ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/07 ojú ìwé 1
  • “Ẹ Máa Ṣe Èyí Ní Ìrántí Mi”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Máa Ṣe Èyí Ní Ìrántí Mi”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Máa Ṣe Èyí”—April 5 La Máa Ṣe Ìrántí Ikú Kristi
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Jèhófà Máa Ń Bù Kún Wa Tá A Bá Ṣe Ìrántí Ikú Kristi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Jọlá Ẹbọ Ìràpadà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ìdí Tá A Fi Ń Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 3/07 ojú ìwé 1

“Ẹ Máa Ṣe Èyí Ní Ìrántí Mi”

Ọjọ́ Kejì Oṣù Kẹrin, Ọdún 2007 La Ó Ṣe Ìrántí Ikú Jésù

1. Kí nìdí tí ọjọ́ kejì oṣù kẹrin, ọdún 2007 fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀?

1 Ní ọjọ́ kejì oṣù kẹrin, ọdún 2007, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn káàkiri ayé á pé jọ láti ṣèrántí kíkú tí Jésù kú ikú ìrúbọ. Ikú tí Jésù kú yìí, látàrí pé ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Bàbá òun tó wà lọ́run ni ọba láyé àtọ̀run, jẹ́ ẹ̀rí pé irọ́ ni Sátánì pa mọ́ aráyé pé wọn ò lè sin Ọlọ́run bí wọn ò bá máa rí nǹkan gbà lọ́wọ́ Ẹ̀. (Jóòbù 2:1-5) Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tún máa ń rán wa létí pé fífi ti Jésù tí kò dẹ́ṣẹ̀ rí, tó jẹ́ ẹni pípé, fi ara rẹ̀ rúbọ, túmọ̀ sí pé ó “fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mát. 20:28) Nítorí náà, Jésù pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Ǹjẹ́ bó o ṣe mọrírì ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye yìí á mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò láti wà níbi ìrántí ìfẹ́ tó jinlẹ̀ jù lọ tí Ọlọ́run fi hàn sí wa yìí?—Jòhánù 3:16.

2. Báwo la ṣe lè múra ọkàn wa sílẹ̀ de Ìrántí Ikú Kristi?

2 Múra Ọkàn Rẹ Sílẹ̀: Bá a bá ń gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ mélòó kan tí Jésù lò kẹ́yìn láyé yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan, ó lè mú ká múra ọkàn wa sílẹ̀ de Ìrántí Ikú Kristi tó ń bọ̀ lọ́nà yìí. (Ẹ́sírà 7:10) Kó bàa lè rọrùn láti múra ọkàn wa sílẹ̀, a ti fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ tá a dìídì ṣe fún Bíbélì kíkà lákòókò Ìrántí Ikú Kristi sínú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ ti ọdún 2007, ó sì tún wà nínú Kàlẹ́ńdà ti ọdún 2007. Àwọn ibi tá a ṣètò fún kíkà yìí bá ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín ọjọ́ mélòó kan tí Jésù lò kẹ́yìn láyé mu. A fi ọjọ́ táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà bọ́ sí lákòókò tiwa hàn nínú kàlẹ́ńdà náà. Kàlẹ́ńdà àwọn Júù la gbé àwọn ọjọ́ àti déètì tí Bíbélì tọ́ka sí kà, ńṣe ni kàlẹ́ńdà náà máa ń bẹ̀rẹ̀ sí i ka ọjọ́ kan látìgbà tí oòrùn bá ti wọ̀ lọ́jọ́ kan títí dìgbà tí oòrùn bá wọ̀ lọ́jọ́ kejì. A ti ro gbogbo ìyẹn náà mọ́ ọn ká tó ṣètò Bíbélì kíkà lákòókò Ìrántí Ikú Kristi. Bó o bá ka àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn tán, tó o sì gbàdúrà kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàṣàrò nípa bí ìfẹ́ tí Ọlọ́run fi hàn sí wa ṣe jinlẹ̀ tó, á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jàǹfààní Ìrántí Ikú Kristi náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.

3. Báwo la ṣe lè ran àwọn olùfìfẹ́hàn àtàwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní látinú Ìrántí Ikú Kristi?

3 Pe Àwọn Míì Wá: Àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February ṣe ìfilọ̀ pé a ó ṣe àkànṣe ìpínkiri kan láti pe àwọn èèyàn síbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí. Ṣó o ti ṣètò tó yẹ kó o bàa lè kópa tó kún rẹ́rẹ́ nínú àkànṣe ìpínkiri yìí? Ǹjẹ́ o ti kọ orúkọ àwọn tó o fẹ́ pè sínú àkọsílẹ̀ rẹ, ṣó o sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún wọn? Ṣe ohun tó yẹ láti rí i pé o tètè dé síbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn láti lè kí àwọn tó o pè àtàwọn míì tó bá wá káàbọ̀. O lè jẹ́ kí wọ́n jókòó tì ẹ́, kó o sì rí i pé wọ́n ní Bíbélì àti ìwé orin lọ́wọ́. Fi wọ́n han àwọn ará míì nínú ìjọ. Bí ètò ọjọ́ náà bá ti parí, fi àkókò sílẹ̀ láti dáhùn ìbéèrè wọn. Ní kí wọ́n wá gbọ́ àkànṣe àsọyé tó máa wáyé ní April 15. Ó ṣe pàtàkì káwọn alàgbà pe àwọn tí wọ́n ti ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ nígbà kan àmọ́ tí wọ́n ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ síbi Ìrántí Ikú Kristi, kí wọ́n sì tún pè wọ́n láti wá gbọ́ àkànṣe àsọyé náà.

4. Lẹ́yìn Ìrántí Ikú Kristi, báwo la ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa tẹ̀ síwájú nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run?

4 Ran Àwọn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Ń Fìfẹ́ Hàn Àtàwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Tẹ̀ Síwájú: Ẹni tó bá sọ àsọyé níbi Ìrántí Ikú Kristi á ṣàlàyé ṣókí nípa bá a ṣe máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, á sì gba àwọn ẹni tuntun níyànjú láti máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà. O lè lo àlàyé tí alásọyé bá ṣe láti jẹ́ kó mọ bó ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i nípa Jèhófà. Bí ẹni tuntun náà ò bá tíì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, rí i pé o ò jáfara láti tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ọjọ́ yẹn, kó o sì fi bá a ṣe máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ hàn án. Jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ pé òun ní láti máa wá sí ìpàdé ìjọ kó bàa lè ní ìmọ̀ kún ìmọ̀, kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run sì lè jinlẹ̀ sí i. (Heb. 10:24, 25) Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa wá sípàdé déédéé. Káwọn alàgbà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ tí wọ́n bá wá síbi Ìrántí Ikú Kristi, kí wọ́n sì bá wọn jíròrò àwọn kókó díẹ̀ tí àsọyé Ìrántí Ikú Kristi náà dá lé lórí. Ó ṣeé ṣe kíyẹn fún wọn níṣìírí láti padà sí í ṣe déédéé nínú ìjọ.

5. Àǹfààní wo ni Ìrántí Ikú Kristi lè ṣe wá?

5 Ìrántí Ikú Kristi máa ń jẹ́ ká ráyè ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí Jèhófà àti Jésù ti ṣe nítorí wa. Irú àṣàrò bẹ́ẹ̀ máa ń mú kí ìfẹ́ tá a ní fún àwọn méjèèjì jinlẹ̀ sí i, ó sì máa ń jẹ́ ká lè máa hùwà rere. (2 Kọ́r. 5:14, 15; 1 Jòh. 4:11) Àkókò ti tó báyìí fáwa àtàwọn olùfìfẹ́hàn wa láti bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ fún ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí, ìyẹn ìṣẹ̀lẹ̀ tá a fi “ń pòkìkí ikú Olúwa, títí yóò fi dé.”—1 Kọ́r. 11:26.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́