Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní March: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá wàásù fún ẹnì kan. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ẹ fún ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ yín ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kò tíì máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé, ẹ ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá wàásù fún ẹnì kan. Bí onílé bá ti ní ìwé náà, tí kò sì fẹ́ kí á wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹ lè fún un ní àwọn ìwé ìròyìn tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ tàbí ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí onílé nífẹ̀ẹ́ sí.
◼ Lọ́dún yìí, ọjọ́ Thursday, April 5, 2012 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Bó bá jẹ́ pé ọjọ́ Thursday lẹ máa ń ṣe ìpàdé yín, ṣe ni kẹ́ ẹ ṣe é ní ọjọ́ mìíràn nínú ọ̀sẹ̀ náà bí àyè bá máa wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí kò bá ṣeé ṣe, tí àwọn ohun kan sì wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tó kan ìjọ yín gbọ̀ngbọ̀n, ẹ lè fi apá yẹn kún ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn míì.
◼ Àwọn kókó tó wà nísàlẹ̀ yìí jẹ́ ìsọfúnni nípa Ìrántí Ikú Kristi. A mú un jáde látinú ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ti ọdún 2011:
○ Iye àwọn akéde kárí ayé: 7,659,019
○ Iye àwọn tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi kárí ayé: 19,374,737
○ Iye àwọn tó jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ kárí ayé: 11,824
○ Iye àwọn tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà: 699,406
◼ Òpin ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé Ìrántí Ikú Kristi la máa sọ àkànṣe àsọyé. Ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé náà ni, “Ǹjẹ́ Òpin Ti Sún Mọ́lé Ju Bó O Ṣe Rò Lọ?”
◼ A máa jíròrò àwọn fídíò méjì tó dá lórí àwọn ọ̀dọ́, tá a pè ní Young People Ask, How Can I Make Real Friends? àti What Will I Do With My Life?, ní àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tó ń bọ̀ lọ́nà. Tẹ́ ẹ bá nílò wọn, ẹ tètè béèrè fún wọn nípasẹ̀ ìjọ yín.