Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 15
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 15
Orin 192
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 1 ìpínrọ̀ 16 sí 20 àti àpótí tó wà lójú ìwé 13
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 5-9
No. 1: 1 Sámúẹ́lì 6:1-9
No. 2: Kí La Lè Fi Dáàbò Bo Ara Wa Lọ́wọ́ Sátánì Àtàwọn Ẹ̀mí Èṣù Rẹ̀?
No. 3: Ṣé Pétérù Ni “Àpáta Ràbàtà” Náà? (td 43B)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 211
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
5 min: “Ǹjẹ́ O Ti Múra Tán Láti Kọrin sí Jèhófà Láwọn Ìpàdé Ìjọ?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fún àwọn ará níṣìírí láti máa mú ìwé orin wọn tuntun wá sí ìpàdé, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ April 5, ọdún 2010.
10 min: Bó O Ṣe Lè Ṣe Ìpadàbẹ̀wò. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lé ìpínrọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lábẹ́ ìsọ̀rí tó wà lójú ìwé 96 nínú ìwé A Ṣètò Wa. Ṣe àṣefihàn kan tó fi hàn bí a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan tó gba ìwé tá à ń lò lóṣù yìí.
15 min: “Iṣẹ́ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá jíròrò ìpínrọ̀ 3, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tó ti láǹfààní láti kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tẹ́ni náà sì ti ń tẹ̀ síwájú. Àwọn ìyípadà wo ni ẹni náà ti ṣe? Ipa wo ni èyí sì ti ní lórí akéde náà?