ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/14 ojú ìwé 2
  • Ṣé Wàá Lo Àǹfààní Yìí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Wàá Lo Àǹfààní Yìí?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fi Hàn Pé O Mọyì Ẹ̀bùn Ọlọ́run Tó Tóbi Jù Lọ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ẹ Jẹ́ Ká Fi Ìmọrírì Wa Hàn​—April 17 La Máa Ṣe Ìrántí Ikú Kristi
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • “Ẹ Máa Ṣe Èyí”—April 5 La Máa Ṣe Ìrántí Ikú Kristi
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • “Ìfẹ́ Tí Kristi Ní Sọ Ọ́ Di Dandan fún Wa”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
km 3/14 ojú ìwé 2

Ṣé Wàá Lo Àǹfààní Yìí?

Ìrántí Ikú Kristi Tó Ń Bọ̀ Máa Jẹ́ Ká Lè Fi Hàn Pé A Moore

1. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ wo la máa ní lákòókò Ìrántí Ikú Kristi?

1 Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ṣe ní April 14 máa jẹ́ ká túbọ̀ mọyì oore tí Jèhófà ṣe fún wa, ká sì ṣe ohun tó máa fi hàn pé a moore. Àkọsílẹ̀ tó wà nínú ìwé Lúùkù 17:11-18 jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà àti Jésù fi ń wo àwọn tó bá moore. Ẹnì kan ṣoṣo péré lára àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá tí Jésù wò sàn ló pa dà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Lọ́jọ́ iwájú, ẹ̀bùn ìràpadà máa wo gbogbo àìlera sàn, ó sì máa jẹ́ kí ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe! Ó dájú pé, ojoojúmọ́ la ó máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí àwọn ìbùkún yẹn. Àmọ́, kí la lè ṣe láwọn ọ̀sẹ̀ mélòó kan sígbà tá a wà yìí tó máa fi hàn pé a moore?

2. Kí la lè ṣe tó máa jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ìràpadà?

2 Ṣe Ohun Tó Máa Jẹ́ Kó O Moore: Àròjinlẹ̀ ló ń mú kéèyàn mọ ọpẹ́ dá. Ká lè túbọ̀ mọyì ìràpadà náà, a fi àkànṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì Kíkà fún àkókò Ìrántí Ikú Kristi sí àwọn ibi mélòó kan, a lè rí i nínú kàlẹ́ńdà, Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ àti nínú Àfikún Àlàyé B12 tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti ọdún 2013 lédè Gẹ̀ẹ́sì. Ẹ lè jíròrò rẹ̀ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Èyí máa jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ìràpadà gidigidi. Ó sì máa ṣe wá láǹfààní torí ó máa jẹ́ ká túbọ̀ máa hùwà tó dára.—2 Kọ́r. 5:14, 15; 1 Jòh. 4:11.

3. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe tó máa fi hàn pé a moore nígbà Ìrántí Ikú Kristi?

3 Fi Hàn Pé O Moore: Tá a bá ṣeni lóore, ọpẹ́ là ń dá. (Kól. 3:15) Adẹ́tẹ̀ tó mọyì oore tí Jésù ṣe fún un wá Jésù kàn kó lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Kò sí àní-àní pé ó máa fìtara sọ fáwọn èèyàn nípa bí Jésù ṣe wo òun sàn lọ́nà ìyanu. (Lúùkù 6:45) Ṣé báa ṣe mọyì ìràpadà máa mú ká fìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ká lè pe ọ̀pọ̀ èèyàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi? Ọ̀nà míì tó dára láti fi hàn pé a moore ni pé ká ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí ká kópa púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù lákòókò Ìrántí Ikú Kristi. Ní ìrọ̀lẹ́ tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi, a máa fẹ́ kí àwọn àlejò káàbọ̀, àá sì rí i pé a dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n bá ní torí pé tọkàntọkàn la mọyì oore tí Jésù ṣe fún wa yìí.

4. Kí la lè ṣe lákòókò Ìrántí Ikú Kristi tí a kò fi ní kábàámọ̀?

4 Ṣé Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí la máa ṣe kẹ́yìn? (1 Kọ́r. 11:26) A ò lè sọ. Àmọ́ ohun tá a mọ̀ ni pé tí àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tá a ní láti fi ìmọrírì hàn yìí bá ti bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, kò sí bá a ṣe lè rí i mọ́. Ṣé wàá lo àǹfààní yìí? Ǹjẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti àṣàrò ọkàn wa mú inú Jèhófà dùn, Ẹni tó fi tinútinú pèsè ìràpadà.—Sm. 19:14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́