Fi Hàn Pé O Mọyì Ẹ̀bùn Ọlọ́run Tó Tóbi Jù Lọ
1. Kí ni ìdí pàtàkì tá a fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà?
1 Nínú gbogbo “ẹ̀bùn rere,” tí Ọlọ́run fún wa, Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n tó fi ṣe ìràpadà fún wa ni ẹ̀bùn tó tóbi jù lọ. (Ják. 1:17) Ọ̀pọ̀ ìbùkún ni ìràpadà yìí mú wá, títí kan ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. (Éfé. 1:7) A mọyì ẹ̀bùn yìí gan-an ni. Lákòókò Ìrántí Ikú Kristi, a máa ń fara balẹ̀ ṣàṣàrò nípa ẹ̀bùn tó ṣeyebíye yìí.
2. Gẹ́gẹ́ bí ìdílé àti lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, kí la lè ṣe tó máa jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ìràpadà náà?
2 Túbọ̀ Mọyì Ẹ̀bùn Yìí: Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé yín láwọn ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú March 30 tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi, a rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìsọfúnni nípa ìràpadà, èyí á jẹ́ kẹ́ ẹ lè túbọ̀ mọyì ẹ̀bùn yìí. Bákan náà, kẹ́ ẹ máa ka àwọn àkànṣe ẹsẹ Bíbélì tá a yàn fún àkókò Ìrántí Ikú Kristi lójoojúmọ́. Ronú nípa àǹfààní tí ìràpadà yẹn ṣe fún ẹ, bó ṣe nípa lórí ojú tó o fi ń wo Jèhófà, ojú tó o fi ń wo ara rẹ, ojú tó o fi ń wo àwọn ẹlòmíì àti èrò rẹ nípa ọjọ́ iwájú. Wàá rí i pé o tún máa jàǹfààní gan-an tó o bá lè fi àwọn orin tá a máa lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi dánra wò.—Sm. 77:12.
3. Báwo lá ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìràpadà náà?
3 Ẹ Fi Ìmoore Hàn: Bá a bá mọyì ìràpadà, èyí á mú ká máa sọ fáwọn èèyàn nípa Jèhófà àti ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tó fi hàn nípa rírán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé. (Sm. 145:2-7) Àwọn ìdílé kan máa ń ṣètò pé kí ẹnì kan, ó kéré tán, nínú ìdílé wọn ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù March, April àti May, láti fi hàn pé àwọn mọyì ìràpadà náà. Bí èyí ò bá ní ṣeé ṣe, ǹjẹ́ ẹ lè ‘ra àkókò pa dà’ kí ẹ lè túbọ̀ ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́? (Éfé. 5:16) Bá a bá mọyì ìràpadà yìí, èyí á tún jẹ́ ká ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. (Ìṣí. 22:17) A rọ̀ ẹ́ pé kó o bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkọsílẹ̀ orúkọ àwọn tó o máa pè wá. Àwọn bí ìpadàbẹ̀wò rẹ, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ, ìbátan rẹ, àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ àti àwọn aládùúgbò rẹ. Lẹ́yìn náà kópa kíkún nínú àkànṣe ètò tá a ṣe láti pín ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi.
4. Àwọn nǹkan tó bọ́gbọ́n mu wo la lè ṣe lákòókò Ìrántí Ikú Kristi?
4 Ìrántí Ikú Kristi máa ń fún wa láǹfààní láti jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a mọrírì ẹ̀bùn tó fún àwa èèyàn gan-an. Ǹjẹ́ ká lo àkókò yìí láti mú kí ìmọrírì wa pọ̀ sí i, ká sì fi hàn pé a mọyì ìràpadà náà àti “àwọn ọrọ̀ tí kò ṣeé díwọ̀n ti Kristi.”—Éfé. 3:8.