Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 16
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 16
Orin 65 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 21 ìpínrọ̀ 16 sí 21, àti àpótí tó wà lójú ìwé 217 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 5-9 (8 min.)
No. 1: 1 Sámúẹ́lì 6:10-21 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ẹ̀kọ́ Wo La Lè Rí Kọ́ Látinú Àpẹẹrẹ Àwọn Ọmọbìnrin Sélóféhádì?—Núm. 36:10-12 (5 min.)
No. 3: Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà Tó Ṣẹ sí Jésù Lára—igw ojú ìwé 11 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “Gbára Dì fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo.”—Títù 3:1.
10 min: Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—ní Taiwan. Ìjíròrò tó dá lórí àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ October 15, 2014, ojú ìwé 3 sí 6. Báwo ni àwọn akéde tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ náà ṣe múra láti lọ sí orílẹ̀-èdè míì? Àwọn ìbùkún wo ni wọ́n rí?
20 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Wá Àwọn Tí Wàá Máa Fún Ní Ìwé Ìròyìn Déédéé.” Ìjíròrò. Lẹ́yìn tí ẹ bá ti jíròrò àpilẹ̀kọ náà, ṣe àṣefihàn bí akéde kan ṣe ń fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹnì kan tó máa ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé. Lẹ́yìn náà, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tó ní àwọn tó máa ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé. Mélòó ni wọ́n? Báwo ló ṣe máa ń múra sílẹ̀ nígbà tó bá fẹ́ lọ sọ́dọ̀ wọn? Ní kó sọ ìrírí kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó ní.
Orin 101 àti Àdúrà