Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 2
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 2
Orin 8 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 18 ìpínrọ̀ 19 sí 24 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jeremáyà 17-21 (10 min.)
No. 1: Jeremáyà 21:1-10 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí Ni Ìṣàkóso Sátánì Ti Fi Hàn?(5 min.)
No. 3: Ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ Nígbà Tí Àwọn Ọ̀tá Kristi Ṣì Wà Láàyè—td 21B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé yìí láti ṣàṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Saturday àkọ́kọ́ lóṣù April.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù April. Ìjíròrò. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì tọ́ka sí àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ April, ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn, kí wọ́n sì sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! April–June 2012, tí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
Orin 99 àti Àdúrà