Irú Ọmọ Ejò náà—Báwo ni A Ṣe Tú u Fó?
“Èmi óò sì fi ọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sáàárín irú ọmọ rẹ àti irú ọmọ rẹ̀.”—GENESISI 3:15.
1. (a) Èé ṣe tí Jehofa fi jẹ́ Ọlọrun aláyọ̀? (b) Kí ni ó ti ṣe kí a baà lè ṣàjọpín ìdùnnú-ayọ̀ rẹ̀?
JEHOFA ni Ọlọrun aláyọ̀, pẹ̀lú ìdí tí ó ṣe gúnmọ́ sì ni. Òun ni atóbilọ́lá àti òléwájú nínú jíjẹ́ Olùfúnni ní àwọn ohun rere, kò sì sí ohun tí ó lè mú kí ìmúṣẹ ìlérí rẹ̀ ṣákìí. (Isaiah 55:10, 11; 1 Timoteu 1:11; Jakọbu 1:17) Ó fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe àjọpín ìdùnnú-ayọ̀ rẹ̀, ó sì pèsè àwọn ìdí tí ó yè kooro fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nípa báyìí, nínú ọ̀kan lára àwọn àkókò tí ó ṣú dùdù jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn—nígbà ìṣọ̀tẹ̀ ní Edeni—ó pèsè ìdí fún wa láti wo ọjọ́ iwájú pẹ̀lú ìrètí.—Romu 8:19-21.
2. Nígbà tí ó ń kéde ìdájọ́ sórí àwọn ọlọ̀tẹ̀ ní Edeni, báwo ni Jehofa ṣe pèsè ìpìlẹ̀ fún ìrètí fún àwọn ọmọ Adamu àti Efa?
2 Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀mí ti Jehofa, nípa títa ko Ọlọrun àti fífi ọ̀rọ̀ èké bà á jẹ́, ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ara rẹ̀ di Satani Eṣu ni. Àwọn ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́, Efa, àti lẹ́yìn náà, Adamu, ti bọ́ sábẹ́ agbára rẹ̀, wọ́n sì ti rú òfin tí Jehofa là sílẹ̀ ketekete. A dájọ́ ikú fún wọn lọ́nà tí ó bá ìdájọ́ òdodo mu. (Genesisi 3:1-24) Síbẹ̀, nígbà tí ó ń kéde ìdájọ́ sórí àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyí, Jehofa pèsè ìdí fún ìrètí fún àwọn ọmọ Adamu àti Efa. Lọ́nà wo? Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní Genesisi 3:15, Jehofa sọ pé: “Èmi óò sì fi ọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sáàárín irú ọmọ rẹ àti irú ọmọ rẹ̀: òun óò fọ́ ọ ní orí, ìwọ óò sì pa á ní gìgísẹ̀.” Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn jẹ́ kọ́kọ́rọ́ sí lílóye gbogbo Bibeli, àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àtijọ́ àti ti lọ́wọ́lọ́wọ́, tí ó kan ayé àti àwọn ìránṣẹ́ Jehofa.
Ohun Tí Àsọtẹ́lẹ̀ Náà Túmọ̀ Sí
3. Gẹ́gẹ́ bí a ti tọ́ka sí i ní Genesisi 3:15, sọ ẹni tí (a) Ejò náà, (b) “obìnrin náà,” (d) “irú ọmọ” Ejò náà, (e) “irú ọmọ” obìnrin náà jẹ́.
3 Láti mọ ìjẹ́pàtàkì rẹ̀, gbé àwọn apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ náà fúnra rẹ̀ yẹ̀ wò. Ẹni tí a ń bá sọ̀rọ̀ ní Genesisi 3:15 ni Ejò náà—kì í ṣe ejò rírẹlẹ̀ náà, bí kò ṣe ẹni tí ó lò ó. (Ìṣípayá 12:9) “Obìnrin náà” kì í ṣe Efa, bí kò ṣe ètò àjọ Jehofa ní ọ̀run, ìyá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí a fi ẹ̀mí yàn lórí ilẹ̀ ayé. (Galatia 4:26) “Irú ọmọ” Ejò náà, ni irú ọmọ Satani, ọmọ rẹ̀—àwọn ẹ̀mí èṣù àti ẹ̀dá ènìyàn títí kan àwọn ètò àjọ ẹ̀dá ènìyàn tí ń fi ìṣesí Satani hàn, tí wọ́n sì ń fi ìṣọ̀tá hàn sí “irú-ọmọ” obìnrin náà. (Johannu 15:19; 17:15) Ní pàtàkì, “irú-ọmọ” obìnrin náà ni Jesu Kristi, tí a fẹ̀mí mímọ́ yàn ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa. Àwọn 144,000, tí a ‘tún bí lati inú omi ati ẹ̀mí,’ tí wọ́n sì jẹ́ ajogún Ìjọba ọ̀run pẹ̀lú Kristi, jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ irú ọmọ ìlérí yẹn. A bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn wọ̀nyí kún irú ọmọ obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ láti Pentekosti ọdún 33 Sànmánì Tiwa síwájú.—Johannu 3:3, 5; Galatia 3:16, 29.
4. Báwo ni Genesisi 3:15 ṣe tan mọ́ bí ayé yóò ṣe di paradise kan, tí ó kún fún àwọn ènìyàn tí ó bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú?
4 Ẹni tí ẹ̀tàn rẹ̀ mú kí aráyé pàdánù Paradise ni ó lo ejò náà ní Edeni gẹ́gẹ́ bí agbọ̀rọ̀sọ. Genesisi 3:15 tọ́ka síwájú sí àkókò tí a óò tẹ ẹni tí ó lo ejò náà rẹ́. Nígbà náà, ọ̀nà yóò ṣí sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn ìránṣẹ́ Ọlọrun láti máa gbé nínú Paradise, tí ó bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ẹ wo àkókò onídùnnú-ayọ̀ tí ìyẹn yóò jẹ́!—Ìṣípayá 20:1-3; 21:1-5.
5. Àwọn ìwà wo ni ó ń fi àwọn ọmọ Eṣu nípa tẹ̀mí hàn?
5 Lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ ní Edeni, àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan àti àwọn ètò àjọ tí ó fi àwọn ìwà bíi ti Satani Eṣu hàn bẹ̀rẹ̀ sí fara hàn—ìṣọ̀tẹ̀, irọ́ pípa, ìfọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, àti ìṣìkàpànìyàn, pa pọ̀ pẹ̀lú ìṣòdìsí ìfẹ́ inú Jehofa àti sí àwọn tí ń jọ́sìn Jehofa. Ìwà wọ̀nyẹ́n fi àwọn ọmọ Eṣu hàn yàtọ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Lára àwọn wọ̀nyí ni Kaini, ẹni tí ó ṣìkà pa Abeli nígbà tí Jehofa fi ojú rere wo ìjọsìn Abeli dípò ti Kaini. (1 Johannu 3:10-12) Nimrodu, jẹ́ ẹnì kan tí orúkọ rẹ̀ gan-an fi hàn pé ọlọ̀tẹ̀ ni, tí ó sì di ọdẹ alágbára ńlá àti alákòóso ní ìṣòdì sí Jehofa. (Genesisi 10:9) Ní àfikún, ìtòtẹ̀léra àwọn ìjọba ìgbàanì ṣẹlẹ̀, títí kan Babiloni, pẹ̀lú àwọn ìsìn wọn tí ìjọba ṣe agbátẹrù rẹ̀, tí a gbé ka orí èké, ìwọ̀nyí sì ni àwọn olùjọsìn Jehofa lára lọ́nà rírorò.—Jeremiah 50:29.
‘Ọ̀tá Láàárín Ìwọ àti Obìnrin Náà’
6. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Satani ti gbà fi ìṣọ̀tá hàn sí obìnrin Jehofa?
6 Ní gbogbo àkókò yìí, ìṣọ̀tá wà láàárín Ejò náà àti obìnrin Jehofa, láàárín Satani Eṣu àti ètò àjọ Jehofa, ti àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí adúróṣinṣin ní ọ̀run. Ìṣọ̀tá Satani ni a fi hàn nígbà tí ó ṣáátá Jehofa, tí ó sì wá ọ̀nà láti da ètò àjọ Jehofa ní ọ̀run rú, nípa títan àwọn áńgẹ́lì láti pa ibùgbé tí ó yẹ wọ́n tì. (Owe 27:11; Juda 6) Ó fara hàn nígbà tí Satani lo àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ láti gbìyànjú láti de àwọn áńgẹ́lì ońṣẹ́ tí Jehofa rán níṣẹ́ lọ́nà. (Danieli 10:13, 14, 20, 21) Ó hàn gbangba-gbàǹgbà ní ọ̀rúndún ogún yìí, nígbà tí Satani wá ọ̀nà láti pa Ìjọba Messia run nígbà tí a bí i.—Ìṣípayá 12:1-4.
7. Èé ṣe tí àwọn áńgẹ́lì adúróṣinṣin ti Jehofa fi ní ẹ̀mí ìṣọ̀tá sí Ejo ìṣàpẹẹrẹ náà, síbẹ̀, ìséraró wo ni wọ́n ti fi hàn?
7 Obìnrin Jehofa, ẹgbẹ́ àwọn áńgẹ́lì adúróṣinṣin, pẹ̀lú bá Ejò ìṣàpẹẹrẹ náà ṣọ̀tá. Satani ti fi ọ̀rọ̀ èké ba orúkọ rere Ọlọrun jẹ́; ó tún ti gbé ìbéèrè dìde sí ìwà títọ́ olúkúlùkù ẹ̀dá onílàákàyè tí Ọlọrun dá, títí kan gbogbo àwọn áńgẹ́lì, ó sì ń gbìyànjú kíkankíkan láti bi ìdúróṣinṣin wọn sí Ọlọrun ṣubú. (Ìṣípayá 12:4a) Àwọn áńgẹ́lì, kérúbù, àti séráfù adúróṣinṣin kò lè ṣe nǹkan mìíràn tí ó yàtọ̀ sí fífi ìkórìíra ńláǹlà hàn sí ẹni tí ó ti sọ ara rẹ̀ di Eṣu àti Satani. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ti dúró de Jehofa, pé kí ó bójú tó àwọn nǹkan ní àkókò tirẹ̀ àti ní ọ̀nà tirẹ̀.—Fi wé Juda 9.
Kíkógunti Irú Ọmọ Obìnrin Ọlọrun
8. Ta ni Satani ń ṣọ́ lójú méjèèjì?
8 Láàárín àkókò yìí, Satani ń ṣọ́ Irú Ọmọ obìnrin náà tí a sọ tẹ́lẹ̀ lójú méjèèjì, ẹni tí Jehofa sọ pé yóò fọ́ Ejò náà ní orí. Nígbà tí áńgẹ́lì láti ọ̀rún kéde pé Jesu, tí a ti bí ní Betlehemu ni ‘Olùgbàlà náà, ẹni tí í ṣe Kristi Oluwa,’ èyí fìdí òtítọ́ náà múlẹ̀ gbọn-ingbọn-in pé, òun ni yóò di Irú Ọmọ tí a sọ tẹ́lẹ̀, ti obìnrin náà.—Luku 2:10, 11.
9. Lẹ́yìn ìbí Jesu, báwo ni Satani ṣe fi ìṣọ̀tá onínú burúkú hàn?
9 Ìṣọ̀tá onínú burúkú tí Satani ṣe fara hàn láìpẹ́, nígbà tí ó tan àwọn kèfèrí awòràwọ̀, láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ àpèrán tí ó mú kí wọ́n kọ́kọ́ lọ sọ́dọ̀ Ọba Herodu ní Jerusalemu, àti lẹ́yìn náà sí Betlehemu, ní ilé tí wọ́n ti rí ọmọdékùnrin náà, Jesu, àti Maria, ìyá rẹ̀. Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn náà, Ọba Herodu pàṣẹ pé kí a pa gbogbo ọmọdékùnrin ọlọ́dún méjì sísàlẹ̀, tí ó wà ní Betlehemu àti àyíká rẹ̀. Nínú èyí, Herodu fi ìkórìíra bíi ti Satani hàn sí Irú Ọmọ náà. Herodu mọ̀ dájúdájú pé ń ṣe ni òún ń gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ẹni tí yóò di Messia náà. (Matteu 2:1-6, 16) Ìtàn jẹ́rìí sí i pé Ọba Herodu jẹ́ oníwàkiwà, alárèékérekè, àti òṣìkàpànìyàn—lóòótọ́, ọ̀kan lára àwọn irú ọmọ Ejò náà ni òún í ṣe.
10. (a) Lẹ́yìn batisí Jesu, báwo ni Satani alára ṣe gbìyànjú láti mú kí ète Jehofa nípa Irú Ọmọ ìlérí náà ṣákìí? (b) Báwo ni Satani ṣe lo àwọn aṣáájú ìsìn Júù nínú ìlépa ète rẹ̀?
10 Lẹ́yìn tí a fi ẹ̀mí mímọ́ yan Jesu ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa àti lẹ́yìn tí Jehofa sọ̀rọ̀ láti ọ̀run, ní fífi hàn pé Ọmọkùnrin òun ni Jesu jẹ́, Satani gbìyànjú léraléra láti mú kí Jesu juwọ́ sílẹ̀ lábẹ́ ìdẹwò, ní títipa bẹ́ẹ̀ wá ọ̀nà láti mú kí ète Jehofa nípa Ọmọkùnrin rẹ̀ ṣákìí. (Matteu 4:1-10) Bí ó ti kùnà nínú ìyẹn, ó yíjú sí bíbá a nìṣó ní lílo àwọn aṣojú tí ó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Lára àwọn tí ó lò láti gbìyànjú láti bu ẹ̀tẹ́ lu Jesu ni àwọn alágàbàgebè aṣáájú ìsìn. Wọ́n lo irọ́ àti ìfọ̀rọ̀-èké-bani-jẹ́, irú àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Satani fúnra rẹ̀ lò. Nígbà tí Jesu sọ fún alárùn ẹ̀gbà kan pé, “Mọ́kànle, . . . a dárí awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì,” àwọn akọ̀wé, láìtilẹ̀ dúró rí i bóyá a ti wo ọkùnrin náà sàn ní tòótọ́, polongo pé asọ̀rọ̀-òdì ni Jesu. (Matteu 9:2-7) Nígbà tí Jesu wo àwọn ènìyàn sàn ní ọjọ́ Sábáàtì, àwọn Farisi pè é ní olùrú-òfin Sábáàtì, wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á run. (Matteu 12:9-14; Johannu 5:1-18) Nígbà tí Jesu lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, àwọn Farisi fẹ̀sùn kàn án pé ó ti mulẹ̀ pẹ̀lú “Beelsebubu, olùṣàkóso awọn ẹ̀mí-èṣù.” (Matteu 12:22-24) Lẹ́yìn tí a jí Lasaru dìde kúrò nínú òkú, ọ̀pọ̀ lára àwọn ènìyàn náà lo ìgbàgbọ́ nínú Jesu, ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi tún gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.—Johannu 11:47-53.
11. Ní ọjọ́ mẹ́ta ṣáájú ikú Jesu, ta ni òún fi hàn gẹ́gẹ́ bí apa kan irú ọmọ Ejò náà, èé sì ti ṣe?
11 Ní Nisani 11, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, bí Jesu tilẹ̀ mọ ohun tí wọ́n ń pète lọ́wọ́ dáradára, ó lọ tààrà láìṣojo sí agbègbè tẹ́ḿpìlì ní Jerusalemu, ó sì kéde ìdájọ́ lé wọn lórí ní gbangba níbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, àwọn akọ̀wé àti Farisi ti fi irú ènìyàn tí wọ́n jẹ́ hàn lọ́nà tí ó bára mu délẹ̀; nítorí náà, Jesu sọ pé: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin ati ẹ̀yin Farisi, alágàbàgebè! nitori pé ẹ̀yin sé ìjọba awọn ọ̀run pa níwájú awọn ènìyàn; nitori ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gba awọn wọnnì tí wọ́n wà lójú ọ̀nà sí ibẹ̀ láyè lati wọlé.” Jesu polongo ní tààràtà pé wọ́n jẹ́ apá kan irú ọmọ Ejò náà, ní sísọ pé: “Ẹ̀yin ejò, ẹ̀yin àmújáde-ọmọ paramọ́lẹ̀, bawo ni ẹ óò ṣe sá kúrò ninu ìdájọ́ Gẹ̀hẹ́nà?” (Matteu 23:13, 33) Ọ̀nà ìsọ̀rọ̀ rẹ̀ tọ́ka padà sí àsọtẹ́lẹ̀ tí ó wà ní Genesisi 3:15.
12, 13. (a) Báwo ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin ṣe fi ẹ̀rí hàn síwájú sí i nípa ẹni tí bàbá wọn nípa tẹ̀mí jẹ́? (b) Àwọn wo ni ó dara pọ̀ mọ́ wọn? (d) Ní ìmúṣẹ Genesisi 3:15, báwo ni a ṣe pa Irú Ọmọ obìnrin náà ní gìgísẹ̀?
12 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Jesu, ọkàn-àyà wọ́n ha gbọgbẹ́, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n rawọ́ ẹ̀bẹ̀ fún àánú Ọlọrun bí? Wọ́n ha ronú pìwà dà nínú ìwà burúkú wọn? Ó tì o! Marku 14:1 ròyìn pé, ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e gan-an, nínú ìpàdé kan tí wọ́n ṣe ní àgbàlá àlùfáà àgbà, “awọn olórí àlùfáà ati awọn akọ̀wé òfin sì ń wá ọ̀nà lati fi ọgbọ́n àrékérekè gbá [Jesu] mú kí wọ́n sì pa á.” Wọ́n ń bá a nìṣó ní fífi ẹ̀mí ìṣìkàpànìyàn ti Satani hàn, ẹni tí Jesu ti ṣàpèjúwe tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí apànìyàn. (Johannu 8:44) Láìpẹ́, Judasi Iskariotu, ẹni tí Satani yí lọ́kàn padà di apẹ̀yìndà, dara pọ̀ mọ́ wọn. Judasi pa Irú Ọmọ obìnrin Ọlọrun, tí ó jẹ́ aláìlẹ́bi, ti, ó sì dara pọ̀ mọ́ irú ọmọ Ejò náà.
13 Ní òwúrọ̀ kùtù hàì Nisani 14, àwọn mẹ́ḿbà kóòtù ìsìn àwọn Júù mú Jesu gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n lọ sọ́dọ̀ gómìnà Romu. Níhìn-ín, àwọn olórí àlùfáà ni wọ́n mú ipò iwájú ní kíkígbe pé kí a kàn án mọ́gi. Nígbà tí Pilatu béèrè pé, “Ṣé kí n kan ọba yín mọ́gi ni?” àwọn olórí àlùfáà ni ó dáhùn pé, “Awa kò ní ọba kankan bíkòṣe Kesari.” (Johannu 19:6, 15) Ní tòótọ́, wọ́n fi hàn ní gbogbo ọ̀nà pé wọ́n jẹ́ apá kan irú ọmọ Ejò náà. Ṣùgbọ́n, ó dájú pé àwọn nìkan kọ́. Àkọsílẹ̀ náà tí a mí sí nínú Matteu 27:24, 25 fúnni ní ìròyìn yìí: “Pilatu bu omi ó sì fọ ọwọ́ rẹ̀ níwájú ogunlọ́gọ̀ naa.” Nígbà náà ni gbogbo àwọn ènìyàn náà sọ pé: “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sórí wa ati sórí awọn ọmọ wa.” Nípa báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn Júù nínú ìran yẹn fi hàn pé apá kan irú ọmọ Ejò náà ni àwọ́n jẹ́. Kí ọjọ́ yẹn tó wá sí ìparí, Jesu ti kú. Nípa lílo irú ọmọ rẹ̀ tí ó ṣeé fojú rí, Satani pa Irú Ọmọ obìnrin Ọlọrun ní gìgìísẹ̀.
14. Èé ṣe tí pípa Irú Ọmọ obìnrin náà ní gìgísẹ̀ kò fi túmọ̀ sí ìṣẹ́gun fún Satani?
14 Satani ha ti borí bí? Àgbẹdọ̀! Jesu Kristi ti ṣẹ́gun ayé, ó sì ti borí olùṣàkóso ayé. (Johannu 14:30, 31; 16:33) Ó di ìdúróṣinṣin rẹ̀ sí Jehofa mú títí dé ojú ikú. Ikú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn pípé pèsè iye owó ìràpadà tí a nílò láti fi ra ẹ̀tọ́ ìwàláàyè tí Adamu pàdánù padà. Nítorí náà, ó ṣí ọ̀nà sí ìyè àìnípẹ̀kun sílẹ̀ fún àwọn tí ó bá lo ìgbàgbọ́ nínú ìpèsè yẹn, tí wọ́n sì ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Ọlọrun. (Matteu 20:28; Johannu 3:16) Jehofa jí Jesu dìde kúrò nínú òkú sínú ìyè àìlèkú ní ọ̀run. Nígbà tí àkókò bá tó lójú Jehofa, Jesu yóò tẹ Satani rẹ́ pátápátá. Nínú Genesisi 22:16-18, a sọ tẹ́lẹ̀ pé Jehofa yóò fi ojú rere wo gbogbo ìdílé tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé, tí ó gbé ìgbésẹ̀ yíyẹ láti bù kún ara wọn nípasẹ̀ adúróṣinṣin Irú Ọmọ yẹn.
15. (a) Lẹ́yìn ikú Jesu, báwo ní àwọn aposteli rẹ̀ ṣe ń bá a nìṣó láti tú irú ọmọ Ejò náà fó? (b) Ìkóguntì síwájú sí i wo ni irú ọmọ Ejò náà ti fi hàn títí di ọjọ́ wa lónìí?
15 Lẹ́yìn ikú Jesu, àwọn Kristian ti a fi ẹ̀mí yàn ń bá a nìṣó láti tú irú ọmọ Ejò náà fó, gẹ́gẹ́ bí Oluwa wọ́n ti ṣe. Bí ẹ̀mí mímọ́ ti sún un ṣiṣẹ́, aposteli Paulu kìlọ̀ nípa “ọkùnrin ìwà àìlófin,” ẹni tí wíwà níhìn-ín rẹ̀ yóò jẹ́ “ní ìbámu pẹlu ìṣiṣẹ́ Satani.” (2 Tessalonika 2:3-10) “Ọkùnrin” yìí tí ó jẹ́ àgbájọ àwọn ènìyàn fẹ̀rí hàn pé òún jẹ́ àwùjọ àlùfáà ti Kirisẹ́ńdọ̀mù. Nítorí èyí, irú ọmọ Ejò náà ń ṣenúnibíni gbígbóná janjan sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu Kristi. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí ó wà nínú Ìṣípayá 12:17, aposteli Johannu sọ tẹ́lẹ̀ pé, Satani yóò máa bá a nìṣó ní bíbá àṣẹ́kù irú ọmọ obìnrin Ọlọrun jagun títí dí ọjọ́ wa. Ìyẹn ni ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a ti fòfin dè, a ti fi ìwọ́jọpọ̀ ènìyànkénìyàn kọ lù wọ́n, a ti fi wọ́n sẹ́wọ̀n, a sì sọ wọ́n sí àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, nítorí ìdúróṣinṣin wọn fún Ìjọba Ọlọrun àti àwọn ọ̀nà òdodo rẹ̀.
Ìtúfó Irú Ọmọ Ejò Náà Lóde Òní
16. Ní àkókò òde òní, àwọn wo ni a ti tú fó pé ó jẹ́ apá kan irú ọmọ Ejò náà, báwo sì ni a ṣe ṣe èyí?
16 Ní àfarawé Jesu Kristi, àwọn Kristian tòótọ́ kò tí ì juwọ́ sílẹ̀ nínú fífi àìṣojo tú Ejò náà àti irú ọmọ rẹ̀ fó. Ní 1917, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, bí a ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sí nígbà yẹn, tẹ ìwé náà, The Finished Mystery jáde, nínú èyí tí wọ́n ti tú ìwà àgàbàgebè ẹgbẹ́ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù fó. Ní 1924, ìpinnu kan tí a tẹ̀ jáde, tí a pè ní Ecclesiastics Indicted ni ó tẹ̀ lé èyí. Àádọ́ta mílíọ̀nù ẹ̀dà ni a pín káàkiri ayé. Ní 1937, J. F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, sọ àwọn ìtúfó irú ọmọ Satani lọ́nà lílágbára nínú àwọn ọ̀rọ̀ àwíyé tí a pe àkòrí rẹ̀ ní “A Tú U Fó” àti “Ìsìn òun Ìsìn Kristian.” Ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, bí àwọn àwùjọ olùgbọ́ ní 50 àpéjọpọ̀ ti ń fetí sílẹ̀, ó sọ ọ̀rọ̀ àwíyé náà, “Dojú Kọ Òtítọ́,” nípa lílo rédíò tẹlifóònù láti London, ní England. Oṣù kan lẹ́yìn náà, ọ̀nà ìsokọ́ra rédíò tí a mú gbòòrò ní United States, gbé ọ̀rọ̀ náà “Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ Tàbí Òmìnira” jáde. Àwọn ìtúfó lílágbára ni a fi kún ìwọ̀nyí láti inú àwọn ìwé bí Awọn Ọta àti Religion àti láti inú ìwé pẹlẹbẹ náà Uncovered pẹ̀lú. Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí a ti ń tẹ̀ jáde láti àwọn ọdún 1920, ìwé náà, Revelation—Its Grand Climax At Hand!,a tí a ti tẹ̀ jáde nísinsìnyí ní èdè 65, fi hàn pé àwọn òṣèlú oníwà ìbàjẹ́ àti àwọn ọlọ́jà bìrìbìrì tí ó jẹ́ oníwọra àti oníwàkiwà pẹ̀lú jẹ́ ara àwọn òléwájú mẹ́ḿbà irú ọmọ Ejò náà tí a lè fojú rí. Nígbà tí àwọn aṣáájú ìṣèlú bá sọ ọ́ di àṣà láti máa lo èké ṣíṣe láti fi ṣi àwọn ọmọ abẹ́ wọn lọ́nà, tí wọn kò ka ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀ sí, tí wọ́n sì ń ni àwọn ìránṣẹ́ Jehofa lára (tí wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ ń fi ìkórìíra hàn sí irú ọmọ obìnrin Ọlọrun), dájúdájú wọ́n ń fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí apá kan irú ọmọ Ejò náà. Ohun kan náà ni ó jẹ́ òtítọ́ ní ti àwọn ọlọ́jà bìrìbìrì, àwọn tí ó jẹ́ pé, láìbìkítà nípa ẹ̀rí ọkàn, wọ́n ń purọ́ kí wọ́n bàa lè jẹ èrè, tí wọ́n sì ń ṣe tàbí ta àwọn nǹkan èlò tí wọ́n mọ̀ dáradára pé ó ń fa àìsàn.
17. Àǹfààní wo ni ó ṣì ṣí sílẹ̀ fún àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó yọrí ọlá, tí ó ṣeé ṣe kí ó jáde kúrò nínú ètò ìgbékalẹ̀ ayé?
17 Ní àtúbọ̀tán, a kì yóò ka gbogbo olúkúlùkù tí ìsìn ayé, ìṣèlú, tàbí ìṣòwò ti sọ di ẹlẹ́gbin sí apá kan irú ọmọ Ejò náà. Àwọn kan lára àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin wọ̀nyí wá ń kan sáárá sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Wọ́n ń lo agbára wọn láti fi ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́ láìpẹ́ láìjìnnà. (Fi wé Ìṣe 13:7, 12; 17:32-34.) A ti nawọ́ ẹ̀bẹ̀ yìí sí gbogbo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó gbọ́n, ẹ̀yin ọba: kí a sì kọ́ yín, ẹ̀yin onídàájọ́ ayé. Ẹ fi ìbẹ̀rù sin Oluwa, ẹ sì máa yọ̀ ti ẹ̀yin ti ìwárìrì. Fi ẹnu ko Ọmọ náà lẹ́nu, kí ó má ṣe bínú, ẹ̀yin a sì ṣègbé ní ọ̀nà náà, bí inú rẹ̀ bá ru díẹ̀ kíún. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.” (Orin Dafidi 2:10-12) Ní tòótọ́, ó ṣe pàtàkì pé, kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́ ojú rere Jehofa gbé ìgbésẹ̀ nísinsìnyí, kí Onídàájọ́ náà ní ọ̀run tó yára ti ilẹ̀kùn àǹfààní pa!
18. Bí wọn kò tilẹ̀ jẹ́ apá kan irú ọmọ obìnrin náà, àwọn wo ni wọ́n jẹ́ olùjọsìn Jehofa síbẹ̀síbẹ̀?
18 Kìkì àwọn tí yóò para pọ̀ di Ìjọba ọ̀run ni apá kan irú ọmọ obìnrin náà. Àwọn wọ̀nyí kéré níye. (Ìṣípayá 7:4, 9) Síbẹ̀, ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn mìíràn ń bẹ, bẹ́ẹ̀ ni, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọn, àwọn tí ó jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí olùjọsìn Jehofa, wọ́n ń wọ̀nà fún ìyè àìnípẹ̀kun lórí paradise ilẹ̀ ayé. Nípa ọ̀rọ̀ àti nípa ìṣe, wọ́n ń wí fún àwọn ẹni-àmì-òróró Jehofa pé: “A óò bá ọ lọ, nítorí àwá ti gbọ́ pé, Ọlọrun wà pẹ̀lú rẹ.”—Sekariah 8:23.
19. (a) Yíyàn wo ni gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ ṣe? (b) Ní pàtàkì, àwọn wo ni a fi ìtara ọkàn bẹ̀ láti gbégbèésẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n nígbà tí àǹfààní ṣì ṣí sílẹ̀?
19 Àkókò tí gbogbo aráyé gbọ́dọ̀ ṣe yíyàn nìyí. Wọ́n ha fẹ́ láti jọ́sìn Jehofa, kí wọ́n sì gbé ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ lárugẹ, tàbí kẹ̀, wọ́n yóò ha gba Satani láyè láti jẹ́ alákòóso wọn nípa ṣíṣe ohun tí ó wù ú? Nǹkan bíi mílíọ̀nù márùn-ún ènìyàn láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè ti mú ìdúró wọn ní ìhà ọ̀dọ̀ Jehofa, ní kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àṣẹ́kù irú ọmọ obìnrin náà, àwọn ajogún Ìjọba. Àwọn mílíọ̀nù mẹ́jọ mìíràn ti fi ìfẹ́ hàn sí kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wọn tàbí wíwá sí àwọn ìpàdé wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń sọ fún gbogbo àwọn wọ̀nyí pé: Ilẹ̀kùn àǹfààní ṣì ṣí sílẹ̀. Ẹ mú ìdúró yín láìmikàn ní ìhà ọ̀dọ̀ Jehofa. Ẹ tẹ́wọ́ gba Kristi Jesu gẹ́gẹ́ bí Irú Ọmọ tí a ṣèlérí náà. Ẹ fi ìdùnnú-ayọ̀ kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò àjọ Jehofa tí a lè fojú rí. Ǹjẹ́ kí ẹ nípìn-ín nínú gbogbo ìbùkún tí Òun yóò pèsè nípasẹ̀ ìṣàkóso Ọba náà, Kristi Jesu.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Ìwọ́ Ha Rántí Bí?
◻ Ta ni Ejò náà tí a tọ́ka sí i ní Genesisi 3:15? Ta sì ni obìnrin náà?
◻ Àwọn ìwà wo ni ó fi irú ọmọ Ejò náà hàn?
◻ Báwo ni Jesu ṣe tú irú ọmọ Ejò náà fó?
◻ Àwọn wo ni a ti tú fó pé wọ́n jẹ́ apá kan irú ọmọ Ejò náà ní àkókò òde òní?
◻ Ìgbésẹ̀ kánjúkánjú wo ní a ń béèrè láti yẹra fún jíjẹ́ apá kan irú ọmọ Ejò náà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jesu tú àwọn alágàbàgebè aṣáájú ìsìn fó pé wọ́n jẹ́ apá kan irú ọmọ Ejò náà