Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 17
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 17
Orin 113 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 4 ìpínrọ̀ 10 sí 18 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 43-46 (10 min.)
No. 1: Jẹnẹ́sísì 44:18-34 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Hẹ́ẹ̀lì Kì Í Ṣe Ibi Ìdánilóró—td 16A (5 min.)
No. 3: Agbára Jésù Ju Ti Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Lọ—lr orí 10 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: Máa Lo Ọgbọ́n Tó O Bá Ń Wàásù. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Jàǹfààní, ojú ìwé 197, ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 200 ìpínrọ̀ 1. Ṣe àṣefihàn kan nípa bí akéde kan kò ṣe fọgbọ́n fèsì nígbà tẹ́nì kan ò fẹ́ gbọ́ ìwàásù rẹ̀. Lẹ́yìn náà ṣe àṣefihàn míì, lọ́tẹ̀ yìí kí akéde náà fọgbọ́n fèsì nígbà tẹ́ni náà ò fẹ́ gbọ́ ìwàásù rẹ̀.
15 min: “Ṣé Wàá Lo Àǹfààní Yìí?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní kí àwọn ará sọ ètò tí wọ́n ṣe kí wọ́n lè ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a yàn fún àkókò Ìrántí Ikú Kristi. Sọ ètò tí ìjọ ṣe fún Ìrántí Ikú Kristi.
Orin 8 àti Àdúrà