Máa Fi Ìmọrírì Ronú Lórí Ìràpadà
1, 2. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi ìmọrírì ṣèrántí ikú Kristi?
1 Ní ìgbọràn sí àṣẹ tí Jésù pa, kárí ayé làwa Kristẹni yóò ti pàdé pọ̀ lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní Sátidé March 22 ọdún 2008, láti ṣe ìrántí ikú Jésù Kristi. (Lúùkù 22:19; 1 Kọ́r. 11:23-26) Ìmọrírì jíjinlẹ̀ tá a ní fún ohun ribiribi tí Jésù ṣàṣeparí rẹ̀ ní ẹgbàá-dín-márùndínlọ́gbọ̀n [1,975] ọdún sẹ́yìn ló máa mú ká ṣèrántí rẹ̀. Bí Jésù ò ṣe yẹhùn títí tó fi kú ikú oró lórí òpó igi, dá orúkọ Baba rẹ̀ láre, ó sì tún tipa báyìí fèsì ẹ̀gàn Sátánì lọ́nà tó dára jù lọ.—Jóòbù 1:11; Òwe 27:11.
2 Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí Jésù fi rúbọ ló fìdí májẹ̀mú tuntun múlẹ̀, ó sì ṣínà fáwọn èèyàn aláìpé láti di àwọn tí Ọlọ́run sọ dọmọ tí wọ́n sì nírètí láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba rẹ̀ lọ́run. (Jer. 31:31-34; Máàkù 14:24) Síwájú sí i, bí Jésù alára ṣe ṣàlàyé fún Nikodémù gan-an lọ̀rọ̀ rí, pé bí Ọlọ́run ṣe yọ̀ǹda Ọmọ rẹ̀ ààyò láti wá kú ikú ìrúbọ fi bí ìfẹ́ rẹ̀ fún èèyàn ṣe pọ̀ tó hàn.—Jòh. 3:16.
3. Báwo làwọn tó bá wá síbi Ìrántí Ikú Kristi ṣe máa jàǹfààní?
3 Pe Àwọn Míì Wá: Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù January dábàá pé ká kọ orúkọ àwọn ojúlùmọ̀ wa tá a fẹ́ pè ká sì rí i pé a sọ fún wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Ṣó o ti ń sọ fáwọn tó o kọ orúkọ wọn sílẹ̀? Ṣó o ti ń ṣètò tó máa jẹ́ kó o lè kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú ìkéde tó máa bẹ̀rẹ̀ ní March 1, láti pe àwọn èèyàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi? Àwọn tó bá wá máa gbọ́ ìsọfúnni látinú Ìwé Mímọ́, èyí sì lè mú kí wọ́n nígbàgbọ́ nínú ìràpadà, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ jogún ìyè àìnípẹ̀kun.—Róòmù 10:17.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká tètè dé síbi Ìrántí Ikú Kristi?
4 Kí gbogbo àwọn tó bá ṣeé ṣe fún ṣètò láti tètè dé kí wọ́n lè fi tẹ̀rín tọ̀yàyà kí gbogbo àwọn tó wá káàbọ̀. Nítorí pé àwọn tó máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi sábà máa ń pọ̀, ó ṣe pàtàkì pé ká pàfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀ sáwọn ẹni tuntun àtàwọn tó máa ń wá sáwọn ìpàdé wa lóòrèkóòrè.
5. Báwo lo ṣe lè múra ọkàn rẹ sílẹ̀ fún ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí?
5 Múra Ọkàn Rẹ Sílẹ̀: A ti dìídì ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní March 17 fún àsìkò Ìrántí Ikú Kristi sínú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ àti Kàlẹ́ńdà ọdún 2008. Tó o bá ṣàyẹ̀wò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, èyí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti múra ọkàn rẹ sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi. (Ẹ́sírà 7:10) Fífi tàdúràtàdúrà ronú lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí máa mú kó o túbọ̀ mọrírì ìfẹ́ tó mú kí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ pèsè ìràpadà fún wa.—Sm. 143:5.
6. Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú mímú kí ìmọrírì wa fún ìràpadà pọ̀ sí i?
6 Bí Ìrántí Ikú Kristi ti ń sún mọ́lé, ẹ jẹ́ ká múra ara wa sílẹ̀ dáadáa ká sì ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí. Fífi ìmọrírì ronú lórí ìràpadà máa fún àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ lókun. (2 Kọ́r. 5:14, 15) Èyí á sì mú káwa náà lè fara wé wọn nínú fífi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ hàn sáwọn ẹlòmíì.—1 Jòh. 4:11.