Fi Ayọ̀ Múra Sílẹ̀ De Ìrántí Ikú Kristi
1. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ wo la máa ní nígbà Ìrántí Ikú Kristi?
1 Lọ́jọ́ Tuesday, March 26, tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi, a máa láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti fi ayọ̀ ọkàn wa hàn bá a ti ń ronú ètò tí Ọlọ́run ṣe láti gbà wá là. (Aísá. 61:10) Tá a bá jẹ́ kí ayọ̀ kún ọkàn wa kó tó di ọjọ́ yẹn, èyí á jẹ́ ká lè túbọ̀ múra sílẹ̀ dáadáa. Ọ̀nà wo la lè gbà múra sílẹ̀?
2. Kí nìdí tá a fi máa ń múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?
2 Bá A Ṣe Lè Múra Sílẹ̀: Ìrántí Ikú Kristi ṣe pàtàkì gan-an, àmọ́ kò la ariwo lọ. Síbẹ̀, ó máa ń nílò pé ká ṣe àwọn ètò tó yẹ ṣáájú àkókò, ká má bàa gbójú fo àwọn ohun tó dà bíi pé kò tó nǹkan àmọ́ tó ṣe pàtàkì. (Òwe 21:5) Ó yẹ ká yan àkókò àti ibi tá a ti máa ṣe é. Ká sì ṣètò bá a ṣe fẹ́ rí àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tó yẹ ká lò. Ó yẹ ká tún ibi tá a máa lò ṣe, kó sì wà ní mímọ́ tónítóní. Kí olùbánisọ̀rọ̀ múra sílẹ̀ dáadáa. Kí àwọn tó máa gbé ohun ìṣàpẹẹrẹ àtàwọn tó ń bójú tó èrò sì ṣe iṣẹ́ wọn létòletò. Ó dájú pé a ti ń ṣètò ọ̀pọ̀ àwọn ohun tá a sọ yìí. Ìdí tá a fi máa ń múra sílẹ̀ ni pé a mọyì ìràpadà, a sì ń láyọ̀ nítorí ètò tí Ọlọ́run ṣe láti gbà wá là.—1 Pét. 1:8, 9.
3. Báwo la ṣe lè múra ọkàn wa sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?
3 Múra Ọkàn Rẹ Sílẹ̀: Ó tún ṣe pàtàkì pé ká múra ọkàn wa sílẹ̀ ká lè lóye ìjẹ́pàtàkì Ìrántí Ikú Kristi dáadáa. (Ẹ́sírà 7:10) Torí náà, ó yẹ ká wá àyè láti ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ètò Ọlọ́run ní kí a kà lásìkò Ìrántí Ikú Kristi. Ká sì ṣàṣàrò lórí àwọn ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé. Èyí á jẹ́ ká lè túbọ̀ mọyì ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí Jésù ní, yóò sì mú kí àwa náà lè fara wé e.—Gál. 2:20.
4. Èwo nínú àwọn ìbùkún tí ìràpadà mú wá ló ń fún ọ láyọ̀ jù lọ?
4 Ikú ìrúbọ Kristi fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Ó gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (1 Jòh. 2:2) Ó jẹ́ ká lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó sì jẹ́ ká lè ní ìrètí ìyè ayérayé. (Kól. 1:21, 22) Ó tún jẹ́ ká lè rọ̀ mọ́ ìpinnu tá a ṣe nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà tá a sì di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. (Mát. 16:24) Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ fi ayọ̀ kún ọkàn wa bá a ti ń múra sílẹ̀, tá a sì ń ṣètò láti péjú pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ṣe lọ́dún yìí!