ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 6/15 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Irú Ọmọ Ejò náà—Báwo ni A Ṣe Tú u Fó?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Kí Nìdí Tí Sátánì Fi Lo Ejò Láti Bá Éfà Sọ̀rọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Lájorí Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Bíbélì
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 6/15 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ ejò tó bá Éfà sọ̀rọ̀ ní ẹsẹ̀?

Gẹ́gẹ́ bí Jẹ́nẹ́sísì 3:14 ṣe sọ, Jèhófà Ọlọ́run sọ fún ejò tó tan Éfà jẹ́ lọ́gbà Édẹ́nì pé: “Nítorí tí ìwọ ṣe nǹkan yìí, ẹni ègún ni ọ́ nínú gbogbo ẹran agbéléjẹ̀ àti nínú gbogbo ẹranko inú pápá. Ikùn rẹ ni ìwọ yóò máa fi wọ́, ekuru sì ni ohun tí ìwọ yóò máa jẹ ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ.” Bíbélì ò sọ pé ejò tí ẹ̀dá ẹ̀mí kan lò láti tan Éfà jẹ yìí ní ẹsẹ̀ tẹ́lẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:14 lè mú káwọn kan rò bẹ́ẹ̀, kò sídìí tó fi yẹ ká rò pé ejò ní ẹsẹ̀ kí Ọlọ́run tó gégùn-ún yìí. Èé ṣe tí kò fi yẹ ká rò bẹ́ẹ̀?

Ìdí pàtàkì jù lọ ni pé Sátánì, tí í ṣe ẹni ẹ̀mí téèyàn ò lè fojú rí tó lo ẹranko rírẹlẹ̀ yìí lọ́nà tí kò tọ́, gan-an ni Jèhófà ń dá lẹ́jọ́. Bíbélì pe Sátánì ní “baba irọ́” àti “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà.” Ó hàn gbangba pé ńṣe ni orúkọ méjèèjì yìí ń tọ́ka sí bí Sátánì ṣe gbẹnu ẹranko kan, ìyẹn ejò, bá Éfà sọ̀rọ̀ láti tàn án jẹ kó lè ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run.—Jòhánù 8:44; Ìṣípayá 20:2.

Ọlọ́run ló dá onírúurú ejò, ó sì hàn gbangba pé Ádámù ló sọ wọ́n ní ejò kí Sátánì tó lo ọ̀kan lára wọn láti tan Éfà jẹ. Ejò tó bá Éfà sọ̀rọ̀ ò lẹ́bi kankan nítorí pé kì í ṣe ẹ̀dá tó lè ronú. Kò lè mọ̀ pé Sátánì ń lo òun, kò sì lè mọ nǹkan kan nípa ìdájọ́ tí Ọlọ́run ṣe fáwọn tó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run nígbà yẹn.

Kí wá nìdí tí Ọlọ́run fi sọ pé òun máa fi ejò sí ipò ìrẹ̀sílẹ̀? Bí ejò ṣe máa ń ṣe tó bá ń lọ káàkiri, ìyẹn bó ṣe máa ń fàyà fà tó sì máa ń yọ ahọ́n bélébélé bíi pé ó ń lá yẹ̀pẹ̀, jẹ́ àpẹẹrẹ tó bá ipò ìrẹ̀sílẹ̀ tí Sátánì wà mu. Ipò tó ga ni Sátánì wà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run kí Ọlọ́run tó wá fi í sí ipò ìrẹ̀sílẹ̀ tí Bíbélì pè ní Tátárọ́sì.—2 Pétérù 2:4.

Kò mọ síbẹ̀ o, bí ejò gidi ṣe lè pa èèyàn ní gìgísẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Sátánì, ní ipò ìrẹ̀sílẹ̀ tó wà, ṣe pa “irú-ọmọ” Ọlọ́run “ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Jésù Kristi ni pàtàkì irú-ọmọ náà, ó sì jìyà fúngbà díẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ Sátánì. Àmọ́ tó bá yá, Kristi àtàwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tí Ọlọ́run jíǹde yóò fọ́ orí ejò ìṣàpẹẹrẹ náà pátápátá. (Róòmù 16:20) Nítorí náà, dídarí tí Ọlọ́run darí ègún sí ejò tó bá Éfà sọ̀rọ̀ fi hàn pé “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà” tá ò lè fojú rí, ìyẹn Sátánì Èṣù, á dẹni ìrẹ̀sílẹ̀ àti pé ó máa pa run pátápátá nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́