ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/07 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 12
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 19
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 26
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 2
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 3/07 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 12

Orin 153

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù March sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ March 15 àti Jí! January-March. (Lo àbá kẹta lójú ewé 4 fún Jí! January-March) Rán àwọn akéde létí pé March 17 ni àkànṣe ìpínkiri láti pe àwọn èèyàn síbi Ìrántí Ikú Kristi máa bẹ̀rẹ̀.

15 min: Nígbà Tí Èèyàn Wa Kan Bá Fi Jèhófà Sílẹ̀. Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí, kó sì gbé e ka Ilé Ìṣọ́ September 1, 2006, ojú ìwé 17 sí 21.

20 min: “Ẹ Máa Ṣe Èyí Ní Ìrántí Mi.”a Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, fi àlàyé kún un látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù March ọdún 2006, ojú ìwé 1, ìpínrọ̀ 3, èyí tó sọ bá a ṣe lè lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni láti ṣàlàyé Ìrántí Ikú Kristi fáwọn olùfìfẹ́hàn tá a bá pè.

Orin 168 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 19

Orin 45

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Jíròrò àwọn kókó tó wà nínú àpótí lójú ìwé 3, èyí tá a pè ní “Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Ìrántí Ikú Kristi.”

20 min: Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, orí 10.

15 min: “Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?”b Ṣe àṣefihàn ṣókí tó máa jẹ́ kí àwùjọ rí bá a ṣe lè máa mú àpilẹ̀kọ yìí wọnú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.

Orin 216 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 26

Orin 115

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù March sílẹ̀. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ April 1 àti Jí! January-March, pẹ̀lú àkànṣe ìwé ìkésíni tá a fi ń pe àwọn èèyàn síbi Ìrántí Ikú Kristi. (Lo àbá kẹrin lójú ìwé 4 fún Jí! January-March.)

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: Báwo Ni Kí N Ṣe Lo Ìgbésí Ayé Mi? Àsọyé tá a gbé ka Jí! ti July-September 2006, ojú ìwé 16 sí 18. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan tàbí méjì tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lẹ́yìn tí wọ́n jáde nílé ẹ̀kọ́ girama. Kí nìdí tí wọ́n fi yàn láti ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún? Àǹfààní wo ni wọ́n ti rí níbẹ̀?

Orin 148 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 2

Orin 177

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Jíròrò ìkésíni tó wà lẹ́yìn Ilé Ìṣọ́ April 1, 2007, kó o sì gba àwọn akéde níyànjú láti pe àwọn olùfìfẹ́hàn wá síbi àkànṣe àsọyé tá a máa gbọ́ ní April 15.

20 min: Ẹ Máa Bá A Nìṣó Láti Máa Ran Àwọn Tó Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Lọ́wọ́. Alàgbà ni kó sọ ọ́ bí àsọyé. Sọ iye àwọn tó pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún yìí, kó o sì sọ àròpọ̀ iye tó ṣeé ṣe káwọn olùfìfẹ́hàn tó wá jẹ́. Sọ ìrírí tó tayọ tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn tó gba ìwé tá a fi pe àwọn èèyàn síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún yìí, bá a bá sì rí lára àwọn olùfìfẹ́hàn tó wá tí wọ́n sọ fáwọn olùbójútó èrò pé àwọn nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mẹ́nu kàn án. Sọ àwọn àbá táwọn akéde lè mú lò láti ran àwọn tó wá lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè túbọ̀ mọ̀ sí i nípa Jèhófà. (Wo km-YR 3/06, ojú ìwé 1, ìpínrọ̀ 5; km-YR 2/05, ojú ìwé 4, ìpínrọ̀ 9; km-YR 2/04, ojú ìwé 5, ìpínrọ̀ 16.) Gba àwọn akéde níyànjú láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn ní kíá mọ́sá.

15 min: Ẹ Lo Ìwé Ọdọọdún Wa, ìyẹn 2007 Yearbook Lọ́nà Rere. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Jíròrò àwọn kókó afúnniníṣìírí tó wà nínú “Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí.” Tẹnu mọ́ àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ìròyìn kárí ayé, ìyẹn “Worldwide Report.” Kó tó di ọjọ́ tóó máa ṣe iṣẹ́ yìí ní ìjọ yín, sọ fáwọn akéde mélòó kan pé kí wọ́n múra sílẹ̀ láti sọ lára ìròyìn àti ìrírí tó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára tó wà lábẹ́ ìròyìn kárí ayé, ìyẹn “Worldwide Report.” Gba àwọn ìdílé níyànjú láti bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìwé náà díẹ̀díẹ̀ títí tí wọ́n á fi kà á tán láàárín ọdún yìí. Mẹ́nu ba àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fi ìwé náà mú káwọn ẹni tuntun wá sínú ètò Jèhófà àti bá a ṣe lè fi fún wọn níṣìírí kí wọ́n lè máa wá sípàdé.

Orin 179 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́