Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 9
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 9
Orin 44 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 21 ìpínrọ̀ 9 sí 15 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 1-4 (8 min.)
No. 1: 1 Sámúẹ́lì 2:30-36 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí Ni Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà?—igw ojú ìwé 10 (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Jésù Fi Jẹ́ Olórí Aṣojú àti Aláṣepé Ìgbàgbọ́ Wa—Héb. 12:2 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “Gbára Dì fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo.”—Títù 3:1.
10 min: “Gbára Dì fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo.” Àsọyé tó dá lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí. Ka Òwe 21:5, Títù 3:1 àti 1 Pétérù 3:15, kó o sì ṣàlàyé rẹ̀. Sọ àǹfààní táwa Kristẹni máa ń rí tá a bá múra sílẹ̀ dáadáa. Ní ṣókí, mẹ́nu ba àwọn apá kan nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ ìsìn ti oṣù yìí, kó o sì sọ bí wọ́n ṣe tan mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí.
10 min: Fọ̀rọ̀ Wá Ọ̀rọ̀ Wò Lẹ́nu Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kí ni ojúṣe yín gẹ́gẹ́ bí Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Báwo lẹ ṣe máa ń múra sílẹ̀ láti darí ilé ẹ̀kọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀? Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ máa múra iṣẹ́ wọn sílẹ̀ dáadáa? Báwo ló ṣe máa ṣe àwọn ará láǹfààní tí wọ́n bá ń ka àwọn ohun tá a máa jíròrò sílẹ̀ kí wọ́n tó wá sípàdé?
10 min: “Ṣé Ò Ń Múra Sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?” Ìjíròrò. Ní ṣókí, sọ ohun tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 2013, ojú ìwé 2. Ṣé àṣefihàn bí akéde kan ṣe ń kí àlejò tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi káàbọ̀.
Orin 8 àti Àdúrà