Orin 1
Àwọn Ànímọ́ Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà, alágbára gbogbo,
Orísun ìyè àti ìmọ́lẹ̀.
Ìṣẹ̀dá ńsọ ti agbára ńlá rẹ;
Lọ́jọ́ ńlá rẹ, yóò túbọ̀ hàn.
2. Ìtẹ́ ńlá rẹ jẹ́ ti òdodo.
Àṣẹ òdodo rẹ sì ńhàn gbangba.
Bí a sì ṣe ńwo inú Ọ̀rọ̀ rẹ
A ńrí ọgbọ́n rẹ kedere.
3. Ìfẹ́ rẹ pípé ló ga jù lọ.
A ò lè san oore rẹ tán pátá.
Oókọ ńlá àtàwọn ànímọ́ rẹ,
La ó máa fayọ̀ polongo.