Orin 9
Ẹ Yin Jèhófà, Ọlọ́run Wa!
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ẹ yin Jáà! Yin Ọlọ́run wa!
Pòkìkí oókọ mímọ́ rẹ̀!
Ẹ kéde! Ọjọ́ rẹ̀ dé tán,
Kí gbogbo èèyàn gbọ́ ìkìlọ̀.
Ọlọ́run pàṣẹ pé àkókò tó
Fọ́mọ rẹ̀ láti di Ọba.
Ẹ sọ, ẹ ròyìn fún gbogbo èèyàn,
Àwọn ìbùkún Jáà tó ńbọ̀!
(Ègbè)
2. Ẹ yin Jáà! Gbé ohùn sókè!
Ẹ kọrin ayọ̀, ẹ gbée ga!
Fìgboyà Kéde ògo rẹ̀,
Látinú ọkàn ìmọrírì.
Ọlọ́run tóbi, iṣẹ́ ńlá rẹ̀ pọ̀,
Bẹ́ẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀, oore rẹ̀ ga.
Ó ńfi inúure, àánú, ìfẹ́ hàn.
Inú rẹ ńdùn báa ti ńké pèé.
(ÈGBÈ)
Ẹ yin Jáà! Yin Ọlọ́run wa!
Jẹ́ káyé gbọ́ròyìn ògo rẹ̀!
(Tún wo Sm. 89:27; 105:1; Jer. 33:11.)