Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 26
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 26
Orin 92 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 18 ìpínrọ̀ 12 sí 18 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jeremáyà 12-16 (10 min.)
No. 1: Jeremáyà 13:1-14 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ǹjẹ́ Gbígba Jésù Gbọ́ Nìkan Ló Máa Jẹ́ Kéèyàn Ní Ìgbàlà?—td 35D (5 min.)
No. 3: Àwọn Ìbùkún Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Mú Wá—td 21A (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀. Sọ àwọn ibi tí ẹ kò tíì pín ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi dé ní àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín.
10 min: Ẹ Má Gbà Gbé Aájò Àlejò. (Héb. 13:1, 2) Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. Sọ ètò tí ìjọ ṣe nípa Ìrántí Ikú Kristi. Ṣàlàyé onírúurú ọ̀nà tí àwọn ará lè gbà jẹ́ kí ara tu àwọn àlejò àtàwọn akéde aláìṣiṣẹ́mọ́ tó bá wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn alápá méjì. Ní apá àkọ́kọ́, akéde kan ń fi ọ̀yàyà kí ẹnì kan tá a fún ní ìwé ìkésíni kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà tó bẹ̀rẹ̀. Ní apá kejì, akéde náà ń bá ẹni náà sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ, kí wọ́n lè ṣètò bí ẹnì kan á ṣe máa wá kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
20 min: Ìṣẹ̀dá Ń Gbé Ògo Ọlọ́run Yọ. Ìbéèrè àti ìdáhùn tá a gbé ka Apá 3 nínú ìwé pẹlẹbẹ Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, ìpínrọ̀ 3 sí 21. Ní ṣókí fi àlàyé tó wà ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ, kó o wá fi àwọn ìbéèrè tó wà fún ìpínrọ̀ 3 sí 21 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà darí ìjíròrò yìí. Fi ìpínrọ̀ tó gbẹ̀yìn nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí parí ọ̀rọ̀ rẹ. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n wo fídíò tó dá lórí bí ìṣẹ̀dá ṣe ń gbé ògo Ọlọ́run yọ, ìyẹn “The Wonders of Creation Reveal God’s Glory,” láfikún sí ìjíròrò yìí.
Orin 110 àti Àdúrà