À ń rí ọwọ́ ìfẹ́ Jèhófà lára àwọn nǹkan tó dá, torí náà ó dá wa lójú pé ó máa fi ọ̀pọ̀ ìbùkún jíǹkí wa bá a ṣe ń fi gbogbo okun wa sìn ín
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àwọn Ohun Tí Jèhófà Dá Fi Hàn Pé Ó Nífẹ̀ẹ́ Wa
Ọwọ́ wa lè dí débi tá ò fi ní kíyè sáwọn nǹkan tí Jèhófà dá, tó jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀làwọ́ ni àti pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Àmọ́ Jésù gbà wá níyànjú pé ká máa fara balẹ̀ kíyè sí wọn, ká sì máa ronú lórí ohun tí wọ́n kọ́ wa nípa Jèhófà.—Mt 6:25, 26.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN OHUN TÍ JÈHÓFÀ DÁ FI HÀN PÉ Ó NÍFẸ̀Ẹ́ WA, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo làwọn nǹkan yìí ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa . . .
àwọn èròjà tó wà láyé?
afẹ́fẹ́?
koríko?
àwọn ẹranko?
ara àwa èèyàn?
ọpọlọ wa?