Ẹ Jẹ́ Ká Fi Ìmọrírì Wa Hàn—April 17 La Máa Ṣe Ìrántí Ikú Kristi
1. Ọ̀rọ̀ onísáàmù wo ló bá àkókò Ìrántí Ikú Kristi mu gẹ́lẹ́?
1 Ìmọrírì tí onísáàmù náà ní fún àánú tí Jèhófà fi hàn àti bó ṣe ń dá àwọn èèyàn nídè, mú kó béèrè pé: “Kí ni èmi yóò san padà fún Jèhófà nítorí gbogbo àǹfààní tí mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀?” (Sm 116:12) Lóde òní, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní ìdí tó pọ̀ láti fi ìmọrírì hàn. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀, Jèhófà fún ìran èèyàn ni ẹ̀bùn tó tóbi jù lọ, ìyẹn ni ìràpadà. Bá a ṣe ń múra sílẹ̀ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní April 17, a ní ìdí láti fi hàn pé a mọ ọpẹ́ dá.—Kól. 3:15.
2. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìdí tá a fi mọrírì ìràpadà?
2 Àwọn Ìbùkún Tá A Rí Nípasẹ̀ Ìràpadà: Ìràpadà ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti rí “ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa” gbà. (Kól. 1:13, 14) Èyí ló jẹ́ ká lè máa fi ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ sin Jèhófà. (Héb. 9:13, 14) A lè ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lọ́dọ̀ Jèhófà tá a bá tọ̀ ọ́ lọ nínú àdúrà. (Héb. 4:14-16) Àwọn tó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà náà ní ìrètí láti wà láàyè títí láé!—Jòh. 3:16.
3. Báwo la ṣe lè fi ìmọrírì wa hàn fún Jèhófà nítorí ìràpadà náà?
3 Fi Ìmọrírì Hàn: Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi ìmọrírì wa hàn ni pé ká máa ka ẹsẹ Bíbélì tá a yàn fún àkókò Ìrántí Ikú Kristi lójoojúmọ́, ká sì máa ṣàṣàrò lé e lórí. A ṣe àpilẹ̀kọ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ṣé Ò Ń Múra Sílẹ̀ fún Ọjọ́ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ọdún?” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ February 1, 2011, láti ràn wá lọ́wọ́. A tún lè sọ bá a ṣe mọyì ìràpadà náà tó fún Jèhófà nínú àdúrà wa. (1 Tẹs. 5:17, 18) Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà fi hàn pé a mọ ọpẹ́ dá ni pé ká pésẹ̀ síbi tá a ti máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní ìgbọràn sí àṣẹ tí Jésù pa fún wa. (1 Kọ́r. 11:24, 25) Síwájú sí i, a tún lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ Jèhófà tí kò láàlà, nípa kíké sí àwọn èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó láti wá pé jọ pẹ̀lú wa.—Aísá. 55:1-3.
4. Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?
4 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó mọrírì kò kàn ní wo Ìrántí Ikú Kristi gẹ́gẹ́ bí ìpàdé mìíràn kan ṣá. Òun ni ìpàdé tó ṣe pàtàkì jù lọ lọ́dún! Bí ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi ṣe ń sún mọ́lé, ǹjẹ́ kí ìpinnu wa dà bíi ti onísáàmù náà tó kọ̀wé pé: “Fi ìbùkún fún Jèhófà, ìwọ ọkàn mi, Má sì gbàgbé gbogbo ìgbòkègbodò iṣẹ́ rẹ̀.”—Sm. 103:2.