Orin 99
Ẹ Yin Ọba Tuntun Tó Jẹ Lórí Ayé
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Kristi àti ìjọ rẹ̀ ńkó
ogunlọ́gọ̀ èèyàn jọ,
Láti inú gbogbo ẹ̀yà
àti orílẹ̀-èdè.
A bí Ìjọba Ọlọ́run;
Ìfẹ́ rẹ̀ fáyé máa tó ṣẹ.
Ẹ̀bùn ’yebíye nìrètí yìí,
Ó ńfúnni láyọ̀, ìtùnú.
(ÈGBÈ)
Ẹ yin Ọlọ́run wa,
Ẹ yin Kristi Jésù.
Wọ́n fi ìràpadà gbà wá là.
A nírètí ìyè láyé ká lè
Sin Jèhófà títí láé.
2. A ńkókìkí Kristi, Ọba wa,
a ńhó ìhó ayọ̀.
Ọmọ Aládé Àlàáfíà
yìí yóò fún wa nígbàlà.
Díẹ̀ ló kù, ayọ̀ wa dé tán:
Jìnnìjìnnì yóò tán láyé,
Àjíǹde yóò tún pabanbarì.
Ayọ̀ yóò sì wá gbayé kan!
(ÈGBÈ)
Ẹ yin Ọlọ́run wa,
Ẹ yin Kristi Jésù.
Wọ́n fi ìràpadà gbà wá là.
A nírètí ìyè láyé ká lè
Sin Jèhófà títí láé.
(Tún wo Sm. 2:6; 45:1; Aísá. 9:6; Jòh. 6:40.)