ORIN 42
Àdúrà Ìránṣẹ́ Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Alágbára, Jèhófà Bàbá wa,
Kórúkọ ńlá rẹ di sísọ di mímọ́.
Alèwílèṣe, jọ̀ọ́, à ń bẹ̀ ọ́.
À ń gbàdúrà kí Ìjọba rẹ dé
Lákòókò tó o ti ṣètò,
Ká lè rí ìbùkún gbà.
2. O ṣé tó ò ń bù kún wa lójoojúmọ́.
Àwọn ẹ̀bùn rere tó ò ńfún wa pọ̀ gan-an.
Ò ń fún wa níyè àt’ìmọ́lẹ̀.
Ò ń fún wa lọ́gbọ́n, ìmọ̀ àtòye.
A ó máa dúpẹ́, a ó yìn ọ́
Lójoojúmọ́ ayé wa.
3. Ìpọ́njú pọ̀ gan-an nínú ayé yìí.
À ń wojú rẹ, jọ̀wọ́ wá tù wá nínú.
Gbogbo àníyàn wa là ń kó wá.
Fún wa lókun, má ṣe jẹ́ ká bọ́hùn.
Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè ṣèfẹ́ rẹ,
Ká sì mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.
(Tún wo Sm. 36:9; 50:14; Jòh. 16:33; Jém. 1:5.)