ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 21
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Jèhófà kọ ẹ̀bẹ̀ Sedekáyà (1-7)

      • Àwọn èèyàn yóò yan ikú tàbí ìyè (8-14)

Jeremáyà 21:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:18; 1Kr 3:15; 2Kr 36:9, 10
  • +Jer 38:1
  • +Jer 29:25; 37:3; 52:24, 27

Jeremáyà 21:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:1; Jer 32:28; 39:1
  • +1Sa 7:10; 2Kr 14:11; Ais 37:36, 37

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 55-56

Jeremáyà 21:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “yí pa dà sí yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 32:5

Jeremáyà 21:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 63:10; Ida 2:5
  • +Ais 5:25

Jeremáyà 21:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Àìsàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:21, 22; Isk 7:15

Jeremáyà 21:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

  • *

    Tàbí “tó ń lépa ọkàn wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:6, 7; Jer 37:17; 39:5-7; 52:9-11; Isk 17:20
  • +Di 28:49, 50; 2Kr 36:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 158-159

Jeremáyà 21:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 11

Jeremáyà 21:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “sá àsálà fún ọkàn rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 27:12, 13; 38:2, 17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2002, ojú ìwé 15-16

Jeremáyà 21:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 44:11
  • +Jer 38:3
  • +2Kr 36:17, 19; Jer 17:27; 34:2; 37:10; 39:8

Jeremáyà 21:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:17; Jer 22:3; Isk 22:29; Mik 2:2
  • +Di 32:22; Ais 1:31; Jer 7:20
  • +Jer 7:5-7

Jeremáyà 21:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Jeremáyà 21:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 5:9; 9:9
  • +2Kr 36:17, 19; Jer 52:12, 13

Àwọn míì

Jer. 21:12Ọb 24:18; 1Kr 3:15; 2Kr 36:9, 10
Jer. 21:1Jer 38:1
Jer. 21:1Jer 29:25; 37:3; 52:24, 27
Jer. 21:22Ọb 25:1; Jer 32:28; 39:1
Jer. 21:21Sa 7:10; 2Kr 14:11; Ais 37:36, 37
Jer. 21:4Jer 32:5
Jer. 21:5Ais 63:10; Ida 2:5
Jer. 21:5Ais 5:25
Jer. 21:6Di 28:21, 22; Isk 7:15
Jer. 21:72Ọb 25:6, 7; Jer 37:17; 39:5-7; 52:9-11; Isk 17:20
Jer. 21:7Di 28:49, 50; 2Kr 36:17
Jer. 21:9Jer 27:12, 13; 38:2, 17
Jer. 21:10Jer 44:11
Jer. 21:10Jer 38:3
Jer. 21:102Kr 36:17, 19; Jer 17:27; 34:2; 37:10; 39:8
Jer. 21:12Ais 1:17; Jer 22:3; Isk 22:29; Mik 2:2
Jer. 21:12Di 32:22; Ais 1:31; Jer 7:20
Jer. 21:12Jer 7:5-7
Jer. 21:14Jer 5:9; 9:9
Jer. 21:142Kr 36:17, 19; Jer 52:12, 13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 21:1-14

Jeremáyà

21 Jeremáyà gbọ́ ọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà, nígbà tí Ọba Sedekáyà+ rán Páṣúrì+ ọmọ Málíkíjà àti Sefanáyà+ ọmọ Maaseáyà, àlùfáà sí i, pé: 2 “Jọ̀wọ́ bá wa wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, torí pé Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ń bá wa jà.+ Bóyá Jèhófà á ṣe ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀ nítorí wa, kí ọba yìí lè pa dà lẹ́yìn wa.”+

3 Jeremáyà sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ fún Sedekáyà pé, 4 ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Wò ó, màá jẹ́ kí àwọn ohun ìjà tó wà ní ọwọ́ yín dojú kọ yín,* àwọn ohun tí ẹ fi ń bá ọba Bábílónì jà+ pẹ̀lú àwọn ará Kálídíà tí wọ́n dó tì yín lẹ́yìn odi. Màá sì kó wọn jọ sí àárín ìlú yìí. 5 Èmi fúnra mi máa na apá mi àti ọwọ́ mi tó lágbára jáde láti bá yín jà+ pẹ̀lú ìbínú àti ìrunú àti ìkannú ńlá.+ 6 Màá pa àwọn tó ń gbé ìlú yìí, látorí èèyàn dórí ẹranko. Àjàkálẹ̀ àrùn* ńlá ni yóò sì pa wọ́n.”’+

7 “‘Jèhófà sọ pé, “Lẹ́yìn náà, màá fi Sedekáyà ọba Júdà àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn èèyàn ìlú yìí, ìyẹn àwọn tó bọ́ lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àrùn, idà àti ìyàn, lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn àti lé ọwọ́ àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí wọn.*+ Á fi idà pa wọ́n. Kò ní bá wọn kẹ́dùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ní yọ́nú sí wọn tàbí kó ṣàánú wọn.”’+

8 “Kí o sì sọ fún àwọn èèyàn yìí pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó, mò ń fi ọ̀nà ìyè àti ọ̀nà ikú síwájú yín. 9 Idà àti ìyàn pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn ni yóò pa àwọn tó bá dúró nínú ìlú yìí. Àmọ́ ẹni tó bá jáde, tó sì fi ara rẹ̀ lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà tí wọ́n dó tì yín, á máa wà láàyè, á sì jèrè ẹ̀mí rẹ̀.”’*+

10 “‘“Nítorí mo ti dojú mi kọ ìlú yìí láti mú àjálù bá a, kì í ṣe fún ire,”+ ni Jèhófà wí. “Màá fi lé ọba Bábílónì lọ́wọ́,+ á sì dáná sun ún.”+

11 “‘Ẹ̀yin agbo ilé ọba Júdà: Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. 12 Ẹ̀yin ilé Dáfídì, ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Ẹ máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́ ní àràárọ̀,

Kí ẹ sì gba ẹni tí àwọn oníjìbìtì jà lólè sílẹ̀,+

Kí ìbínú mi má bàa sọ bí iná+

Tó ń jó tí ẹnì kankan kò lè pa

Nítorí ìwà ibi yín.”’+

13 ‘Wò ó, mo dojú kọ ọ́, ìwọ tó ń gbé àfonífojì,*

Ìwọ àpáta tó wà ní ilẹ̀ tó tẹ́jú,’ ni Jèhófà wí.

‘Ní ti ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ pé: “Ta ló lè wá bá wa jà?

Ta ló sì lè ya wọnú àwọn ibùgbé wa?”

14 Màá mú kí ẹ jíhìn

Gẹ́gẹ́ bí ìṣe yín,’+ ni Jèhófà wí.

‘Màá dáná sun igbó rẹ̀,

Á sì jó gbogbo ohun tó yí i ká run.’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́