Ìṣẹ̀dá Ń Gbé Ògo Ọlọ́run Yọ
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ràn kí wọ́n máa wo àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá. Àmọ́ ìwọ̀nba èèyàn ló mọ̀ pé bí àwọn ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe nìyẹn ń jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó wà lọ́kàn Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa àti irú ẹni tó jẹ́ gan-an. (Róòmù 1:20) Nígbà ayé Dáfídì, ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà látinú ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí. Bákan náà, ó tún “rí” àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà, èyí sì mú kó túbọ̀ sún mọ́ ọn. (Sm. 8:3, 4) Apá Kẹta nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, máa jẹ́ kí àwa, àwọn ọmọ wa àti àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa díẹ̀ lára àwọn ohun tí Jèhófà dá, ó máa jẹ́ ká rí àwọn ànímọ́ rẹ̀, ó sì máa jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa jẹ́, èyí táá mú kí á lè túbọ̀ sún mọ́ ọn.
“Máa Fi Tọkàntara Ṣàkíyèsí” Iṣẹ́ Ọwọ́ Jèhófà: Jésù rọ̀ wá pé kí á “fi tọkàntara ṣàkíyèsí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run” kí á sì “kọ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n lára àwọn òdòdó lílì pápá.” (Mát. 6:26, 28) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú Ẹlẹ́dàá wa máa lágbára sí i, a máa túbọ̀ mọyì ọgbọ́n Jèhófà, a máa túbọ̀ mọyì bó ṣe ní agbára láti gbà wá, a ó sì rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́. Dípò tó o fi máa jẹ́ kí àwọn ohun tí ẹ̀dá èèyàn ṣe gbà ọ́ lọ́kàn, wá àyè láti máa kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà dá, kó o sì máa ronú nípa ohun tí àwọn nǹkan yìí ń jẹ́ ká mọ̀ nípa Ọlọ́run wa.—Sm. 19:1.