Orin 2
A Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Rẹ Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
1. A dúpẹ́, Jèhófà, fún ’mọ́lẹ̀ òótọ́,
Tóo ńtàn sórí wa lọ́sàn-án àtòru.
A dúpẹ́ páa ní àǹfààní àdúrà,
Táa lè kó àníyàn wa wá bá ọ.
2. A dúpẹ́, Jáà fún Ọmọ rẹ onífẹ̀ẹ́,
Tó ṣẹ́gun ayé nípa ìgbàgbọ́.
A dúpẹ́ ìtọ́ni láti ṣèfẹ́ rẹ,
Táa fi lè mú àwọn ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.
3. A dúpẹ́, Ọlọ́run, pé a ńlè wàásù
Òtítọ́ àti orúkọ ńlá rẹ.
A dúpẹ́ pé gbogbo ègbé yóò dópin,
Tíbùkún ’jọba rẹ yóò wà láéláé.
(Tún wo Sm. 50:14; 95:2; 147:7; Kól. 3:15.)