Orin 98
Fífúnrúgbìn Èso Ìjọba Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ẹ wá gbogbo ẹrú Jèhófà,
Tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run lọ́kàn.
Ẹ jáde wá ṣiṣẹ́ Ọ̀gá wa,
Kí ẹ tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀.
Ẹ gbin èso òtítọ́ láìbẹ̀rù
Sínú ọkàn tí yóò sèso
Síyìn Ọlọ́run wa bí ẹ ti ńṣiṣẹ́,
Tẹ́ẹ̀ ńkópa kíkún lóde ẹ̀rí.
2. Lára irúgbìn tẹ́ẹ fún lè bọ́
Sínú ọkàn bí òkúta.
Wọ́n lè ṣe dáadáa fúngbà díẹ̀,
Ṣùgbọ́n ọkàn wọn ṣì máa hàn.
Tẹ́gùn-ún bá pa ọ̀rọ̀ náà,
a jẹ́ pé;
Wọ́n níwọra fóhun ayé.
Síbẹ̀, èso míì yóò dàgbà; ẹó sì ríi
Lórílẹ̀ àtàtà, tó sì mọ́.
3. Béso rẹ ṣe máa ṣe dáadáa tó
Ọwọ́ rẹ lèyí wà jù lọ.
Pẹ̀lú sùúrù àtẹ̀mí ìfẹ́,
Ọkàn wọn lè wá gba òótọ́.
Bóo wà lójúfò, wàá ki wọ́n láyà,
Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú ’gboyà.
O lè máa retí láti fayọ̀ kórè
Ọgbọọgbọ̀n tàbí ọgọ́rọ̀ọ̀rún.
(Tún wo Mát. 13:19-23; 22:37.)