ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/06 ojú ìwé 1
  • Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Jọlá Ẹbọ Ìràpadà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Jọlá Ẹbọ Ìràpadà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Lílọ sí Ìpàdé Ń Sọ Nípa Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • “Ẹ Máa Ṣe Èyí”—April 5 La Máa Ṣe Ìrántí Ikú Kristi
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Ẹ Jẹ́ Ká Fi Ìmọrírì Wa Hàn​—April 17 La Máa Ṣe Ìrántí Ikú Kristi
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Jèhófà Máa Ń Bù Kún Wa Tá A Bá Ṣe Ìrántí Ikú Kristi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 3/06 ojú ìwé 1

Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Jọlá Ẹbọ Ìràpadà

A Ó Ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní April 12

1. Ọ̀nà wo làwa èèyàn Ọlọ́run gbà ń fi ẹ̀mí ìmoore hàn nítorí ẹbọ ìràpadà?

1 “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run fún ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ aláìṣeé-ṣàpèjúwe.” (2 Kọ́r. 9:15) Wẹ́kú lọ̀rọ̀ yìí ṣe pẹ̀lú ojú tá a fi ń wo oore tí Ọlọ́run ṣe fáwa èèyàn rẹ̀ àti inú rere onífẹ̀ẹ́ tó fi hàn sí wa nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi. A óò túbọ̀ fi irú ẹ̀mí ìmoore yìí hàn lákànṣe nígbà tá a bá pé jọ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní April 12.

2. Àwọn wo ló bá àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lọ síbi Ìrántí Ikú Jésù, kí sì lohun tó yẹ kí wọ́n ṣe kí wọ́n tó lè jọlá ẹbọ ìràpadà náà?

2 Àwọn èèyàn tó tó mílíọ̀nù mẹ́wàá ni wọ́n máa ń pé jọ síbi Ìrántí Ikú Kristi pẹ̀lú àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́dọọdún. Bí wọ́n ṣe ń bá wa pé jọ yìí, ṣe ni wọ́n ń fi ẹ̀mí ìmoore hàn fún ẹbọ ìràpadà Kristi. Ṣùgbọ́n, kí wọ́n tó lè jọlá ẹbọ ìràpadà náà, wọ́n gbọ́dọ̀ fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Jòh. 3:16, 36) Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti nírú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀? Lákòókò Ìrántí Ikú Kristi yìí, a lè gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n sì máa wá sí ìpàdé ìjọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ìwọ wo àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí.

3. Ọ̀nà wo la lè gbà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tá a bá ń pe àwọn èèyàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi?

3 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: Bó o bá pe àwọn olùfìfẹ́hàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi, o ò ṣe kúkú gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ sí fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́? Sọ fún ẹni náà pé o fẹ́ ṣàlàyé ohun tí Ìrántí Ikú Kristi túmọ̀ sí fún un, kó o wá ṣí ìwé náà sí ojú ìwé 206 sí 208, kẹ́ ẹ sì jíròrò àkòrí náà, “Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa—Ìrántí Ikú Kristi Tá A Ń Ṣe Láti Bọlá fún Ọlọ́run.” Bó o bá fẹ́, o lè jíròrò àlàyé tó wà níbẹ̀ tán lẹ́ẹ̀kan tàbí nígbà tó o bá padà lọ lẹ́ẹ̀kejì, bóyá nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì orí ìdúró. Ìgbà tẹ́ ẹ bá fi máa parí ìjíròrò lórí kókó yẹn, ó ṣeé ṣe kẹ́ni náà fẹ́ kẹ́ ẹ jíròrò orí 5 tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Ìràpadà—Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fúnni.” Lẹ́yìn tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́ ẹ̀ ń ṣe náà bá ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, ẹ padà lọ ka orí mẹ́rin tó bẹ̀rẹ̀ ìwé náà.

4. Ta la lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lákòókò Ìrántí Ikú Kristi yìí?

4 Ta la lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà yìí? O lè bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn tẹ́ ẹ jọ wà nílé ìwé, tàbí àwọn aládùúgbò rẹ tó bá nífẹ̀ẹ́ sí irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀. Àwọn arákùnrin lè lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yẹn láti kọ́ ọkọ tí kì í ṣe ajẹ́rìí, àmọ́ tí ìyàwó ẹ̀ wà nínú òtítọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Má sì ṣe gbàgbé láti lò ó fún àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tí wọ́n kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Láfikún sí i, ó yẹ ká sapá gan-an láti pe àwọn tí wọ́n ń ṣe déédéé nínú ìjọ nígbà kan rí wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. (Lúùkù 15:3-7) Ǹjẹ́ ká ṣe ohun tó bá yẹ láti ran gbogbo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè jọlá ẹbọ ìràpadà náà.

5. Báwo la ṣe lè gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn olùfìfẹ́hàn níyànjú láti máa wá sí àwọn ìpàdé ìjọ tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀?

5 Àwọn Ìpàdé Ìjọ: Ibi Ìrántí Ikú Kristi ni ìpàdé àkọ́kọ́ tí ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn olùfìfẹ́hàn mìíràn máa ń kọ́kọ́ wá. Síbẹ̀, báwo la ṣe lè gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n wá jàǹfààní àwọn ìpàdé tó kù? Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti April 2005, ojú ìwé 8 dábàá yìí, ó ní: “Jẹ́ kí wọ́n mọ àkòrí àsọyé fún gbogbo èèyàn tẹ́ ẹ máa gbọ́ nípàdé lọ́sẹ̀ yẹn. Fi àpilẹ̀kọ tá a máa kà lọ́sẹ̀ náà nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti ibi tá a máa kà nínú ìwé tá à ń lò ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ hàn wọ́n. Ṣàlàyé fún wọn nípa Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Tó o bá ní iṣẹ́ nínú ìpàdé ilé ẹ̀kọ́, kò burú tó o bá fi dánra wò lójú wọn. Sọ àwọn kókó pàtàkì tó o gbọ́ rí láwọn ìpàdé fún wọn. Fi àwòrán tó wà nínú àwọn ìwé wa hàn wọ́n kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fọkàn yàwòrán bí ìpàdé wa ṣe máa ń rí. Ọjọ́ tó o bá kọ́kọ́ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ni kó o ti fi ìpàdé lọ̀ wọ́n.”

6. Ọ̀nà méjì wo la lè gbà ran àwọn ọlọ́kàn rere lọ́wọ́ láti jọlá ẹbọ ìràpadà?

6 Bá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ọlọ́kàn rere déédéé tí wọ́n sì ń wá sí ìpàdé ìjọ déédéé, wọ́n máa ń tètè lóye ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa gba àwọn ẹlòmíràn níyànjú láti lè rí Ìrántí Ikú Kristi yìí bí àǹfààní tó máa jẹ́ kí wọ́n lè jọlá ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye jù lọ tí Ọlọ́run fi ta wá lọ́rẹ, ìyẹn ẹbọ ìràpadà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́