Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 11
Orin 168
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù February sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ February 1 àti Jí! January-March. (Lo àbá kẹta lójú ìwé 8 fún Jí! January-March.)
15 min: Ṣó O Lè Lọ Sìn Níbí Tí Wọ́n Ti Nílò Àwọn Oníwàásù Púpọ̀ Sí I? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ July 15, 2003, ojú ìwé 20. Fi àlàyé kún un látinú ìwé A Ṣètò Wa ojú ìwé 111, ìpínrọ̀ 1, sí ojú ìwé 112, ìpínrọ̀ 1. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò ní ṣókí lẹ́nu ẹni tó ti lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Àwọn ìṣòro wo ni wọ́n dojú kọ, báwo ni wọ́n sì ṣe borí wọn? Àwọn ìbùkún wo ni wọ́n ti rí?
20 min: Ran Àwọn Ẹni Tuntun Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Tẹ̀ Síwájú Gẹ́gẹ́ bí Òjíṣẹ́. Lẹ́yìn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí kò tó ìṣẹ́jú kan, darí ìjíròrò látinú Ilé Ìṣọ́ December 1, 2005 ojú ìwé 31 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà ni kó o lò. Lẹ́yìn tó o bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 18, ṣe àṣefihàn bí onílé kan ṣe ń ta ko akéde tuntun kan tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú akéde tó ti nírìírí lóde ẹ̀rí. Akéde tuntun yẹn kò fèsì lọ́nà tó gbéṣẹ́, onílé yẹn bá lóun ò gbọ́ mọ́. Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò níbẹ̀, akéde tó ti nírìírí yẹn gbóríyìn fún akéde tuntun náà fún akitiyan rẹ̀, ó wá fi bó ṣe lè lo ìwé pẹlẹbẹ Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó dá àwọn tó bá fẹ́ bẹ́gi dínà ọ̀rọ̀ lóhùn hàn án.
Orin 50
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 18
Orin 17
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
25 min: “Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára Lèyí!”a Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí. Nígbà tó o bá fẹ́ mú ọ̀rọ̀ rẹ wá síparí, ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí ìjọ ti gbé ṣe lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, kó o sì sọ ọ́ lọ́nà tó ń gbéni ró.
Orin 194
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 25
Orin 81
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù February sílẹ̀. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Ṣàṣefihàn bá a ṣe lè fi ìwé ìkésíni pe àwọn mọ̀lẹ́bí wa tàbí aládùúgbò kan wá síbi Ìrántí Ikú Kristi.
20 min: “Máa Fi Ìmọrírì Ronú Lórí Ìràpadà.”b Bí àkókò bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.
15 min: Múra Sílẹ̀ Láti Fàwọn Ìwé Ìròyìn Tó Bá Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé Lọni. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Lẹ́yìn tó o bá ti ṣàkópọ̀ Ilé Ìṣó March 1 àti Jí! January-March ní ṣókí, ní káwọn ará sọ àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kó fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kí wọ́n sì sọ ìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀. Ní kí wọ́n mẹ́nu ba àwọn kókó kan látinú àwọn àpilẹ̀kọ tí wọ́n ní lọ́kàn láti lò lóde ẹ̀rí. Ìbéèrè wo ni wọ́n lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni wọ́n máa fẹ́ láti kà látinú àpilẹ̀kọ náà? Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ March 1 àti Jí! January-March lọni. (Lo àbá kẹrin lójú ìwé 8 fún Jí! January-March.)
Orin 119
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 3
Orin 223
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó pàtàkì látinú àpótí náà “Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Ìrántí Ikú Kristi.”
20 min: Ṣé Wàá Bẹ̀rẹ̀ Sí Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kan Lóṣù March? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Lóṣù March ìwé Bíbélì fi kọ́ni la máa fi ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, a sì máa fi ṣe àfojúsùn wa láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tó fani lọ́kàn mọ́ra tó wà nínú ìwé náà. Jíròrò bá a ṣe lè fi lọni nígbà tá a bá padà lọ bẹ ẹni tó fìfẹ́ hàn nígbà tá a fún un ní ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi wò, nígbà tá a bá lọ padà bẹ ẹni tó gba ìwé ìròyìn wò àti nígbà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé lẹ́yìn March 22. (Wo km-YR 8/07 ojú ìwé 3; km-YR 3/06 ojú ìwé 1, ìpínrọ̀ 3; km 3/06 ojú ìwé 3 sí 6.) Ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tàbí méjì.
15 min: Máa Lo Bíbélì Nígbà Tó O Bá Ń Dáhùn Ìbéèrè. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Jàǹfààní, ojú ìwé 143 sí 144. Ṣàṣefihàn ráńpẹ́ kan tó dá lórí bí akéde kan ṣe lo Bíbélì láti fi dáhùn ìbéèrè kan táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín.
Orin 145
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.