Ṣé Ò Ń Múra Sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?
Ohun kan ṣẹlẹ̀ ní Nísàn 13 ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Jésù mọ̀ pé alẹ́ kan ṣoṣo ló kù tí òun á fi wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ òun tímọ́tímọ́ kí wọ́n tó pa òun. Ó máa ṣe Ayẹyẹ Ìrékọjá tó kẹ́yìn pẹ̀lú wọn, ó sì máa dá ohun kan tí wọ́n á máa rántí sílẹ̀, ìyẹn Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Ó dájú pé wọ́n ní láti múra sílẹ̀ dáadáa fún ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí. Torí náà, ó rán Pétérù àti Jòhánù pé kí wọ́n lọ ṣètò àwọn nǹkan tí wọ́n máa lò sílẹ̀. (Lúùkù 22:7-13) Látìgbà yẹn ló ti jẹ́ pé ọdọọdún làwọn Kristẹni tó fẹ́ ṣe Ìrántí Ikú Kristi ti kà á sí ohun pàtàkì pé kí wọ́n máa múra sílẹ̀ fún ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. (Lúùkù 22:19) Àwọn nǹkan pàtó wo la lè ṣe láti múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ṣe ní April 3?
Ìmúrasílẹ̀ Tí Gbogbo Wa Máa Ṣe:
Ṣètò láti kópa dáadáa nínú pípín ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi.
Ṣàkọsílẹ̀ orúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ, àwọn ìbátan rẹ, àwọn ọmọ iléèwé rẹ, àwọn ará ibiṣẹ́ rẹ àtàwọn míì tó o bá mọ̀, kó o sì pè wọ́n wá.
Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a máa ń kà lákòókò Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì ṣàṣàrò lé wọn lórí.
Wá síbi Ìrántí Ikú Kristi kó o sì kí àwọn àlejò káàbọ̀.