọrẹ tá a máa ń gbà, àyàfi tí wọ́n bá béèrè nípa bá a ṣe ń ri owó ṣe iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Bí ilé ìtajà kan bá ṣe rí ló máa pinnu bóyá kó o tọrọ àyè lọ́wọ́ ọ̀gá ibẹ̀ láti bá àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ ní ṣókí. Tó bá fún ẹ láyè, ohun tó o bá ọ̀gá náà sọ ni kó o bá àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ sọ. Bí ọwọ́ òṣìṣẹ́ kan bá dí, má ṣe sọ̀rọ̀ púpọ̀, kó o wá fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú. Tí kò bá ṣeé ṣe láti bá àwọn òṣìṣẹ́ náà sọ̀rọ̀, ó ṣeé ṣe kí wọ́n gbà kó o fi àwọn ìwé kan sílẹ̀ tí wọ́n á lè kà nígbà tí ọwọ́ wọn bá dilẹ̀.
5. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ ṣojo láti wàásù ní ibi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé?
5 Jésù àti Pọ́ọ̀lù fi ìgboyà wàásù fún àwọn èèyàn ní ibi iṣẹ́ ajé wọn, ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 4:18-21; 9:9; Ìṣe 17:17) Bẹ Jèhófà pé kí ó jẹ́ kí ọkàn rẹ balẹ̀ kó o sì lè ní ìgboyà. (Ìṣe 4:29) Kò sígbà téèyàn dé ibi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé tí kò ní bá èèyàn, torí náà o ò ṣe gbìyànjú rẹ̀ wò ná?