Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 11
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 11
Orin 68 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 6 ìpínrọ̀ 13 sí 18 àti àpótí tó wà lójú ìwé 74 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Máàkù 13-16 (10 min.)
No. 1: Máàkù 14:22-42 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀ sí Ẹ̀mí Mímọ́?—td 15E (5 min.)
No. 3: Kí Ni Ọkàn?—td 40A (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ka Mátíù 10:7-10 àti Lúùkù 10:1-4. Kẹ́ ẹ sì jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè wúlò fún wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
10 min: Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I—Apá Kìíní. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 111, ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 112, ìpínrọ̀ 2. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n ti ṣí lọ sí àgbègbè míì tàbí tí wọ́n kọ́ èdè tuntun kí wọ́n lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i. Àwọn ìṣòro wo ni wọ́n ti borí? Kí ni ìdílé wọn tàbí ìjọ ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́? Àwọn ìbùkún wo ni wọ́n ti rí?
10 min: “Fi Ayọ̀ Múra Sílẹ̀ De Ìrántí Ikú Kristi.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Sọ ètò tí ìjọ ṣe nípa Ìrántí Ikú Kristi. Sọ àwọn ibi tẹ́ ẹ ti pín ìwé ìkésíni dé àtàwọn ibi tó kù.
Orin 8 àti Àdúrà