ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w23 March ojú ìwé 15-19
  • Túbọ̀ Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Jèhófà Lára Àwọn Nǹkan Tó Dá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Túbọ̀ Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Jèhófà Lára Àwọn Nǹkan Tó Dá
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA KÍYÈ SÍ ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ DÁ?
  • ỌLỌ́RUN FI ÀWỌN NǸKAN TÓ DÁ KỌ́ WA LẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA ARA RẸ̀
  • JÉSÙ FI ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ DÁ KỌ́ WA KÁ LÈ MỌ BÀBÁ RẸ̀
  • BÁWO LA ṢE LÈ KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I NÍPA ỌLỌ́RUN LÁRA ÀWỌN NǸKAN TÓ DÁ?
  • Máa Fi Àwọn Nǹkan Tí Jèhófà Dá Kọ́ Ọmọ Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Àwọn Ohun Tí Jèhófà Dá Fi Hàn Pé Ó Nífẹ̀ẹ́ Wa
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Ìṣẹ̀dá Ń Gbé Ògo Ọlọ́run Yọ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?—Apá 3: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Gbà Pé Ọlọ́run Wà?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
w23 March ojú ìwé 15-19

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 12

Túbọ̀ Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Jèhófà Lára Àwọn Nǹkan Tó Dá

“Àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, torí à ń fi òye mọ̀ wọ́n látinú àwọn ohun tó dá.”​—RÓÒMÙ 1:20.

ORIN 6 Ọ̀run Ń Polongo Ògo Ọlọ́run

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa

1. Kí ni ọ̀kan lára àwọn nǹkan tí Jóòbù ṣe tó jẹ́ kó túbọ̀ mọ Jèhófà?

NÍGBÀ ayé Jóòbù, onírúurú èèyàn ló bá sọ̀rọ̀. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tí òun àti Jèhófà jọ sọ ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an. Nígbà tí wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀, Jèhófà sọ fún Jóòbù pé kó kíyè sí díẹ̀ lára àwọn nǹkan àgbàyanu tóun dá. Ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ kí Jóòbù mọ̀ pé ọlọ́gbọ́n ni òun àti pé òun máa ń bójú tó àwọn ìránṣẹ́ òun. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run rán Jóòbù létí pé tóun bá lè bójú tó àwọn ẹranko, òun máa lè bójú tó òun náà. (Jóòbù 38:39-41; 39:1, 5, 13-16) Nígbà tí Jóòbù kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, ó kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà, ó sì jẹ́ kó mọ àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní.

2. Kí nìdí tó fi máa ń ṣòro fún wa láti kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá?

2 Táwa náà bá ń kíyè sí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, á jẹ́ ká túbọ̀ mọ irú ẹni tó jẹ́. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, ó lè má rọrùn fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ ìlú ńlá lò ń gbé, ó lè jẹ́ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Jèhófà dá lò ń rí lójoojúmọ́. Tó bá sì jẹ́ ìgbèríko lò ń gbé, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò ráyè tó láti kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Torí náà, ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa wáyè, ká sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà àti Jésù ṣe lo àwọn nǹkan tí Jèhófà dá láti kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn nǹkan tá a lè ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA KÍYÈ SÍ ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ DÁ?

Ádámù ń wo ìgbín tó ń rìn lórí àpáta.

Jèhófà fẹ́ kí Ádámù gbádùn àwọn nǹkan tóun dá, kó sì sọ wọ́n lórúkọ (Wo ìpínrọ̀ 3)

3. Kí ló fi hàn pé Jèhófà fẹ́ kí Ádámù gbádùn àwọn nǹkan tóun dá?

3 Jèhófà fẹ́ kí ẹni tó kọ́kọ́ dá sáyé gbádùn àwọn nǹkan tóun dá. Nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù, ó fi í sínú Párádísè kan, ó sì ní kó máa bójú tó o kí gbogbo ayé lè di Párádísè. (Jẹ́n. 2:8, 9, 15) Ẹ wo bí inú Ádámù ṣe máa dùn tó nígbà tó rí bí àwọn igi eléso ṣe ń dàgbà táwọn ewéko sì ń yọ òdòdó. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni Ádámù ní pé Jèhófà gbéṣẹ́ fún un kó máa bójú tó ọgbà Édẹ́nì! Jèhófà tún sọ fún Ádámù pé kó sọ oríṣiríṣi ẹranko lórúkọ. (Jẹ́n. 2:19, 20) Jèhófà fúnra ẹ̀ lè sọ àwọn ẹranko yẹn lórúkọ, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ádámù ló gbé iṣẹ́ yẹn fún. Kò sí àní-àní pé Ádámù máa kíyè sí àwọn ẹranko yẹn dáadáa. Á wo bí wọ́n ṣe rí àti bí wọ́n ṣe ń ṣe, kó tó sọ wọ́n lórúkọ. Ó dájú pé Ádámù máa gbádùn iṣẹ́ yẹn gan-an. Ó sì dájú pé iṣẹ́ yìí máa jẹ́ kó rí i pé ọlọ́gbọ́n ni Bàbá rẹ̀ ọ̀run torí pé àwọn nǹkan tó dá rẹwà gan-an, wọ́n sì máa jẹ́ ká gbádùn ayé wa.

4. (a) Kí nìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa kíyè sí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá? (b) Èwo nínú àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá lo mọyì jù?

4 Ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá ni pé ó fẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè ọ̀run, kí ẹ sì wò ó.” Lẹ́yìn náà, ó wá béèrè pé: “Ta ló dá àwọn nǹkan yìí?” Ó dájú pé a mọ ẹni náà. (Àìsá. 40:26) Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan tó wà lọ́run àti ayé títí kan àwọn nǹkan tó wà nínú òkun, àwọn nǹkan yìí sì ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́. (Sm. 104:24, 25) Tún ronú nípa bí Jèhófà ṣe dá àwa èèyàn. Tá a bá rí àwọn nǹkan tó rẹwà, a máa ń mọyì ẹ̀ gan-an. Jèhófà dá wa ká lè máa ríran, ká máa gbọ́ràn, ká mọ nǹkan lára, ká mọ adùn nǹkan, ká sì lè gbóòórùn. Àwọn nǹkan yìí ló ń jẹ́ ká gbádùn oríṣiríṣi nǹkan tí Jèhófà dá.

5. Bí Róòmù 1:20 ṣe sọ, àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá?

5 Bíbélì tún sọ ìdí pàtàkì míì tó fi yẹ ká máa kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Àwọn nǹkan náà ń jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ní. (Ka Róòmù 1:20.) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá wo àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, àá rí i pé onírúurú wọn ló wà, àgbàyanu sì ni wọ́n. Ṣé àwọn nǹkan yẹn ò fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni Ọlọ́run? Tún ronú nípa onírúurú oúnjẹ tá à ń gbádùn. Àwọn oúnjẹ yẹn jẹ́ ká rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Tá a bá ń kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, tíyẹn sì ń jẹ́ ká rí àwọn ànímọ́ tó ní, á jẹ́ ká túbọ̀ mọ irú ẹni tó jẹ́ ká sì sún mọ́ ọn. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe lo àwọn nǹkan tó dá láti fi kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan.

ỌLỌ́RUN FI ÀWỌN NǸKAN TÓ DÁ KỌ́ WA LẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA ARA RẸ̀

6. Kí la rí kọ́ lára àwọn ẹyẹ tó máa ń ṣí kiri?

6 Jèhófà ní àkókò tó máa ń ṣe nǹkan. Lọ́dọọdún, láti ìparí oṣù February sí àárín oṣù May, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń rí àwọn ẹyẹ àkọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣí lọ sí apá àríwá. Ọlọ́run sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹyẹ àkọ̀ tó ń fò lójú ọ̀run mọ àkókò rẹ̀.” (Jer. 8:7) Bí Jèhófà ṣe jẹ́ káwọn ẹyẹ àkọ̀ mọ ìgbà tí wọ́n máa ṣí lọ sí ibòmíì, òun náà ti mọ ọjọ́ àti wákàtí tó máa ṣèdájọ́ ayé burúkú yìí. Lónìí, tá a bá ń rí àwọn ẹyẹ tó ń ṣí láti ibì kan sí ibòmíì, wọ́n máa ń rán wa létí pé Jèhófà ti dá ọjọ́ àti wákàtí tó máa pa ayé burúkú yìí run, ìyẹn sì ń fi wá lọ́kàn balẹ̀.​—Háb. 2:3.

7. Kí ló máa ń dá wa lójú tá a bá rí ẹyẹ tó ń fò? (Àìsáyà 40:31)

7 Jèhófà máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lágbára. Jèhófà ṣèlérí nípasẹ̀ wòlíì Àìsáyà pé òun máa fún àwọn ìránṣẹ́ òun lókun láti “fi ìyẹ́ fò lọ sókè réré bí ẹyẹ idì” nígbà tí wọn ò bá lókun mọ́ tàbí tí wọ́n bá rẹ̀wẹ̀sì. (Ka Àìsáyà 40:31.) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń rí àwọn ẹyẹ idì tó máa ń fò lọ sókè réré, wọn kì í sì í sábà lo agbára púpọ̀ láti ju ìyẹ́ wọn. Ohun tó jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe ni pé bí wọ́n bá ṣe ń rá bàbà nínú atẹ́gùn tó móoru, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n á máa fò lọ sókè sí i. Èyí rán wa létí pé tí Jèhófà bá lè fún àwọn ẹyẹ idì lágbára, ó dá wa lójú pé ó máa fún àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ náà lágbára! Torí náà, tó o bá rí ẹyẹ ńlá tó ń fò lọ sókè réré lójú ọ̀run láìfi agbára ju ìyẹ́ ẹ̀, máa rántí pé Jèhófà máa fún ìwọ náà lágbára láti borí àwọn ìṣòro tó o bá ní.

8. Kí ni Jóòbù kọ́ lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, kí làwa náà sì lè kọ́?

8 Ó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Jèhófà ran Jóòbù lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé òun. (Jóòbù 32:2; 40:6-8) Nígbà tí Ọlọ́run ń bá Jóòbù sọ̀rọ̀, ó sọ nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tóun dá irú bí ìràwọ̀, ìkùukùu àti mànàmáná. Jèhófà tún sọ nípa àwọn ẹranko bíi màlúù igbó àti ẹṣin. (Jóòbù 38:32-35; 39:9, 19, 20) Gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá yìí jẹ́ ká rí i pé agbára ẹ̀ ò láàlà, ó nífẹ̀ẹ́ wa, ọgbọ́n ẹ̀ sì pọ̀ gan-an. Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà àti Jóòbù jọ sọ yẹn mú kí Jóòbù túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Jóòbù 42:1-6) Lọ́nà kan náà, tá a bá ń kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, wọ́n máa rán wa létí pé òun ló gbọ́n jù, òun ló sì lágbára jù lọ láyé àtọ̀run. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà lágbára láti fòpin sí gbogbo ìṣòro wa, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dájú pé àwọn nǹkan tá a sọ yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

JÉSÙ FI ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ DÁ KỌ́ WA KÁ LÈ MỌ BÀBÁ RẸ̀

9-10. Kí ni oòrùn àti òjò kọ́ wa nípa Jèhófà?

9 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jésù mọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Torí pé Jésù jẹ́ “àgbà òṣìṣẹ́,” ó láǹfààní láti bá Bàbá ẹ̀ ṣiṣẹ́ nígbà tó dá àwọn nǹkan tó wà láyé àtọ̀run. (Òwe 8:30) Nígbà tí Jésù wá sáyé, ó fi àwọn nǹkan tí Bàbá rẹ̀ dá kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ohun tó kọ́ wọn.

10 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn. Nínú Ìwàásù orí Òkè, Jésù ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun kíyè sí méjì lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá táwọn èèyàn kì í kíyè sí. Àwọn nǹkan méjì náà ni oòrùn àti òjò. Àwọn nǹkan méjì yìí ṣe pàtàkì torí pé wọ́n ń gbé ẹ̀mí wa ró. Jèhófà lè sọ pé kí oòrùn má ràn, kí òjò má sì rọ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ò sin òun, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Gbogbo èèyàn pátá ló ń jàǹfààní àwọn nǹkan yìí. (Mát. 5:43-45) Jésù lo àwọn ohun tí Jèhófà dá yìí láti fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà fẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn. Nígbàkigbà tá a bá rí oòrùn tó rẹwà tó ń wọ̀ tàbí tí òjò tó tuni lára ń rọ̀, wọ́n máa ń rán wa létí pé Jèhófà kì í ṣojúsàájú. Táwa náà bá ń fara wé Jèhófà, tá à ń wàásù fún gbogbo èèyàn, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn nìyẹn.

11. Tá a bá rí àwọn ẹyẹ, báwo nìyẹn ṣe ń fi wá lọ́kàn balẹ̀?

11 Jèhófà ń pèsè àwọn ohun tá a nílò fún wa. Nínú Ìwàásù orí Òkè yẹn kan náà, Jésù tún sọ pé: “Ẹ fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run; wọn kì í fúnrúgbìn tàbí kárúgbìn tàbí kí wọ́n kó nǹkan jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí, síbẹ̀ Baba yín ọ̀run ń bọ́ wọn.” Ó ṣeé ṣe káwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù máa rí àwọn ẹyẹ tó ń fò lójú ọ̀run nígbà tí Jésù bi wọ́n pé: “Ṣé ẹ ò wá níye lórí jù wọ́n lọ ni?” (Mát. 6:26) Ohun tí Jésù sọ yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa bójú tó wa! (Mát. 6:31, 32) Àwọn nǹkan tá à ń rí kọ́ lára àwọn nǹkan tí Jèhófà dá yìí máa ń jẹ́ ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ìrẹ̀wẹ̀sì mú arábìnrin ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè Sípéènì torí pé kò rílé tó dáa gbé. Àmọ́ nígbà tó rí àwọn ẹyẹ tó ń jẹ èso, ọkàn ẹ̀ balẹ̀. Ó sọ pé: “Àwọn ẹyẹ yẹn rán mi létí pé Jèhófà ń bójú tó wọn, ó sì máa bójú tó èmi náà.” Kò pẹ́ sígbà yẹn, arábìnrin yẹn rílé táá máa gbé.

12. Kí ni Mátíù 10:29-31 sọ nípa àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́, kí ni wọ́n sì kọ́ wa nípa Jèhófà?

12 Jèhófà mọyì ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Kí Jésù tó rán àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ jáde láti lọ wàásù, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má bẹ̀rù àwọn tó máa ta kò wọ́n. (Ka Mátíù 10:29-31.) Torí náà, ó sọ̀rọ̀ nípa ẹyẹ ológoṣẹ́ táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ní Ísírẹ́lì. Owó táṣẹ́rẹ́ ni wọ́n máa ń ra àwọn ẹyẹ yìí nígbà ayé Jésù. Àmọ́, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Ìkankan nínú wọn ò lè já bọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀.” Jésù tún sọ pé: “Ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” Jésù wá fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lójú pé Jèhófà mọyì ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, torí náà wọn ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù inúnibíni. Ó dájú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa rántí ohun tó sọ fún wọn bí wọ́n ṣe ń rí àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ nígbà tí wọ́n ń wàásù láwọn ìlú àti abúlé ní Ísírẹ́lì. Ìgbàkigbà tí ìwọ náà bá rí ẹyẹ kékeré kan, máa rántí pé Jèhófà mọyì ẹ torí pé o “níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” Torí náà, má bẹ̀rù táwọn èèyàn bá ń ta kò ẹ́, Jèhófà máa wà pẹ̀lú ẹ.​—Sm. 118:6.

BÁWO LA ṢE LÈ KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I NÍPA ỌLỌ́RUN LÁRA ÀWỌN NǸKAN TÓ DÁ?

13. Kí ló máa jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá?

13 Nǹkan míì wà tá a lè ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà lára àwọn nǹkan tó dá. Kí làwọn nǹkan náà? Àkọ́kọ́, ká máa wáyè láti kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Lẹ́yìn náà, ká máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí wọ́n kọ́ wa nípa Jèhófà. Lóòótọ́, ó lè má rọrùn fún wa láti ṣe gbogbo ohun tá a sọ yìí, àmọ́ ẹ gbọ́ ohun tí Arábìnrin Géraldine tó wá láti Kamẹrúùnù sọ. Ó ní: “Ìlú ńlá ni mo dàgbà sí, torí náà èèyàn gbọ́dọ̀ wáyè kó tó lè máa kíyè sí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá.” Alàgbà kan tó ń jẹ́ Alfonso sọ pé: “Mo ti rí i pé ó yẹ kí n máa wáyè kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, kí n sì ronú lórí ohun táwọn nǹkan náà kọ́ mi nípa Jèhófà.”

Dáfídì ń wo àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run nígbà tó ń da àgùntàn ní pápá lálẹ́.

Nígbà tí Dáfídì kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá tó wà láyìíká ẹ̀, ó ṣàṣàrò nípa wọn, kó lè mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Kí ni Dáfídì rí kọ́ nígbà tó ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá?

14 Dáfídì ronú jinlẹ̀ lórí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá. Ó sọ fún Jèhófà pé: “Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti ṣètò sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú jẹ́ tí o fi ń fi í sọ́kàn?” (Sm. 8:3, 4) Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí Dáfídì ń wo ojú ọ̀run lálẹ́, kò kàn wo bí àwọn ìràwọ̀ yẹn ṣe pọ̀ lọ súà nìkan. Ó tún ṣàṣàrò lórí ohun táwọn ìràwọ̀ yẹn kọ́ ọ nípa Ọlọ́run. Ó kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà tóbi lọ́ba. Ìgbà kan wà tí Dáfídì tún ronú nípa ìgbà tóun ń dàgbà nínú ìyá òun. Bí Dáfídì ṣe ṣàṣàrò lórí gbogbo nǹkan yìí jẹ́ kó túbọ̀ mọyì ọgbọ́n tí Jèhófà ní.​—Sm. 139:14-17.

15. Sọ àwọn ànímọ́ Jèhófà tó o rí lára àwọn nǹkan tó dá. (Sáàmù 148:7-10)

15 Bíi ti Dáfídì, ibi yòówù ká wà, a máa rí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá tá a máa ṣàṣàrò nípa ẹ̀. Tó o bá wo àwọn nǹkan tó wà láyìíká ẹ, á jẹ́ kó o rí àwọn ànímọ́ Jèhófà tó wà lára àwọn nǹkan náà. Bí àpẹẹrẹ, nígbàkigbà tó o bá ń yá oòrùn, máa rántí pé Jèhófà lágbára gan-an. (Jer. 31:35) Ronú nípa ọgbọ́n Ọlọ́run tó o bá rí ìtẹ́ tí ẹyẹ kan kọ́. Máa ronú nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ Ọlọ́run aláyọ̀ tó o bá rí ọmọ ajá tó ń fi ìrù ẹ̀ ṣeré. Máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó nífẹ̀ẹ́ wa tó o bá rí ìyá kan tó ń bá ọmọ ẹ̀ jòjòló ṣeré. Torí náà, ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa tó lè jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára Jèhófà torí pé gbogbo ohun tó dá ló ń yìn ín, bóyá wọ́n tóbi tàbí wọ́n kéré, bóyá wọ́n jìnnà sí wa tàbí wọ́n sún mọ́ wa.​—Ka Sáàmù 148:7-10.

16. Kí la pinnu pé àá máa ṣe?

16 Ọlọ́run tá à ń sìn gbọ́n gan-an. Ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó lágbára, gbogbo ohun tó dá ló sì rẹwà. Àwọn ànímọ́ tá a sọ yìí àtàwọn míì la máa rí lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá tá a bá ń kíyè sí wọn. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa wáyè kíyè sáwọn nǹkan tí Jèhófà dá, ká sì máa ronú nípa ohun tí wọ́n kọ́ wa nípa Jèhófà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá túbọ̀ sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wa. (Jém. 4:8) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí bí àwọn òbí ṣe lè fi àwọn nǹkan tí Jèhófà dá kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè sún mọ́ Jèhófà.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká wáyè láti máa kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá?

  • Àwọn nǹkan tí Jèhófà dá wo lòun àti Jésù fi kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì?

  • Nǹkan míì wo la lè ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà lára àwọn nǹkan tó dá?

ORIN 5 Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Ọlọ́run

a Àgbàyanu làwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Ó máa ń yà wá lẹ́nu tá a bá rí àwọn nǹkan tó dá yìí, látorí àwọn nǹkan tó tóbi bí oòrùn títí dórí àwọn nǹkan bíńtín bí ewé kékeré ara òdòdó. A tún lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn nǹkan tí Jèhófà dá torí wọ́n máa ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ ká máa kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá àti bí wọ́n ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ sún mọ́ ọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́