Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Inú wa dùn láti sọ fún yín pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ó lé mẹ́rìnlélógójì, ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti méjìlélógójì [344,342] akéde ló ròyìn lóṣù August ọdún 2012. A ò tíì ní iye akéde tó pọ̀ tó báyìí rí. Èyí fi ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá ó lé mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [14,026] ju iye akéde tó ròyìn lóṣù August ọdún 2011 lọ. Iye wákàtí táwọn akéde yìí lò jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́fà, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà àti irínwó ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n [6,120,428]. Èyí fi hàn pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti méjìlá, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé méje [512,607] ni iye wákàtí tí wọ́n lò fi ju ti oṣù August ọdún 2011 lọ. Ó ṣe kedere pé ẹ̀mí Jèhófà túbọ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti tan ìhìn rere náà kálẹ̀.—Ìṣe 1:8; 9:31.